Wo òògùn mẹ́fà tó ń dìn agbára ìbálòpọ̀ kù fún ọkùnrin àmọ́ tí ọ̀pọ̀ ṣì ń lò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin gbogbo akolekan ti ọkunrin maa n ni lati ri i pe awọn ṣe ojuṣe awọn bii baale ati baba ọmọ, ọna kan ṣoṣo ti wọn fi n gbadun aye ju ni ibalopọ ti wọn maa n ni pẹlu obinrin.
Amọ to ba n di pe eyi paapaa tun ti n bọ rẹlẹ, o le mu ohun gbogbo su ọkunrin.
Ọpọ nnkan ni iwadii ti tọka si pe o le fa a ki agbara ati ba obinrin sun dinku fun ọkunrin, amọ ọkan pataki wa ninu rẹ to jẹ pe oogun tawọn ọkunrin n lo lo n fa a.
Iwadii fi han pe awọn ogun kan wa to n gba agbara lati le sẹ bii akọ ninu yara, ati pe igba mi-in wa to jẹ pe ileewosan gan-an ni wọn yoo ti kọ ọ fun wọn lati lọ ra a.
Ki I ṣe pe oogun naa wa fun lati gba agbara ọkunrin bi iwadii ṣe wi, nnkan ọtọ ni iru awon ogun bẹẹ wa fun. Ṣugbọn ipadabọ iṣẹ wọn ti oloyinbo n pe ni side effects lo n gba agbara nnkan ọkunrin.
Gẹgẹ bi iṣẹ iwadii pataki kan lati ANI News Agency ṣe kede, ọpọ ogun lo wa nipele yii tawọn ọkunrin o mọ, ti wọn n ko owo wọn ra a lati tọju ohun kan tabi ikeji, ṣugbọn to n ṣakoba fun ilera ọlọmọkunrin lọdọ abo.
Wọnyi lawọn ogun to le din agbara nnkan ọkunrin ku
- Oogun ara riro
Eyi ni awọn ogun ti oloyinbo pe ni Analgesic, ti wọn wa fun lilo nigba ti ara ba n roni.
Ọpọ eeyan ni ki i ro o lẹẹmeji ki wọn too gbe oogun ara riro lura, koda ko jẹ irora diẹ bayii naa ni wọn ni.
Ṣugbọn ọpọ eeyan naa ni ko mọ pe awọn oogun ara riro yii n din agbara ati ba obinrin lo pọ ku.
Oogun ara riro maa n di awọn eroja to n ṣiṣẹ fun ibalopọ lara ọkunrin lọwọ bi iwadii ṣe wi, yoo dena awọn sẹẹli ati omoonu to n mu ibalopọ lọ geerege fun takọtabo.
- Oogun to n dena ijaya
Lode oni, eeyan to pọ niye ni won maa n ṣaroye lori aibalẹ ọkan, eyi maa n mu ki awọn elomiran maa koju ikayasoke ati aya jija.
Bayii ni wọn yoo maa lo awon ogun to le gbogun ti iṣoro yii.
Amọ awọn ogun yii maa n pa agbara ati ni ibalopọ ni, ko ni I jẹ ki eeyan tiẹ ronu ati ṣe ojuṣe rẹ lẹka ajọṣepọ tọkọtaya.
Nigba mi-in ẹwẹ, o maa n fa ki ọkunrin ma tiẹ ranti pe o pẹ toun ti ṣe 'kinni' gbẹyin, o si le ma jẹ ko wu u lati ṣe to ba tiẹ ranti.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ogun ti wọn fi n tọju apọju ọra ati ẹjẹ dídì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ogun kan wa ti wọn fi n tọju apọju ọra ninu ara, eyi to le fa ki ẹjẹ eeyan maa dipọ.
Eyi naa jẹ ọkan lara awọn ogun to n din agbara ibalopọ ku fun ọkunrin.
Awọn onimọ iṣegun sọ pe awọn ogun yii maa n ṣe akoba fun awọn ẹya ara to n ṣiṣẹ fun ọmọ bibi.
Bakan naa ni awọn iwadii kan fidi ẹ mulẹ, pe awọn ogun ti wọn fi n tọju ẹjẹ didi maa n fa iṣoro aile ṣe deede lọdọ obinrin fun ọkunrin.
- Oogun to n tọju ironu ati airi oorun sun
Irufẹ awon ogun yii ni wa labala ohun ti a mọ si Benzodiazepine.
Wọn maa n ni ki eeyan lo o to ba ni iṣoro kan to n da ọkan laamu, bi eeyan ko ba le sun daadaa ati bi awon iṣan ara kan ba n roni.
Awọn ogun naa ni wọn maa n lo fun iṣẹ ọpọlọ ati ọpa ẹyin, ti wọn jẹ aaye meji to n paṣẹ ara.
- Awọn ogun yii wa fun lati din ijaya ku, ki ara si le balẹ bo ṣe yẹ.
Ṣugbọn lilo wọn le fa wahala fun ọkunrin, eyi ri bẹẹ pẹlu bo ṣe le nipa lori ibalopọ ati ṣiṣe owo ọmọ.
Awọn ogun to n gbogun ti ifunpa giga.
Awọn oogun yii ni oloyinbo n pe ni "Anti-hypertensive medications"
Awọn eeyan to ni ifunpa giga lọkunrin, ti wọn si n lo awọn oogun to le ja ifunpa giga naa walẹ le maa koju awọn nnkan bii ko maa rẹ eeyan.
Eyi ri bẹẹ nitori lara opa ẹjẹ ni awọn oogun yii ti n ṣiṣẹ ju, o si le fa awọn idiwọ kan fun ọpọlọ.
Fun awọn eeyan kan, irinṣẹ ibalopọ wọn ni yoo foriko o.
Awọn akọṣẹmọṣẹ tun sọ pe awọn ogun to n mu ifunpa walẹ yii le ni ipa buburu lara obinrin pẹlu, paapaa julọ ti yoo ni nnkan ṣe pẹlu ibimọ.
Oogun ikọ́ ife
Eyi ni ikọ ti oloyinbo n pe ni Tuberculosis.
Bi eeyan ba n ra awọn ogun lori atẹ awọn ti ko kọṣẹ oogun tita, paapaa oogun ikọ ife titi kan awọn ogun ti wọn maa n lo bi imu eeyan ba di, gbogbo rẹ lo maa n ni ipa lori ilera.
Fun awọn kan, iru itọju yii le nipa labala ibalopọ, o le fa ki ibalopọ run si wọn, o si le fa ki ẹni to ti n ṣe daadaa lori iyawo rẹ tẹlẹ di ṣe eekan sunlọ.
Iyawo paapaa le di ẹni ti ibalopọ jẹ iṣoro fun.
Lọọ ri dokita a rẹ
Bi o ba ri apẹẹrẹ pe oogun kan n da jijẹ ọkunrin pipe rẹ laamu, tete lọọ ri dokita a rẹ.
Ma ṣe da oogun naa duro lojiji lai kọkọ lọ fi to dokita to ni ki o maa lo o leti, wọn yoo sọ igbesẹ to ba kan fun ọ lori ilera a rẹ.



























