Àlàyé rèé lórí ohun tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó gbẹ̀mí èèyàn 235, ṣe èèyàn 4,300 léṣe ní Venezuela

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan eeyan 188 lo ti padanu ẹmi wọn nibi isẹlẹ ilẹ riri meji to ṣẹlẹ lorilẹede Venezuela.
Aarẹ fidihẹ orilẹede naa, Delcy Rodríguez, ṣalaye pe eeyan to din diẹ ni ẹgbẹrun kan lo farapa nibi iṣẹlẹ naa.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi si n wa awọn eeyan to ha sabẹ awọn ile to wo lagbegbe ilu Guaira.
Koda, wọn n gbọ ohun awọn eeyan to ha sabẹ pangulutu ti wọn n pe fun iranwọ lati yọ wọn jade.
Ajọ USGS orilẹede Amẹrika sọ pe iṣẹlẹ ilẹ riri mejeeji naa ṣelẹ lera wọn, eyi to jẹ ko ni ipa to buru.
Iwadii fi idi rẹ mulẹ pe ori abọ isalẹ ilẹ meji ni orilẹede Venezuela wa, o si le jẹ nigba ti abọ meji yii kan ara wọn ni iṣẹlẹ ilẹ riri naa waye.
Aarẹ Rodriguez ti kede ilu o fararọ, ọpọ orilẹede lo si ti ṣeleri lati ṣeranwọ fun Venezuela.
Iṣoro nla akọkọ ree ti yoo koju Venezuela lati igba ti Aarẹ Donald Trump ti fọwọ ofin mu Aarẹ Nicolas Maduro loṣu Kinni ọdun yii.
Ilẹ riri ọhun to jin to ogun kilomita ninu ilẹ lo ṣẹlẹ ni nnkan bi ago mẹfa kọja iṣẹju mẹrin ni Venezuela l'Ọjọru.
Iṣẹlẹ naa ba ọpọ eeyan nile wọn tori ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni ana Ọjọru ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹfa jẹ ni Venezuela.
''Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi n ṣiṣẹ pẹlu iranwọ lati orilẹede Amẹrika, Dominican Republic, El Salvador, Mexico ati Qatar lati doola awọn to ha sabẹ ilẹ''
Alan Chung to jẹ olukọ ni Caracas sọ fun BBC pe oun ri eruku loke ati bi awọn opo ina ṣe n ṣana nigba ti wọn kan ara wọn.
Aworan lati Venezuela ṣafihan awọn ile to ti bajẹ latari iṣẹlẹ naa.
Minisita fun ọrọ abẹnu, Diosdado Cabello, sọ pe ọpọ ile lo dawo ni Caracas, bakan naa lo tun sọ pe ilẹ iriri naa tun ṣọṣẹ ni Trujillo, Yaracuy, Carabobo, Aragua ati Miranda.
Aarẹ Rodriguez ni papakọ ofurufu Venezuela to wa ni Maiquetía ti wa ni titi pa nitori ipa ti ilẹ riri naa ni nibẹ.
Aarẹ Rodriquez sọ pe ẹkun La Guaira to wa lapa ariwa olu ilu orilẹede naa ni iṣẹlẹ naa ti ni ipa to buru julọ.
BBC ti fi idi iroyin nipa ile itura alaja mẹwaa to di ilẹẹlẹ mulẹ lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri naa.
Iṣẹlẹ ilẹ riri yii jẹ ọkan lara irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ to ti ṣẹlẹ lati ọdun 1967 ti ilẹ riri kan ti ṣẹlẹ ni olu ilu Venezuela nibi ti igba eeyan ti padanu ẹmi wọn.
Olori ẹgbẹ alatako ni Venezuela, María Corina Machado, sọ loju opo X rẹ pe oun kẹdun pẹlu gbogbo idile ati ẹbi lorilẹede naa.
Aarẹ Rodrguez ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi n ṣiṣẹ pẹlu iranwọ lati orilẹede Amẹrika, Dominican Republic, El Salvador, Mexico ati Qatar lati doola awọn to ha sabẹ ilẹ.
Ẹwẹ, Aarẹ Trump ti sọ pe oun ti sọ fun ijọba oun lati wa lojufo fun iṣẹlẹ ilẹ riri.
Ki lo ṣokunfa ilẹ riri yii?
Orilẹede Venezuela wa lori abọ isalẹ ilẹ meji nibi ti apa South America ati Caribbean ti pade.
Ajọ Amẹrika to n ṣewadii nipa ilẹ sọ pe ọkan ninu ilẹ riri meji to ṣẹlẹ naa waye latari nnkan to waye ninu alafo to wa laarin abọ to wa ni isalẹ meji naa.
Wọn fi idi rẹ mulẹ pe awọn abọ to wa ni isalẹ ilẹ yii lo san sara ti o si fa ilẹ riri.
Ajọ USGS ni nnkan to ṣẹlẹ laarin abọ meji naa lagbara, ohun lo si fa ohun to ṣẹlẹ naa.
Ajọ naa fikun ọrọ rẹ pe o ṣee ṣe ki ilẹ mimi tun ṣẹlẹ lorilẹede naa lẹyin ilẹ riri to waye.
Lara ọna ti awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi fi maa n mọ ipa iṣẹlẹ riri ni bi o ṣe jin to ninu ilẹ.
Bi ilẹ riri ba ṣe sun mọ ori ilẹ si ni ipa rẹ ṣe maa n lagbara si.



























