Ṣé lóòtọ́ ni Alfa Muyideen Ajani Bello kò fẹ́ kí wọ́n ṣe àdúrà ọjọ́ kẹjọ fún òkú òun?

Aworan Alfa agba Muyideen Bello

Oríṣun àwòrán, Others

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni ọjọ kẹfa oṣu kejila ni iroyin jade sita pe Oni wassu agbaye, Alhaji Muyideen Ajani Bello jade laye, ti ọpọ eeyan si ti bẹrẹ si ni ma ba awọn mọlẹbi kẹdun.

Ṣugbọn fọnran kan lu sita lẹyin iku Oniwasu naa nibi to ti ti ẹnu bọ ọrọ lori igba to yẹ ki adura wa fun awọn eeyan to ba ku.

Bi ọpọ ṣe ti mọ, adura ọjọ kẹjọ, ọjọ kẹta tabi ka da ọjọ lo wọpọ ni ilẹ Yoruba ati ni awọn ilẹ mii.

Ninu waasi to wa lori ayelujara naa, Oloogbe Muyideen Ajani Bello ni ṣiṣe adura oku ni ọjọ kẹfa, ogoji ọjọ ko si ninu ofin Islam.

Bakan ni oloogbe ṣapejuwe igbesẹ gẹgẹ bii eyi to lodi si ofin Ọlọrun, ti gbogbo eeyan to ba lọwọ ninu rẹ si ni lati tọrọ aforijin.

"Ggbogbo ohun ta n ponle yii, ẹ lọ si ile ibomi, wọn ko ponle tori wọn ti ri pe ko si nnkan nibẹ"

Ko si igba ti a ko le ṣe adura fun oloogbe

BBC kan si awọn ọmọ oloogbe lati sọ boya wọn ni erongba lati se eto adura kankan fun oloogbe.

Ibrahim, ọkan ninu awọn Baba to ba wa sọrọ ni ohun ti Baba sọ ṣaaju ko to di oloogbe.

O jẹ ko dimọ pe imọ Islam lo n da ri oloogbe, to si jẹ pe iṣẹ Ọlọrun ni oloogbe wa jẹ laye.

Ibrahim ni ohun ti Baba fi kọ awọn ni pe ti eeyan ba ku, gbogbo nnkan ni wọn yoo da duro fun, ti wọn yoo si fun ni anfani si nnkan mẹta.

"A gbọdọ fikun ohun ti Baba sọ nitori ọrọ Ọlọrun. Nnkan mẹta to wa ninu Haditi ti Baba gbagbọ ninu rẹ ni pe nnkan mẹta ti sẹku ti oku ni Ọmọ daada to ba fi silẹ, ohun to ba se to n fi ṣe anfani fun awọn eeyan ati imọ to fi kọ awọn eeyan to n se anfani."

Ibrahim ni adura fun oku ko ni ọjọ ṣugbọn Baba duro lori Ọlọrun.

"Igba ti Baba wa laaye ni a ti n se adura fun ati pe lati ọjọ ti baba ti ku ni a ti bẹrẹ si ni ṣe adura fun oloogbe.

"Baba ọ sọ pe ọjọ mẹjọ, ọjọ mẹta tabi ọjọ kan ṣugbọn adura ma ba oku.

"Lati igba ti baba ti ku ni a tin se adura wọn"

Ki ni Islam sọ nipa adura oku?

Sheikh Taofeeq Akeugbagold ba BBC sọrọ lori ohun ti ẹṣin Islam lori sise eto adura fun oloogbe.

Akeugbagold ni Islam ko mu ọjọ kan lati fi ranti oku fi ṣe adura ṣugbọn ka mu sọ sise oku di awẹjẹwẹmu lasiko iranti oku.

"Islam ni iṣẹ rere ti eeyan ba ṣe lasiko to wa laye ni yoo ma tẹle lẹyin to ba ku.

"Ṣugbọn awọn eeyan to ba eeyan nla ninu aye, awọn ma n fi kan ranti wọn lati ma jẹ ki orukọ wọn parẹ ati pe ki awọn nnkan ti wọn fi silẹ ko ma parẹ."

Akeugbagold tẹsiwaju pe sise oku ko da bi sise igbeyawo tabi ode ariwa nibi ti ọpọ ti ma n jẹun tabi mu nnkan.

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Sheik Muyideen Ajani Bello

Ogbontarigi ni Sheik Muyideen Ajani Bello ninu ẹkọ ati imọ ẹsin Islam.

Ọmọ bibi ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo si ni pẹlu.

Iroyin sọ pe apa Ariwa ni baba naa gbe fun eyi to pọ ninu igbeaye rẹ, ko to o fi ilu Ibadan ṣe ibugbe lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin.

Bakan naa ni awọn akọsilẹ kan sọ pe ọmọ ọdun mẹwaa ni Bello wa to ti bẹrẹ sii ṣe waasi.

Baba rẹ to gbajumọ daadaa nigba naa labule Agberigbe, to wa niluu Iwo lo kọ ọ ni keu.

Muyideen Ajani Bello ni iroyin sọ pe o ṣiṣẹ olukọ ni Ansa-ru-deen College to wani Saki, ipinlẹ Oyo.

Sheik Ajani Bello tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ nile ẹkọ girama kan niluu Abẹokuta, nibi to ti kọ iṣiro ati Biology