You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n rán wa láti ṣekúpa Apostle Suleman - Afurasí
Ileeṣẹ Ọlọpaa lọjọbọ niluu Abuja safihan awọn afurasi janduku fun orisirisi ẹsun bi iṣekupani, ijinigba, adigunjale ati awọn ẹsun miiran.
Ọkan lara awọn afurasi ọhun ni Yusuf Isah, ẹni ọdun mejilelọgbọn fun ẹsun pe o pẹlu awọn janduku kan to sekọlu si ọkọ Ojisẹ Ọlọrun fun ile ijọsun Omega Fire Ministries Worldwide, Johnson Suleman.
Afurasi ọhun ninu ifọrọwerọ to se pẹlu awọn akọroyin, ni erongba awọn ti awọn fi se ikọlu naa ni lati sekupa Ojisẹ Ọlọrun, Johnson Suleman.
Afurasi salaye bi wọn se kọlu ọkọ Suleman
Awọn agbebọn sekọlu si ọkọ Suleman ni opopona Benin si Auchi nipinlẹ Edo, ti wọn si sekupa eeyan mẹfa pẹlu ọlọpaa mẹta.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi ni ọwọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ Isah lẹyin ọpọlọpọ iowadi.
Isah sọ fun awọn akọroyin pe oun ati awọn akẹgbẹ rẹ sọ Ojisẹ Ọlọrun naa ti ti de ibi ti wọn ti sekọlu si pẹlu ibọn AK47 marun un.
"Ikọlu ti a si Suleman ni lati sekupa. N ko mọ idi ta fi fẹ pa. Ilayasu ati Labisca lo mọ nipa rẹ.
"A kọlu ọkọ Suleman pẹlu ibọn Ak47 marun un. Labisca lo sọ lati ibi to ti n bọ de ibi ti a ti kọlu."
Ki ni Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?
Agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa fi idi rẹ mulẹ pe Ibọn AK47 marun un, ibọn K2 meji ati ọpọlọpọ ọta ibọn ni awọn gba lọwọ afurasi naa.
"Lẹyin iwadii wa lori isẹlẹ to sẹlẹ si Ojisẹ Ọlọrun Johnson Suleman ni opopona Benin si Auchi nibi ti eeyan mẹfa pẹlu ọlọpaa mẹta ti padanu ẹmi wọn ni ọwọ ti tẹ Yusuf Isah, ọmọ bibi ipinlẹ Kogi, to n se isẹ Plumber ni agbegbe Agbaraoluwa Phase 2 Ijoka niluu Akure, ipinlẹ Ondo, ti a si gba Ibọn AK47 marun un, ibọn K2 meji ati ọpọlọpọ ọta ibọn ni awọn gba lọwọ rẹ."
Adejọbi fikun pe "Afurasi naa darapọ mọ ẹgbẹ naa lọdun 2021 lẹyin to kuro ni ẹwọn Olokuta ni bi to wa lati ọdun 2019 fuin ẹsun ole jiga
"Ẹgbẹ yii ni se isẹ ijinigbe fun owo, ti wọn si ti kopa ninu ọpọlọpọ ijinigbe laarin ọdun 2021 si 2023 ki ọwọ ọlọpaa to tẹ wọn..
"Afurasi naa jẹwọ pe awon ẹgbẹ oun lo ji gbajumọ kan ni Jetu gbe lọdun 2022, ti wọn si gba owo toto adọrin milọnu naira ki wọn tu silẹ."