You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n fẹ̀sùn kan dókítà yìí pé ó sọ ọ̀pọ̀ aláboyún di àgan! Kí lohùn tò ṣẹ̀lẹ̀ gan?
Njẹ o ni oogun oni koro ti eeyan le lo ti yoo sọ obinrin di agan?
Abi iwọ ti gbọ nipa oniṣegun oyinbo to n fi iṣẹ abẹ sọ awọn obinrin di agan?
Gbogbo ibeere wọnyi lo gbode latara bi awọn ẹlẹsin Buddha ni Sri Lanka ṣe fẹsun kan awọn musulumi nibẹ.
Koko iroyin ti wọn n gbe ka yii si ni pe awọn musulumi nilẹ naa n fọgbọn mu alekun ba iye eeyan wọn.
Ko tan sibẹ wọn ni wọn n sọ awọn obinrin ẹlẹsin Buddha di agan.
Dokita kan lati ilu Kurungẹla ni wọn naka si pe o wa nidi ẹsun yii.
Mohamed Shafi, Dokita oniṣegun oyinbo sọ fun BBC pe ''musulumi ni mi wọn si fẹsun kan mi pe mọ n ṣe iṣẹ abẹ bonkẹlẹ eleyi to n sọ awọn obinrin ẹlẹsin Buddha di agan.
Wọn parọ mọ dokita yii pe o n lo irinṣẹ kan lati fi tẹ ile ọmọ awọn obinrin oloyun Buddha lasiko iṣẹ abẹ ti eyi ko si jẹ ki wọn ri ọmọ bi mọ.
Lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kaarun 2019 wọn fẹsun kan ti wọn si gbelọ sile ẹjọ labẹ ofin pe o hu iwa agbesunmọmi.
O ni ''wọn sọ mi sẹwọn pẹlu awọn ọdaran. Mo wa n ro wi pe ki lo de ti wọn fi ṣe bayii fun mi? Mo ni lati moribọ tori awọn ọmọ ati iyawo mi'.
Ọgọta ọjọ lo lo latimọle.
Ni oṣu Keje ọdun 2019 ile ẹjọ gba beeli rẹ amọ wọn ni ko lọ rọọkun nile lẹnu iṣẹ tori iwadii yi.
Lẹyin ọdun mẹrin, ileeṣẹ ilera ijọba Sri Lanka da a pada sẹnu iṣẹ rẹ tori pe wọn ko ribi fẹsẹ ẹsun ti wọn fi kan an rinlẹ.
Ikọlu ado oloro lọjọ Ajinde
Ni Sri Lanka awọn ẹlẹsin Buddha ko ida 70% iye eeyan miliọnu mejilelogun ilẹ naa tawọn musulumi si ko ida mẹwa.
Awọn Hindu jẹ ida mejila tawọn Kristẹni ko si ju ida meje lọ.
Ṣaaju ẹsun ti wọn fi kan dokita Shafi gbogbo awọn to n tọju wa lati orisi ẹsin tabi ẹya kaakiri orileede naa.
Amọ ado oloro to bugbamu ni ile ijọsin Kristẹni to ṣeku pa eeyan 250 lọjọ ajinde yi nkan pada.
Ikọlu yi ti ẹgbẹ alakatakiti musulumi kan to lajọṣepọ pẹlu ISIS ṣe leleyi to buru julọ lẹyin igba ti ogun abẹle wa sopin nilẹ naa lọdun 2009 laarin awọn ọmọ ogun ijọba ati ikọ Tamil Tigers.
Ibugbamu yi mu ki ọpọ eeyan ni ọkan idẹyẹsi si ẹsin Islaamu.
Koda o buru debi pe awọn kan dana sun mọṣalaṣi ile ati ṣọọbu awọn musulumi. Musulumi kan si padanu ẹmi rẹ pẹlu.
Ẹsun ti ko fẹsẹ mulẹ
Lọjọ Kẹtalelogun oṣu Kaarun, oṣu kan lẹyin ikọlu ọjọ ajinde ni ileeṣẹ iwe iroyin Diviana gbe iroyin jade to si fẹsun kan dokita kan to lo ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ Thawheed Jamath pe o sọ ẹgbẹrun mẹrin awọn obinrin Buddha di agan.
Wọn ṣe akojọpọ iwadii ti wọn tori rẹ mu dokita naa.
Thawheed Jamath wa lara awọn ẹgbẹ musulumi ti wọn lo wa nidi ikọlu ado oloro ọjọ ajinde.
Ileeṣẹ iroyin naa ko sọ ibi to ti ri ẹri to fi kan dokita naa tabiu ko sọ orukọ rẹṣugbọn kopẹ pupọ kawọn eeyan to gbe aworan dokita Shafi sita ti wọn si fi ibi to wa si oju opo Facebook.
''Igba akọkọ ni yẹn ti wọn fẹsun kan mi nita gbangba lori ọrọ yi.''
Dokita Shafi sọ pe oun kọwọ rin pẹlu awọn agba dokita lati lọ fẹjọ sun adari ileewosan Kurungela Dokita Sarath Weerabandra lori iṣẹlẹ yi .
Bẹẹ lo ni oun sọ fun pe awọn eeyan n dunkoko mọ ẹmi oun.
Amọ Weerabandra sọ pe ọrọ to ba ṣẹlẹ ninu ile iwosan nikan loun le da si,
Lẹyin ọjọ meji to fẹjọ sun yi, o ni ''wọn gbe mi lọ si ahamọ ọlọpaa ki ọrọ naa ma ba da igboro ru''
Awọn akọroyin naa ko duro deedewọ
Ọrọ yi ran kaakiri loju opo ayelujara ati lori ẹrọ mohunmaworan.
''Wọn ka ẹsun si mi lọrun, Wọn pe mi ni agbesunmọmi nita gbangba. Gbogbo awọn ileeṣẹ iroyin ti ko mọṣẹ ba mi lorukọ jẹ. Wọn ko ba aye mi''.
Dokita Shafi ni ọrọ yii buru debi pe ''wọn halẹ mọ iyawo mi wi pe awọn yoo gbẹmi rẹ. O bẹrẹ si ni foya fun ẹmi awọn ọmọ mi''.
''Ọmọ mi to dagba julọ n palẹmọ idanwo lasiko yii ṣugbọn ko le lọ nitori awuyewuye yii. O binu si wa ti iporuru ọkan si ba a. A pada wa ile ẹkọ miran fun un ni''.
Bawo lọrọ ṣe pada ni iyanju?
Nigba ti wọn ko ri ẹri kankan lori awọn ẹsun ti wọn fi kan Dokita Shafi yii, o pada sẹnu iṣẹ loṣu karun-un ọdun 2023 ni ile iwosan Kurunegala.
O gba owo oṣu rẹ ọdun mẹta ti wọn ko san lasiko iwadii to jẹ 2.7 million rupees owo ilẹ wọn to ṣe deede $8,750.
Gbogbo owo yii ni o fi tọrẹ si ileeṣẹ ilera pe ki wọn fi ra oogun.
Pupọ awọn Dokita lorileede Sri Lanka lo n japa lọ silẹ okere nitori ipenija eto ọrọ aje ti ko burẹkẹ nilẹ naa.
Ṣugbọn Dokita Shafi sọ pe oun ko ni lọ si ibikankan bi kii ṣe pe ki oun duro lati maa ṣiṣẹ ni ile iwosan ti wọn ti fẹsun eke kan an.
''Awọn mọlẹbi mi sọ pe ki n ma duro ṣugbọn mo mọ wipe ọna kan ti mo le fi jẹ ki wọn mọ wipe mi o jẹbi ni ki n pada si ile iwosan yii ki n si tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti wọn tori rẹ parọ mọ mi.''