Ibi tí rògbòdìyàn tó ń lọ ní France lórí ọmọ ọdún 17 tí ọlọ́pàá kan pa nìyí

Awọn olùfẹ̀hónúhàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published

Ó jọ wí pé rògbòdìyàn tó ń wáyé ní orílẹ̀ èdè France ti ń rodò lọ mumi lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún tí àwọn ènìyàn ti ń ṣe ìwọ́de lórí bí ọlọ́pàá ṣe pa ọmọdé kan, Nahel M tó kọ̀ láti dúró nígbà tí ọlọ́pàá da dúró nígbà tó wa ọkọ̀.

Wàhálà tí àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ń fa dínkù jọjọ lálẹ́ ọjọ́ Àìkú àti pé àwọn ènìyàn tí ọwọ́ ọlọ́pàá náà bà kéré níye.

Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ France, Emmanuel Macron tí sọ fún Mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ abẹ́lé láti ri pé wọ́n da ọlọ́pàá yanturu sí ìgbooro láti ri dájú pé ohun gbogbo padà bọ̀ sípò bó ṣe yẹ.

Ní ọjọ́ Ajé ni àwọn Mayor ní kí àwọn gbọ́dọ̀ ṣe àmójútó pé àdínkù bá wàhálà tí bí wọ́n ṣe ń jí nǹkan dínkù lórí ìwọ́de yìí.

Ní ìlú Nanterre tó jẹ́ ìlú Nahel, Mayor Patrick Jarry ní inú òun dùn pé wàhálà tí àwọn olùfẹ̀hónúhàn ń fà ti dínkù àmọ́ tó ní àwọn kò ní fojú fo ìṣẹ̀lẹ̀ tó bí rògbòdìyàn náà gan.

Jarry ní àwọn máa ri dájú pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ikú Nahel tí ọlọ́pàá pa.

Mayor ìlú Reims, ìlú kan tí kò ju ìrìn wákàtí méjì sí Paris ní ọjà tí àwọn ènìyàn tí máa ń lọ ra nǹkan náà ni wọ́n ti jí gbogbo ọjà inú rẹ̀ kó.

Ọlọ́pàá tí iye wọn tó 45,000 ni wọ́n ti dà sí àwọn ìlú káàkiri orílẹ̀ èdè náà láti bí ọjọ́ mélòó kan tí rògbòdìyàn náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ àti ilé ni àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà jó níná káàkiri orílẹ̀ èdè France.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun ilé Mayor Paris

Bákan náà ni wọ́n tún ṣe ìkọlù sí ilé Mayor Paris pẹ̀lú èrò láti dáná sun ilé rẹ̀, tí wọ́n sì tún yìbọn ba ìyàwó àti àtàwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń sálọ.

Ìwà yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń bu ẹnu àtẹ́ lù tí wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan àwọn tó ṣe iṣẹ́ náà.

Olóòtú ìjọba France, Elisabeth Borne júwe ìgbésẹ̀ náà bí èyí tìkò tọ̀nà àmọ́ wọn kò rí ẹnìkankan mú láti fẹ̀sùn pé ó ṣe iṣẹ́ láabi yìí.

Mayor Vincent Jeanburn kò sí nílé nígbà tí ìkọlù náà wáyé àmọ́ ìyàwò rẹ̀ tó wà nílé nígbà ìkọlù náà ṣèṣe lẹ́sẹ̀ tí ọmọ wọn kan náà sì farapa.

Ẹbí Nahel rọ àwọn olùwọ́de láti dáwọ́ ìkọlù dúró

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bẹ́ẹ̀ náà ni Nadal, ìyáìyá ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún Nahel, tí àwọn ọlọ́pàá pa rọ àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn láti dáwọ́ ìwọ́de tí wọ́n ń ṣe dúró.

Ìyá náà ní òun kò fẹ́ bí àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ṣe ń ba àwọn sọ́ọ̀bù, ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn ọkọ̀ jẹ́ káàkiri gbogbo ìgboro nítorí ikú ọmọọmọ òun.

Ó ní gbogbo àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ kàn ń lo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé sí ọmọọmọ òun láti fi máa hu ìwà tí kò tọ́ ni.

Nadal ní ó dá òun lójú pé ọlọ́pàá tó ṣekúpa ọmọọmọ òun máa fojú winá òfin àti pé kí gbogbo àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn dáwọ́ gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe dúró.

Ó fi kun pé gbogbo ìwọ́de tí wọ́n ń ṣe náà kò dá ẹ̀mí Nahel padà nítorí náà òun ń fẹ́ kí àláfíà jọba nínú ìlú.

Ní Nanterre ni Nadal ti bá àwọn akọ̀ròyìn ilé iṣẹ́ BFM TV sọ̀rọ̀ lórí rògbòdìyàn tó ti gba orílẹ̀ èdè France kan láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun tí ọlọ́pàá ti yìnbọn pa Nahel.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀ka ìdájọ́ wí pé wọ́n máa ṣe ìdájọ́ ọlọ́pàá náà bó ṣe tó àti bó ṣe yẹ.

Ó fi kun pé bí àwọn ṣe ń gba owó fún ọlọ́pàá tó pa ọmọọmọ òun jẹ́ ohun tó ba òun lọ́kàn àmọ́ ẹni tó ṣe àgbékalẹ̀ gbígba owó náà ní kìí ṣe láti sọ wí pé ọlọ́pàá náà kò jẹ̀bi.

Ó ní àwọn ẹbí ọlọ́pàá ọ̀hún ni òun ń gba owó náà fún.

Ààrẹ Macron máa ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn Mayor káàkiri àwọn ibi tí rògbòdìyàn náà ti ṣe àkóbá fún.