Ọlọ́pàá mú afurasí ajọ́mọgbé méjì n'Ibadan, dóòlà ọmọ ọdùn márùn-un tí wọ́n jí gbé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adegboye Seyi Sunday; ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), ati Adegboye Elijah Adefemi, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) ni wọn ti wa ni ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo bayii, lẹyin tọwọ ba wọn fun ẹsun jiji ọmọbinrin kan, Fikayo Gbemiga, ọmọ ọdun marun-un, gbe niluu Ibadan.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa pada ri ọmọdebinrin naa gba pada lai fi ara pa, o ṣi lo to ọsẹ kan lakata awọn to ji i gbe naa.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Oyo, DSP Olayinka Ayanlade fi sita ṣe ṣalaye, ọjọ kẹta oṣu Keje ọdun 2026 yii ni awọn afurasi naa wọ ile awọn obi Fikayo to wa lagbegbe Iyana-Ofa,niluu Ibadan lọna aitọ, ti wọn si ji i gbe lọ.

Lẹyin ti wọn ji ọmọ naa gbe ni wọn beere fun miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe wi, wọn si ti gba miliọnu kan ninu owo naa ki ọwọ palaba wọn too pada segi.

Bi ọwọ ọlọpaa ṣe ba awọn afurasi ti wọn tun gba ọmọ naa kalẹ

Gẹgẹ bi DSP Olayinka Ayanlade ṣe ṣalaye ninu atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo to fi lede, ẹka to n gbogun ti ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa naa lo ṣiṣẹ lorii bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi naa, ati bi wọn ṣe doola Fikayo Gbemiga.

Imọ ẹrọ ati awọn ilana itọpinpin mi-in lo ni ikọ atọpinpin naa lo ti wọn fi mọ ibi ti awọn afurasi ajinigbe naa farapamọ si.

Nigba to di ọjọ kọkanla, oṣu Keje ọdun 2026 yii ni ikọ atọpinpin naa ṣe aṣeyọri lori iwadii.

Nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ naa ni wọn de ibi ti awọn eeyan naa fi ṣe ibuba.

DSP Ayanlade fidi ẹ mulẹ pe agbegbe Mojoyin Molade, Iwo Road, n'Ibadan ni wọn fi ara ṣoko si pẹlu ọmọ ti wọn ji gbe.

Nibẹ ni wọn ti gba ọmọde naa lọwọ wọn ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan fun itọju, bẹẹ ni wọn fi ṣinkun ofin gbe awọn to gbe e pamọ.

Lorii miliọnu kan naira ti awọn eeyan naa ti kọkọ gba, ọjọ kẹjọ oṣu Keje ni wọn gba a bi alaye ọlọpaa, ilu Gbọngan, nipinlẹ Osun ni won si ti gba a gẹgẹ bii ara miliọnu mẹwaa ti wọn beere.

Bi ọwọ ṣe tẹ wọn wayii ti wọn si ti n sowọpọ pẹlu ọlọpaa, igbesẹ ti n lọ lati gba miliọnu kan naa pada lọwọ wọn bawọn ọlọpaa ṣe ṣalaye.

Bẹẹ ni wọn ni iwadii n tẹsiwaju lati mu awọn ikọ ajinigbe naa to ba tun ku.