Mọ̀lẹ́bí kẹ̀yìn sí eégún agboolé wọn n’Ibadan, Olubadan gbóríyìn fún wọn

Egungun ati onilu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Sen. Lekan Balogun, Alli Okunmade II ti gbe oṣuba kare fun mọlẹbi Jalaruru ti Opo-Yeosa ni ijọba ibilẹ Iwọorun-Ariwa ilẹ Ibadan, fun bi wọn ṣe fi ọwọ osi juwe ile fun eegun ile wọn ti ọpọ eeyan mọ si "Jalaruru".

Ọba Balogun gboriyin fun mọlẹbi naa lasiko ti Mọgaji ile wọn, Muftau Gbadegesin ṣe abẹwo si aafin Olubadan ilẹ Ibadan, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to awọn oniroyin leti lati ọwọ akọwe iroyin fun Olubadan, Oladele Ogunsola.

Ẹnu ti n kun eegun Jalaruru to jẹ gbajugbaja eegun fun oriṣiriṣi iwa ti ko bojumu lawujọ, ti o si tun n da awọn eeyan ilu laamu, nipasẹ eyii ti gbogbo mọlẹbi ṣe fi ofin de eegun naa, lati dẹkun ẹrẹ ti o n ta si aṣọ ala idile naa.

Mọgaji Gbadegesin ṣe alaye wi pe ofin ti wọn fi de eegun Jalaruru ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin lo waye nipasẹ awọn rogbodiyan to rọ mọ ijade rẹ, ti o si ti di nnkan to fẹ ba orukọ ẹbi jẹ.

O ni, "Ara wa ko gba iru iṣẹlẹ naa mọ, a ko si ri nnkan mii ṣe sii ju pe ki a ni ki o lọ rọọkun nile fun anfaani awọn eeyan ilu.

O dun ni jọjọ wi pe nnkan ko ri bayii tẹlẹri ninu itan eegun naa.

Mọgaji Gbadegesin sọ pe nigba kan, eegun Jalaruru maa n jade lọdọọdun, yoo si wọ awọn oju Ile wa mejilelọgbọn to n bẹ ni agboole kan naa lati gba adura fun gbogbo eeyan, lẹyin eleyii si ni yoo pada sinu iyẹwu rẹ titi di ọdun to n bọ".

"Ṣugbọn lojiji, ilana yipada nitori ọlaju, eegun yii wa di nnkan ẹru ati ijaya ti o si mu ki awọn janduku fi ori pamọ si abẹ rẹ lati ba orukọ ẹbi jẹ."

Olubadan gbe oriyin fun igbesẹ naa, pẹlu alaye wi pe yoo ṣe anfaani fun gbogbo eeyan ilu.

Ọba Balogun ni, oun mọ mọ riri rẹ ati gbogbo mọlẹbi Jalaruru fun igbesẹ to ni arinrin yii.

“Botilẹ jẹ wi pe o ti ṣẹlẹ ki n to gun ori aleefa, ti ọpọ eeyan ko si mọ nipa rẹ, ṣugbọn o jẹ ọpakutẹlẹ fun ibagbepọ alaafia fun gbogbo eeyan.”

Olubadan sọ pe ko si nnkan ti a le fi we alaafia, bẹẹni ko si nnkan ti o pọju lati ṣe ki alaafia le j'ọba.

Olubadan ti fi ofin de ọdun eegun ri

Ninu oṣu Keje, ọdun 2023, Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun, pasẹ pe ki awọn egungun mase jade mọ jakejado ilẹ naa.

Eyi ko si sẹyin iwa jagidi jagan ti wọn n hu, eyi to n ko ijamba ba araalu ati dukia wọn.

Ọba naa tun kesi awọn olori ikọ eegun kọọkan taa mọ si Alaagba ni ilẹ Ibadan pe ki wọn wa sibi ipade pajawiri kan laafin rẹ lori ọrọ naa.

Kabiyesi fi itara han bi orisirisi iroyin ikọlu ati iwa jagidijagan ṣe gbode lasiko ọdun egungun yi.

Bẹẹ lo ni inu oun ko dun si fọnran fidio to gbode ti Kabiyesi si ṣapejuwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi itabuku aafin nitori oun ti kilọ pe ki wọn ma sọ eegun di ọna ati da wahala silẹ.

Ki lo le ṣẹlẹ ti eegun ba kọ lati jade niluu Ibadan?

Eegun to mu ada lọwọ

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/KEHINDE.SAHEED.372

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2020 , Olubadan tilẹ Ibadan to ti waja, Ọba Saliu Akanmu Adetunji paṣẹ pe egungun kankan ko gbọdọ jade fun ọdun eegun, nitori arun Coronavirus.

Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ naa lọdun 2020, Oloolu ni oun ko gbọ ri rara pe ni ọdun kan, eegun ko ni fi aṣọ wọlẹ nilu Ibadan.

Oloolu ni "awọn nnkan to maa n sẹlẹ lẹyin rẹ maa n lagbara, Ọlọrun ma jẹ ka ri ogun igbona, Coronavirus si ree, igbona lo bii,aṣọ eegun si lo maa n ko arun kuro nilu.

Agba eegun naa ni idakureku ojo to n waye laarin ìlú, isoro nla ni, orisirisi arun ni yoo si maa bẹ silẹ, to fi mọ arun ti a ko gbọ ri.

"Aṣẹ ti ijọba pa fun Olubadan lo sọ sita, oun ti ko si ye ijọba ni pe egungun la fi tẹ Ibadan do, bi eegun ko ba si jade, isoro yoo sẹlẹ, Ọlọrun ma jẹ ki aburu ṣe wa."

Oloolu tẹsiwaju pe "Ọrọ bii wahala ni yoo maa sẹlẹ n'Ibadan, ọrọ bii ogun, bii ọtẹ, awọn etutu kan wa ta maa n ṣe fun ọba, bawo wa ni yoo ṣe wa di sise lọdun yii, ti wọn yoo ni ka ma ṣe etutu ọhun amọ ka jokoo sile."

Oloolu tẹ siwaju pe awọn egungun kan wa to jẹ pe ti wọn ko ba jade, nnkan yoo ṣe awọn to n gbe eegun naa, to si fi eegun kan ti wọn ni ko ma jade ni ọdun kan ṣe apẹẹrẹ, o ni ọmọ ẹni to n gbe eegun naa meji lo ku.