Ìjọba fojú mẹ́ta lára àwọn afurasí agbésùnmọ̀mí tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé l'Ogbomoso hàn nílé ẹjọ́

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti foju mẹta ninu awọn afurasi agbesunmọmi ti wọn ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ gbe lọ ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso han nile ẹjọ giga apapọ l'Abuja lonii ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keje yii.

Awọn afurasi mẹta ọhun, Abdulrazak Umar, Yunusa Musa ati Shamsu Adamu Sani ni ijọba ti fẹsun onikoko mẹwaa to da lori igbesunmọmi, ijinigbe, fifi ọrọ pamọ ati wiwa kusa lọna aitọ kan.

Oni ọjọ Ẹti ni ijọba fawọn ẹsun naa kan wọn nile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe Umar lo n jẹ Abu Khalifa, nigba ti Musa n jẹ Yunusa bin Musa, Sani si n jẹ Abu Itisar.

Ijọba ibilẹ Suleja ni ipinlẹ Niger lawọn mẹtẹẹta ti wa.

Igbimọ olupẹjọ sọ fun ile ẹjọ pe awọn afurasi mẹtẹẹta gbimọ pọ pẹlu ọkunrin kan to n jẹ Muhammad Sani, Jibril Mohammed ati Ibrahim Khabab laarin oṣu Kinni si Ikarun un ọdun 2026 yii lati ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe nile ẹkọ girama Esinele ati Yawota nijọba ipinlẹ Oyo.

Wọn ni awọn ẹsun yii lodi si nnkan to wa ni abala 26(1) iwe ofin Naijiria lori ọrọ igbesunmọmi.

Ijọba apapọ tun fẹsun kan awọn afurasi mẹtẹẹta naa pe awọn lo ṣagbatẹru ijinigbe Oriire, ati pe wọn tun kọ lati sọrọ nipa awọn to ji awọn akẹkọọ ati olukọ naa gbe ni ijọba ibilẹ Oriire.

Ifarahan yii waye lẹyin ọsẹ kan tawọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe ni Oriire gba ominira.

Ni ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ọdun yii lawọn ajinigbe naa ya wọ ilu Esinele ati Yawota l'Ogbomoso nibi ti wọn ti ji akẹkọọ mọkandinlogoji ati olukọ meje lọ.

Àwọn ajínigbé ṣekúpa sọ́jà, Amotekun, ọlọ́dẹ àti olùkọ́ méjì nínú igbó, Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ Esinele sọ ìdí tí wọ́n fi pa àwọn olùkọ́

Ṣaaju ni ọga agba ile ẹkọ girama Esinele, Arabinrin F.R. Alamu ti sọ pe iriri to buru jai ni a ni ninu igbo pẹlu awọn ajinigbe.

Arabinrin Alamu ni ''awọn ajinigbe naa dẹru ba wa, wọn tun sọ wa pe ijọba ti gbagbe wa sinu igbo.

Wọn maa n lo foonu wọn lati ba oriṣiiriṣii awọn eeyan sọrọ.

Arabinrin Alamu sọ pe nnkankan tawọn gbagbọ ni pe awọn ọmọ Naijiria n gbadura fawọn.''

Ọga ile ẹkọ girama Esinele fikun ọrọ rẹ pe ọjọ keji ti wọn ko awọn de inu igbo lawọn ajinigbe naa ṣekupa ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe , oloogbe Michael Oyedokun.

Arabinrin Alamu ṣalaye pe wọn pa awọn olukọ meji lati le jẹ ki ijọba fun wọn ni nnkan ti wọn n beere fun un.

O ni nigba tawọn gbominira tan lawọn to mọ wi pe gbogbo agbaye lo fẹ kawọn bọ lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Apa ti wa ni ara wa bayii, amọ, a gbagbọ wi pe apa naa yoo san nigba to ba ya.

Arabinrin naa dupẹ lọwọ ijọba, awọn ẹṣọ eleto aabo ati gbogbo eeyan ti wọn kopa kan tabi omiran lati ri pe wọn gbominira lọwọ ajinigbe.