Wo àwọn orílẹ́-èdè ilẹ̀ Afirika táwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika kò gbọdọ̀ lọ

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba ilẹ Amẹrika ti kede awọn orileede mẹtalelogun kan nilẹ Afirika, Asia ati Yuroopu tawọn ọmọ ilẹ naa ko gbọdọ gba kọja, ti wọn ko si gbọdọ lọ sibẹ.

Ninu atẹjade ti awọn alakoso ilẹ Amẹrika fi sita l'Ọjọru ọsẹ yii ni wọn ti sọ pe awọn orileede naa lewu pupọ lati debẹ lasiko yii.

Amẹrika sọ pe ipele kẹrin ni awọn orileede mẹtalelogun ọhun wa ninu awọn orileede ti Amẹrika sọ pe awọn araalu ko gbọdọ lọ, fun idi eyi, wọn ni ko si ohun kankan to yẹ gbe awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lọ sawọn orilẹede naa.

Mẹwaa ninu awọn orileede yii ni wọn wa nilẹ Africa – awọn si ni Burkina Faso, Uganda, Democratic Republic of Congo, Mali, Niger, Sudan, ati awọn miran.

"A ti gbe amoran irin ajo dide lati ipele akọkọ si ipele kẹrin, ipele kẹrin jẹ 'Ẹ MA ṢE LỌ SIBẸ'.

Amoran ipele kẹrin yii lo ni i ṣe pẹlu ohun ti wọn n koju nibẹ, ati aini agbara kikun lati ṣe iranwọ f'awọn ọmọ Amẹrika to n gbe nibẹ," amọran naa wa, pẹlu bi wọn ṣe ṣapejuwe awọn orileede ọhun gẹgẹ bii ibi to lewu.

Orukọ awọn orileede tawọn ọmọ Amẹrika ko gbọdọ lọ

Afghanistan

Belarus

Burkina Faso

Burma

Central African Republic (CAR)

Chad

Democratic Republic of the Congo (DRC)

Haiti

Iran

Iraq

Lebanon

Libya

Mali

Niger

North Korea

Russia

Somalia

South Sudan

Sudan

Syria

Uganda

Ukraine

Yemen

Ki lo de ti Amẹrika ṣe fi awọn orileede wọnyi si ipele kẹrin?

Pupọ ninu awọn orileede wọnyi ni wọn ti wa ninu akọsilẹ wi pe wọn n koju iṣoro lẹka eto aabo, rukerudo tabi pe ijọba wọn ko si ni agbara lati koju rẹ.

Uganda – orileede yii lo ṣẹṣẹ darapọ lẹyin ti ilẹ Amẹrika ṣe afikun lori orileede naa si ipele kẹrin, nitori ajakalẹ arun Ebola to gbode ati awọn iwa ọdaran miran bii agbebọn aṣekupani ati awọn ohun miran ti ko fọkan awọn araalu balẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹkun Ila-Oorun ilẹ Afrika ti n fi iroyin awọn aṣeyọri wọn sita nipa aarun naa, pẹlu bi awn aṣoju ijọba ṣe sọ pe wọn yoo yọnda awọn to fara kaaṣa l'Ọjọbọ, ọsẹ yii.

Ilẹ Amẹrika ninu atẹjade sọ pe iwa ọdaran to nii ṣe pẹlu ipa lewu fun orileede Uganda, ati awọn iwa bii idigunjale, kikogun ija ile, ati iwa to nii ṣe pẹlu ifipabanilopọ.

Wọn fi kun un pebi iwa ipa awọn agbebọn ṣe lewu, eyi to nii ṣe pẹlu ẹkun Ila-Oorun Afrika, ati pe gbogbo igba ni iwọde n ṣẹlẹ, lai si ikilọ.

Iṣakoso Donald Trump tun ti ṣagbekalẹ idena labẹ akọle '49' ninu ilana fifi ofin de awọn araalu lati rin irin ajo, ati pe gbogbo awọn araalu ti won n gbe ni DRC ni wọn ti fun ni gbedeke ọjọ mọkanlelogun lati tete pada si Amẹrika.

DR Congo – Ileeṣẹ eleto aabo ti 'Department of Homeland Security', sọ pe nitori ọrọ Ebola to gbode, awọn ti ṣagbekalẹ ofin idena miran fun gbogbo awọn araalu wọn to n gbe lorileede DR Congo lati pada sile laaarin gbedeke ọjọ mọkanlelogun nipasẹ ọkọ baalu akero.

Ninu atẹjade naa, ijọba ilẹ Amẹrika sọ pe awọn ko nii gba gbogbo awọn arinrin ajo lati DR Congo laaye lati wọ baalu to n lọ si Amẹrika laaarin ọjọ mọkanlelogun naa.

"Ki gbogbo ọmọ ilẹ Amẹrika ati awọn to n gbe nilẹ Amẹrika, ti wọn ti ṣabẹwo si DRC maa palẹmọ lati kuro nibẹ lọ si ẹkun Iwọ Oorun Afrika fun ọjọ mọkanlelogun, ko to di pe wọn n pada bọ nilẹ Amẹrika," awọn alakoso sọ bẹẹ.

Ninu oṣu Kẹrin, ilẹ Amẹrika fi orileede Burkina Faso sinu orukọ orileede ti wọn ko gbọdọ rin irin ajo lọ, nitori awọn iwa ọdaran to n ṣẹlẹ nibẹ, bii ijinigbe, agbegbọn aṣekupani ati eto ilera.

Mali – Ninu oṣu Kẹfa ni Amẹrika fi Mali sinu akọsilẹ naa, nitori awọn iwa ọdaran to n ṣẹlẹ nibẹ, bii ijinigbe, agbegbọn aṣekupani ati eto ilera. Eyii naa ko si gbẹyin fun awọn orileede bii Niger.

Ki ni ipele kẹrin amọran naa tumọ si?

Ilana eto amọran ilẹ Amẹrika lo bẹrẹ lati ipele kinni si ipele kẹrin, leyi to so nipa 'awọn igbesẹ to yẹ lati gbe' ati 'ma ṣe rin irin ajo'.

Ipele kẹrin yii lo ga julọ nitori to nii ṣe pẹlu idunkooko mọ ẹmi. Wọn maa n fi silẹ fun awọn agbegbe ti ijọba nigbagbọ pe awọn orileede naa lewu gidigidi lẹka eto aabo ati ilera.

Ijọba ilẹ Amẹrika sọ pe wọn le ma ni agbara to to lati ran awọn eeyan lọwọ, to fi mọ awọn asiko ti iṣẹlẹ pajawiri ba waye lawọn orileede naa.