Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Sam Larry níbi tí ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ Adewale ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Sam Larry/Instagram
Ọpọ eeyan lo ti n kọminu lori ipo ti gbajugbaja agborin-larugẹ, Samson Erinfolami Balogun tawọn eeyan mọ si Sam Larry, wa lẹyin ti iroyin fidi rẹ mulẹ pe ijamba ṣẹlẹ si ọkọ rẹ lopopona ilu Eko si Calabar niluu Eko.
Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ ti Sam Larry wa ninu rẹ fori sọ ọkọ tirela kan eyi to jẹ ki Adewalẹ to jẹ ẹṣọ ilumọọka agborin-larugẹ naa padanu ẹmi rẹ.
Lẹyin naa ni a gbọ pe wọn gbe Sam Larry lọ sile iwosan nibi to ti n gba itọju.
Sọrọsọrọ kan lori ayelujara, Odumayo Funke Olufemi tawọn eeyan mọ si Odumayo 2000 tiẹ sọ pe o ṣee ṣe ki Sam Larry ti dagbere faye lẹyin ijamba ọkọ to ṣẹlẹ naa.
Amọ, akọroyin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Mr LilGaga lori itakun ayelujara sọ pe irọ nla ni iroyin ti Odamayo 2000 n gbe kaakiri.
Mr LilGaga sọ fun gbogbo eeyan pe ko si nnkankan to ṣe Sam Larry, tori pe oun si ba a sọrọ lẹyin ijamba to ṣẹlẹ naa.
Ko si ẹni to le sọ pato ipo ti Sam Larry wa bayii, bawọn kan ṣe n sọ pe o fẹsẹ ṣeṣe lawọn mii n sọ pe Eledua nikan lo le ko o yọ nibi to farapa de.
Amọ, ẹnikẹni ko tii le sọ bayii bi ohun to ṣẹlẹ si Sam Larry ṣe pọ to.
Baba mi da? Ọmọ Adewale ẹṣọ Sam Larry to ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ kerora
Ninu ibanujẹ ọkan ni ẹbi Adewale, ẹṣọ Sam Larry to ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lopopona marosẹ Eko si Calabar wa bayii.
Fidio kan lori itakun ayelujara ṣafihan bi iyawo oloogbe ati ọmọ rẹ kan ṣe n ke irora lẹyin ti wọn gbọ iroyin iku Adewale.
Fidio naa ṣafihan bi iyawo Adewale ṣe jokoo silẹ to n sunkun nigba tawọn ẹbi atawọn ọrẹ n kẹdun pẹlu rẹ.
Bi iyawo Adewale ṣe n sunkun ninu fidio naa ni aburo rẹ obinrin naa n dami loju poro poro.
Bakan naa ni ọmọdebinrin kan ti ọkunrin kan gbe mọra n sunkun ti o si n sọ pe ''baba mi, baba mi, ẹ gbe baba mi wa o.''
Bi ọmọ yii ṣe n ke lawọn ẹbi naa n sunkun ni asun gba.
Ọkọ ti Adewale ati Sam Larry wa ninu rẹ ni a gbọ pe o fori sọ ọkọ tirela kan nibi ti Adewale ti ku lẹsẹ kẹsẹ.
Fidio to ṣafihan bi ẹbi Adewale ṣe n ṣọfọ iku rẹ ti tan kaakiri oju opo ayelujara
Ta a ni Sam Larry?
Samson Erinfolami Balogun tawọn eeyan mọ si Sam Larry jẹ oniṣowo ati agborin-larugẹ to gbajugbaja nipinlẹ Eko ati lorilẹede Naijiria.
Odu ti kii ṣe aimọ fun oloko ni Sam Larry lagbo awọn olorin ni orilẹede Naijiria.
O ti ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ilumọọka olorin bii Naira Marley, Portable ati Mohbad to ti doloogbe bayii.
Lọjọ keje oṣu Kinni ọdun 1980 ni a bi Sam Larry nipinlẹ Eko, eyi to tumọ si pe ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni i ṣe.
Olamide Ajike ni orukọ iyawo Sam Larry, kii sii saba sọ nnkankan nipa iyawo rẹ nita.
Eyi ni ko jẹ ki awọn eeyan mọ nnkan pupọ nipa Olamide.
Eledua si fi ọmọkunrin kan ati ọmọbinrin kan da igbeyawo wọn lọla.
Ẹnu bẹrẹ sii kun Sam Larry lọdun 2023 nigba ti ọdọmọde olorin takasufe Mohbad ku lojiji.
Nigba naa ni wọn fẹsun kan an wi pe o huwa ipa si Mohbad nigba aye rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fọwọ ofin mu Sam Larry ati akọrin Naira Marley lori ọrọ naa.
Amọ, wọn pada fi awọn mejeeji silẹ loṣu Kọkanla ọdun 2023.




























