Oyún ọmọ mi kejì kò tíì pé oṣù mẹ́ta, tí mo fi kan ìdààmú nínú ìgbéyàwó, mo sun ṣégè ẹkún - Wasila Coded
Lara awọn gbajumọ osere tiata lobinrin, Bimpe Akintunde jẹ gbajumọ osere to ti ko ipa to pọ ninu ọpọ sinima.
Bimpe, ti ọpọ eeyan tun mọ si Wasila Coded, lo jẹ ọmọ bibi ilẹ Ijebu, to si maa n ko oniruuru ipa ninu ere.
Laipẹ yii ni ariwo sọ lori ayelujara pe igbeyawo to sẹsẹ se ti daru.
Asiko yii si lo foju han pe oyun ti wa ninu Bimpe nigba naa, tiọkunrin to loyun fun ko si beere rẹ mọ titi to fi bimọ.
BBC News Yoruba fi ọ̀rọ̀ wá Wasila Coded lẹ́nu wò láti mọ ọ̀pọ̀ ìrírí tó là kọjá lásìkò ìṣòro náà àti imọ̀ràn rẹ̀ fáwọn obìnrin tó wà ní irú ipò yìí.

"Bi mo se n sunkun ninu oyun ọmọ keji, naa ni ẹgbọn rẹ n ba mi sunkun"
Bimpe Akintunde, lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ salaye pe ẹkun ni oun maa n sun lasiko ti oun loyun ọmọ oun keji, ti baba rẹ si kọ oun silẹ.
"Mo sun sege ẹkun ninu oyun ọmọ mi keji, ki Ọlọrun ba mi wo o.
Mo maa n sunkun, ẹgbọn ọmọ naa yoo tun maa ba mi sunkun.
Ohun rere ni Ọlọrun fi ọmọ yẹn se fun mi tori pe oyun rẹ ko tii pe osu mẹta ninu mi, ti mo ti bẹrẹ si ni kan idaamu ninu igbeyawo yẹn.
Lo ba di pe ko maa ni pe se oun lo maa kọkọ loyun ni, iru oyun wo gan lo ni?
Ọlọrun ko si fi oyun yẹn da mi laamu o."
Bimpe Akintunde wa gba awọn obinrin nimọran pe ti wọn ba pade ọkunrin kan to ni iyawo ni oun fẹ fẹ, oun ko fẹ fi akoko obinrin sofo.
"Emi kori nnkan to buru ninu ki obinrin se iyawo keji, ikẹta, ikẹrin lọdọ ọkunrin kan amọ ẹ mase fẹ ọkunrin to ba n le iyawo kan lọ, ko to fẹ omiran"
Ninu ifọrọwerọ naa, Bimpe Akintunde tọ awọn obinrin sọna lati mọ awọn iwa to yẹ ki wọn sa fun lara awọn ọkunrin, ki wọn ma baa jin si ọfin gẹgẹ bi ti oun.
"O yẹ ki obinrin gbinyanju ki ẹ tiẹ dọrẹ pẹlu ọkunrin naa, ko le mọ ibi ti ọkunrin naa ti n bọ ati ibi ti obinrin yẹn naa n lọ.
To ba jẹ pe mo dọrẹ pẹlu ọkunrin naa ni, gbogbo nnkan to se mi yẹn, ko ba ma sẹlẹ si mi.
Emi kori nnkan to buru ninu ki obinrin se iyawo keji ati ikẹta, ikẹrin lọdọ ọkunrin kan.
Sugbọn ka wa wa, ti o ba ri ọkunrin to ni iyawo meji ninu ile, to ni iyawo akọkọ ti lo ogun ọdun lọdọ oun, ti iyawo keji si ti lo ọdun mẹwa, mo fi ọwọ si pe ki eeyan fẹ iru ọkunrin bẹẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe ile olorogun, ọgba were ni."
Osere tiata naa tun gba awọn obinrin nimọran pe ti wọn ba ri ọkunrin to fẹ fẹ wọn, to si ni oniyawo pupọ ni oun, o yẹ ki ẹ́ beere ibi tawọn iyawo rẹ wa?
Amọ, o ni ti ọkunrin naa ba ni gbogbo awọn iyawo oun naa ti lọ, ko yẹ ki obinrin fẹ iru ọkunrin bẹẹ nitori pe awọn asiwaju rẹ ko duro, ki ni oun fẹ fi duro nibẹ?
"Mo kan maa rọ awọn obinrin pe ki wọn kẹkọ lati ara irinajo mi ninu igbeyawo."
"Emi ko lọ sile ọkọ kan ri, ẹyin ọdun kẹjọ ti mo bi akọbi mi, ni mo sẹsẹ wa ri ọkọ ti mo fẹ fẹ"
Ọpọ eeyan lo n ka ọkọ si Bimpe Akintunde lọrun pe o ti bimọ fun baba meji, ti ko si duro nile ọkọ kan.
Ninu ọrọ rẹ, gbajumọ osere naa ni ẹni to ba ka, oun ni ẹnu maa ro.
"O dara ki eeyan kuro ninu igbeyawo kan ni aaye, ju ki wọn gbe oku rẹ kuro ninu igbeyawo lọ.
Emi bii ẹnikan fẹran igbeyawo amọ lọpọ igba, kii dun mọ obinrin to ba fẹ ọkọ kan ju ẹyọ kan lọ ninu.
Emi ko lọ sile ọkọ kan ri amọ oore ọfẹ ati oore idunnu ni akọbi mi jẹ fun mi.
Ẹyin ọdun kẹjọ ti mo bi, ni mo sẹsẹ wa ri ọkọ ti mo fẹ fẹ.
Ọpọlọpọ lo n kaanu mi pe lẹyin ọdun mẹjọ, wọn tun se bayii fun mi, amọ akọsilẹ onikaluku yatọ."
"Emi si maa fẹ ọkọ si o abi ọmọ ọdun melo ni mi?"
Osere tiata naa wa fidi rẹ mulẹ fun BBC News Yoruba pe oun si maa fẹ ọkọ si tori ọjọ ori oun kere lati da duro.
"Emi si maa fẹ ọkọ si o abi ọmọ ọdun melo ni mi?
N ko le fẹ ọkọ to ba ni ki n ma sisẹ tiata amọ mo maa fẹ ọkunrin to maa ti mi lẹyin nidi isẹ yi.
Mo n rọ awa obinrin to bi awọn ọkunrin pe ka jẹ ki awọn ọmọkunrin wa mọ bi wọn ti n se pẹlu obinrin, agaga to ba wa nipo oloyun.
To ba wa jẹ obinrin, ti ko si si ẹnikẹni lati ran ọ lọwọ, lati ba ẹ gbe ẹru awọn ọmọ rẹ, iwọ naa, san ọja rẹ ko le.
Mase ronu, mase bara jẹ, ma si rẹwẹsi, o le jẹ ibi ti o ti n ja lanba kiri lo maa ti ri oluranlọwọ."
Bimpe Akintunde tun rọ awọn obinrin lati wa isẹ se, ki wọn ma si se fi ironu se ara wọn lese, ki wọn di opo Ọlọrun ọba mu, ki wọn o si mu isẹ wọn ni ọkunkundun.
O tun rọ awọn obinrin to wa nile ọkọ gan, pe ki wọn mase da ọwọ delẹ maa duro ki ọkọ wọn de, amọ ki wọn wa isẹ se.






