Dibu Ojerinde Corruption Case: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ní òun kò fi orúkọ àwọn iléeṣẹ́ náà sílẹ̀ láti ba ọ̀gá òun ní orúkọ jẹ́

Published

Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fun ọ̀gá àgbà ajọ JAMB tẹ́lẹ̀ ti jẹ́rìí lórí àwọn dúkìá tí ọ̀gá rẹ̀ ní.

Peter Oyewole, tii se oludamọran lori ọrọ ofin sí ọga agba ajọ JAMB tẹlẹ rí, Ọjọgbọn Dibu Ojerinde ti ṣalaye fun ileẹjọ awọn ohun ti ọga rẹ ra lori ipo.

O tun sọ bi ọga rẹ ṣe ṣi ileeṣẹ mẹjọ ni igba to wa lori oye gẹgẹ bí alaṣẹ ajọ JAMB.

Peter Oyewole, lasiko to n jẹri niwaju ile ẹjọ bii ẹlẹrii fun ajọ ICPC lori ẹsun lilu jibiti owo to to biliọnu marun ati diẹ naira (N5,2bn) ti wọn fi kan Ojerinde, lo sisọ loju awọn ọrọ naa.

Oyewole tun salaye ni Ọjọru pe Ọjọgbọn Ojerinde tun kọ ile mẹta.

O ni ọga agba ajọ JAMB tẹlẹ tun dokoowo pẹlu awọn ile ifowopamọ kan nigba to wa ni ọfiisi.

Awọn ohun ti wọn ni ọga agba JAMB ra ree nigba to wa lori oye:

Oyewole jẹrii pe ile nla meji ati pẹtẹẹsì kan wà lara awọn dukia ti Ọjọgbọn Ojerinde ra nigba naa.

Awọn dukia mii ni ilegbe awọn akẹkọọ, Oke-Afin Boys and Girls hostel Ltd, Sapati Int'l School, Doyin Ogbohi Petroleum Ltd, Cheng Marbles Ltd.

Awọn mii tun ni Standout Institute Ltd, Trillion Learning Centre Ltd, Grace Petroleum Ltd àti Ifelodun Communications Ltd.

Oyewole wa ko gbogbo awọn iwe ẹri to lo fi ṣe iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ naa wa sile ẹjọ gẹgẹ bi ẹri.

Ẹsun ti ajọ ICPC fi kan Ọjọgbọn Ojerinde to jẹ ọga agba JAMB tẹlẹ niyii:

Ẹsun lilu owo to le biliọnu marun un, N5.2bn, ni ponpo nigba to wa ni ọfisi gẹgẹ bi ọga agba ajọ JAMB ni wọn fi kan Ọjọgbọn Ojerinde.

Ni ileẹjọ ijọba apapọ to wa niluu Abuja ni igbẹjọ ọhun ti n waye.

Níbẹ ni amofin Oyewole ti jẹrii pe oun ni oun ba Ọjọgbọn Ojerinde ṣe iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ to da silẹ nigba ti o fi jẹ ọga ajọ JAMB.

Agbẹjọro ajọ ICPC, Ebenezer Sogunle lo mu Oyewole wa sile ẹjọ lati jẹrii tako Ọjọgbọn Ojerinde.

Oyewole sọ fun adajọ Obiora Egwuatu pe orisiirisii orukọ ni Ọjọgbọn Ojerinde lo lati ṣe iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ naa.

N ko se iforukọsilẹ ileesẹ fun Ojerinde lati ba ni orukọ jẹ:

O ni meji pere ninu awọn ileeṣẹ naa ni orúkọ Ojerinde wa gẹgẹ bi alakosoo nigba to lo orukọ awọn eeyan mii fawọn ileeṣẹ yoku.

Oyelowo ni oun ko tiẹ ba ọkankan ninu awọn eeyan naa pade ri.

O fikun ẹri rẹ pe, awọn eeyan ti Ojerinde lo orukọ wọn ni Ojerinde Dayo, Ojerinde Olumide, Awodayo Habib, Adeyanju Gbenga, Ojerinde Olutoyin, Ojerinde Akanbi, Ojerinde Adedayo, Olayiwola Ayanwale, Ibrahim Danmusa ati Sanusi Alade Najeem.

O ṣalaye ṣiwaju sii oun ko ṣe iforukọsilẹ dukia fun Ọjọgbọn Ojerinde lati ba a lorukọ jẹ.

Oyewole to jẹ ọmọ ilu Igboho kan naa pẹlu Ojerinde ni ohun ti o sọ foun ni oun n ṣe.

Amofin Oyelowo tun ṣafihan iwe mejila ti oun ati Ọjọgbọn Ojerinde kọ si ara awọn l'asiko iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ naa.

Bakan naa lo tun ṣafihan ẹda awọn iwe metadinlogun to fi awọn ileeṣẹ loriṣiiriṣii.

Ki ni agbẹjọro Ọjọgbọn Dibu Ojerinde sọ?

Amọ ṣa, Ibrahim Ishiyaku (SAN) to jẹ agbẹjọro fún Ọjọgbọn Ojerinde ko le beere nkankan lọwọ Oyelowo nitori o ni awọn iwe ẹri ti Oyelowo ko wa sile ẹjọ ko si lara ẹri ti wọn fi han oun.

O rọ ile ẹjọ lati sun igbẹjọ naa siwaju ki o le lanfaani lati wo awọn ẹri naa finnifinni.

Lẹyin naa ni adajọ Egwuatu sun igbẹjọ si ọjọ kẹrin àti ikarahun oṣu kẹrin odun yii.

Ta ni Dibu Ojerinde:

Ọjọgbọn Dibu Ojẹrinde jẹ olukọ agba nile ẹkọ fasiti, ki wọn to yan si ipo ọga agba fun ajọ to n se kokari idanwo asewọle sawọn ile ẹkọ giga nilẹ wa, JAMB.

Ọjọ Kẹwaa osu kẹrin ọdun 2012 ni wọn yan ggẹ bi ga ajọ JAMB, to si kuro ni ipo naa ni ọjọ kinni osu kẹjọ ọdun 2016.

Ojerinde, tii se ọmọ bibi ilu Igboho nipinlẹ Oyo lo ọdun mẹrin gbako gẹgẹ bi ọga agba fun ajọ JAMB naa.

Saaju lo ti kọkọ jẹ Akọwe agba fun ajọ to n se kokari idanwo asejade nile ẹkọ girama, NECO.

Ọdun 1999 si ọdun 2007 si lo fi jẹ akọwe agba fun ajọ NECO naa.

Ọdun 2021 ni ajọ ICPC fi ẹsun onikoko mejidinlogun kan Ọjọgbọn Ojerinde, eyi to da lori lilu owo ijọba ni ponpo.