You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
5G network: Báyìí tí ìjọba Nàìjíríà ti buwọ́lù ìfilọ́lẹ̀ 5G, kí làwọn ǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀?
Ijọba orileede Naijiria lẹyin atotonu pupọ ti pada buwọ́lu lilo ẹrọ alatagba itakun agbaye 5G.
Minisita feto ibaraẹnisọrọ, Ọjọgbọn Isa Pantami fi ikede yi sita lọjọru pe igbimọ alaṣẹ Naijiria ti faṣẹ si lilo ẹrọ alatagba yi.
Ikede yi ni lẹsẹkẹsẹ ni 5G ti bẹrẹ si ni di lilo labala ti yoo waye laarin asiko yi si ọdun 2025.
Bayi to ti wa di lilo, yoo ṣe ọpọ ọmọ Naijiria lanfaani lati mọ si nipa ẹrọ alatagba yi, paapa pẹlu bi awọn orisirisi iroyin eyi to jẹ ootọ ati ayederu ti ṣe n kaakiri lori 5G.
Nkan pataki to yẹ ni mimọ nipa 5G ree taa se atupalẹ rẹ:
Njẹ ajọṣepọ wa laarin 5G ati Covid-19 ?
Nigba ti ijọba Naijiria kọkọ mẹnu ba lilo 5G, o bọ si asiko igba ti ajakalẹ aarun Covid-19 bẹrẹ si ni gbode ni dun 2020.
Lasiko naa, awọn ọmọ Naijiria kan n bẹru pe 5G yi ni ipa to n ko lori itankalẹ Covid-19.
Lati le ṣalaye aarin yi, ijọba Naijiria sọ pe awọn kan si ajọ meji pataki-ajọ ilera lagbaye,WHO, ati ajọ to n risi ọrọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ lagbaye,ITO.
Awọn mejeeji yi fidi ọrọ mulẹ pe ko si ibaṣepọ laarin awọn mejeeji ati pe 5G ko ni nkankan ṣe pẹlu itankalẹ aarun Covid-19.
Diẹdiẹ ni wọn fẹ bẹrẹ lilo 5G.
Ẹrọ alatagba yi ko le kaakiri gbogbo Naijria lẹẹkan naa.
Idi ni pe awọn nkan eelo rẹ yoo maa de agbegbe kọọkan lẹsẹlẹsẹ ni.
Awọn ilu nla bi Eko, Abuja ati awọn miran lo ṣeeṣe ki wọn kọkọ bẹrẹ si ni jẹ anfaani lilo 5G yii.
Naijiria nikan kọ lo wa ni ipele ṣiṣe amulo 5G bayi
Ninu alaye ti Minisita Pantami ṣe fawọn akọroyin, o ni orileede Amẹrika, United Kingdom ,Switzerland,Germany ati awọn orileede Europe mii ti n ṣe amulo 5G.
Ni Afirika, South Africa ati Lesotho naa ti n lo.
Lawọn to wa ni ipo ti Naijiria wa pẹlu 5G la ti ri awọn orileede bi Kenya, Uganda, Morocco ati Egypt.
Lilo oju opo ayelujara yoo ma a yá ju ti tẹlẹ lọ
Ninu awọn anfaani ti 5G yoo mu wa fawọn to n lo ni pe data taa n lo yoo maa ṣiṣẹ ni kiakia ju ti 4G ti ọpọ n lo bayi.
Fun apẹẹrẹ, bi eeyan ba fẹ wo fidio lori ẹrọ ayelujara tabi to ba fẹ 'download' rẹ, asiko ti yoo fi le ṣe eleyi lori 5G yoo ya ju ti 4G lọ.
Fawọn to ba tun wa lẹka aabo bi awọn ọmọ ogun Naijiria, 5G yoo fun wọn lanfaani lati tete ṣe awọn iṣẹ to nilo ẹrọ alatagba ni kiakia.
Ẹka ifowopamọ,ẹkọ ati ọrọ aje miran naa yoo ri data 5G lo nipa mimu iṣẹ wọn ya, ti awọn onibaara ko si ni gba akoko to pẹ lati se karakata eyi keyi ti wọn ba fẹ ṣe.