Bodija Plank Market: Iná tún ṣẹ́ wọ ìsọ̀ pákó ni Bodija ìlú Ibadan

Published

Ìsọ pákó tó jẹ́ gbájúgbajà ní ìlú Ibadan tí múná, gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ

Nínú fọ́nran kan to n lọ lójú òpó twitter ni àwọn ènìyàn ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, bákan náà ni àwọn tó ni sọ́ọ̀bù nínú ọjọ́ náà tí wọ́n sì bá òṣìṣẹ́ BBC Yoruba sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, iná náà kọjá sísọ.

Nínú fọ́nran ọ̀hún bákan náà ni a ri àwọn ara àdúgbò tí wan ń sá kíjokíjo ti wọ́n sì n pè fún ìrànwọ́ àwọn panápaná.

Láipẹ̀ yìí ni ìsọ̀ páàtì ọkọ̀ jónà ti ọ̀pọ̀ àwọn olùtajà agbègbè náà sí n ka òfò wọ́n lọ́wọ́ ki èyí tún tó wáye