Aárò Dino ń sọ àwọn aṣòfin; Mammadou dọmọ onilu ni France
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Attahiru Jega pe àwọn Asòfin ní olè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaga ajọ to ń rísí ètò ìdìbò Nàìjíríà (INEC) tẹlẹri, Ọjọgbọn Attahiru Jega, ni ọ̀nà àbáyọ ni ki a dẹ́kun rìbá gbígbà ni Naijiria.
Attahiru Jega ti fi ẹsun kan awọn Ile Igbimọ Asofin lorilẹ-ede Naijiria pe wọn fẹran lati ma a gba owo ni ọna ẹburu lati le se isẹ wọn.
Jega sọ ọrọ yii nibi to ti n se idanilẹkọọ lori ayajọ Ọjọ Iṣejọba Tiwantiwa (Democracy Day) t'ọdun yii ni Abuja lorilẹ-ede Naijiria.
Nigeria vs DR Congo: Eagles gbá ọ̀mì pẹ̀lú Leopard ní Pọtá

Ìkọ agbaboolu Super Eagles orílè-èdè Nàìjíríà ati akẹgbẹ wọn láti orílè-èdè DR Congo ti gba àmì ayò kọọkan nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọrẹsọrẹ
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà wà lára ipalemo ìkọ Super Eagles ṣaaju ìdíje ife ẹyẹ àgbáyé to n bò lónà ní Russia. E ka ekunrere re ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Aliu Sodiq mú ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn àwọn ènìyàn nípà ìrírí mọ́ṣúàrì.

























