Coronavirus Cases in Africa: Àráàlú ló kù, ìjọba ń tiraka lórí àrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others
Oludasilẹ ati Pasitọ Agba Ijọ Daystar Christian Centre, Sam Adeyemi ti kesi awọn araalu lorilẹede Naijiria paapaa ni ipinlẹ Eko lati tẹle aṣẹ ijọba lori arun Coronavirus.
Pasitọ Adeyemi fi ero rẹ han lasiko ifọrọwanilẹnuwo lori ẹrọ ikansiraẹni ti BBC News Yoruba.
Adeyemi ni ijọba n tiraka lati ri wi pe wọn sa gbogbo ipa wọn lati gbogun ti itankalẹ arun Coronavirus lorilẹede Naijiria, amọ awọn eniyan ko kọ ibi ara si gbogbo ilakalẹ ijọba lori yiyago fun ara ẹni ati fifọ ọwọ loorekoore.
O ni o ku diẹ kaato pẹlu bi ijọba se jẹ ki ofin konile-o- gbele rọlẹ ni ipinlẹ Eko, eleyii to ni o jẹ ki awọn eniyan kọ lati tẹlẹ gbogbo eto ti ajọ eleto ilera ti la kalẹ fun awọn eniyan lati ri wi pe arun Coronavirus ko tankalẹ ju bo ṣẹ lọ.
Pasito Ijọ Daystar Christian Centre parọwa si ijọba wi pe ki wọn jẹ ki ofin konile o gbele ọlọjọyipo o pada lati le dẹkun itankalẹ arun Coronavirus nitori orilẹede Naijiria ko ni eto ilera to peye lati koju arun Coronavirus to ba ju bo ṣe lọ.
‘Imọ ẹrọ 5G ko niiṣẹ pẹlu arun Coronavirus’
Oludasilẹ ati Pasitọ Agba Ijọ Daystar Christian Centre, Sam Adeyemi tun ti fi idi rẹ mọlẹ wi pe imọ ẹrọ 5G ko ni nkan ṣe pẹlu arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Others
Pasito Sam Adeyemi ni iwe itan ni ohun ti ri ka wi pe ajakalẹ arun ti sẹlẹ ri lorilẹede Naijria ni bi ẹgbẹrun ọdun sẹyin ti o si pa ọpọlọpọ eniyan.
Wọn fikun wi pe, nigba ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ko i tii si imọ ẹrọ kankan, bẹẹ ọpọlọpọ ẹmi si lọ si ajakalẹ arun naa.
Nitori naa ni Adari ijọ Daystar Christian Centre, Sam Adeyemi naa wa rọ awọn eniyan lati fẹran ara wọn nitori ifẹ ni akoja ofin.
























