Fatima Ribadu and Aliyu Atiku wedding: Ṣé lóòtọ́ ni Nuhu Ribadu àti Atiku Abubakar fẹ́ di àna láì fi ti òṣèlú ṣe?

Aliyu Atiku ati Fatima Ribadu

Oríṣun àwòrán, Abdallah Yunus Abdallah/twitter

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ọdun diẹ sẹyin, Nuhu Ribadu gẹgẹ bi olori ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, tanna wadii Atiku abubakar, to jẹ Igbakeji Aarẹ Naijiria. Ṣugbọn lonii, awọn mejeeji ti fẹ ẹ di ana.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe Fatima Ribadu, to jẹ ọmọ Alaga akọkọ fun ajọ EFCC, Nuhu Ribadu, ti fẹ ẹ di iyawo Aliyu Atiku, to jẹ ọmọ igbakeji aarẹ nigba kan, Atiku Abubakar.

Ọjọ Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni iroyin sọ pe ayẹyẹ igbeyawo naa yoo waye, gẹgẹ bi akọsilẹ to wa lori kaadi ipe sibi igbeyawo ti BBC ri.

Iwe ipe sibi igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Others

Amọ , Fatima Ribadu ati Aliyu atiku, ko ti i sọ ohunkohun lori iroyin naa.

Aliyu Atiku Abubakar jẹ jẹ oye Turaki Adamawa.

Ọwọ baba rẹ, Atiku Abubakar lo ti jogun oye naa, lẹyin ti Atiku fi silẹ lati joye Waziri Adamawa lọdun 2017.

Aliyu Atiku ati Fatima Ribadu

Oríṣun àwòrán, Alhaji IU Wakili/twitter

Oye Turaki Adamawa jẹ ọkan lara awọn oye pataki ninu eto lọbalọba nipinlẹ Adamawa.

Bakan naa ni Aliyu jẹ oṣiṣẹ banki, to si tun jẹ Oludari ileeṣẹ Priam Group, to jẹ apapọ gbogbo ileeṣẹ ti baba rẹ da silẹ. Awọn ileeṣẹ naa lo ni oṣiṣẹ to pọju lọ nipinlẹ Adamawa.

Aliyu Atiku ati Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, American University of Nigeria

Fatima Ribadu jẹ ọkan lara ọmọ marun-un ti Nuhu Ribadu bi.

Bakan naa lo jẹ ọrẹ timọtimọ pẹlu ọmọ Aarẹ Muhammadu Buhari, Hanan, to sẹ igbeyawo laipẹ yii.

Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria si ti n sọ oriṣiriṣi nkan nipa igbeyawo awọn ọmọ agba oloṣelu mejeeji.

Paapa nitori pe ẹgbẹ osẹlu ọtọọtọ ni wọn n ṣe: Atiku Abubakar jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, Nuhu Ribadu si jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, amọ ipinlẹ Adamawa ni awọn mejeeji ti wa.

Ohun ti ọpọ eeyan n sọ lori ọrọ igbeyawo naa ni pe awọn oloṣelu Naijiria kii ṣe ọta ara wọn, tako bi awọn araalu sẹ n ri wọn.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe o yẹ ki awọn ọmọ Naijiria to ma n ba ara wọn ja nitori oloṣelu tun ero ara wọn pa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5