You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iyabo Ojo bèèrè 1bn lọ́wọ́ Naira Marley
Gbajumọ oṣerebinrin, Iyabo Ojo, ti beere biliọnu kan Naira lọwọ akọrin takasufe, Naira Marley.
Ninu atẹjade kan ti Arabinrin Ojo fi si ori Instagram rẹ lọsan ọjọ aje, lo ti kede pe oun beere owo naa lọwọ Azeez Fashola, nitori pe o ba oun l’orukọ jẹ.
Ọsẹ to kọja ni agbẹjọro Naira Marley kede pe akọrin naa n beere ọgọrun miliọnu Naira lọwọ Iyabo Ojo, to si tun ni o gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ oun ninu iwe iroyin kan.
Naira Marley fi ẹsun kan Iyabo Ojo ati awọn eeyan mii, to fi mọ ileeṣẹ iroyin Punch, pe wọn ba oun lorukọ jẹ nitori iku akọrun, Imole aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad.
Akọrin naa sọ pe awọn ọrọ ti Arabinrin Ojo sọ, n tọka si oun gẹgẹ bi ẹni to pa Mohbad.
Ileeṣẹ orin Naira Marley lo gbe awọn orin Mohbad jade nigba aye rẹ.
Ṣugbọn ninu iwe ipẹjọ ti oun naa fi sita gẹgẹ bi esi si Naira Marley, Iyabo Ojo sọ pe oun gbe igbesẹ naa nitori pe agbẹjọro rẹ, Olalekan Ojo, ko fun oun ni iwe ipẹjọ lọna to yẹ, to si tun dunkooko mọ oun lori ayelujara.
Ileeṣẹ ofin to n ṣoju oṣerebinrin naa, Maverick Forte Legal, sọ ninu iwe ti wọn fi ranṣẹ si agbẹjọro Naira Marley, eyi ti Iyabo fi ẹ̀dà rẹ si Instagram, pe awọn pinnu lati fi esi fun -un, lẹyin ti iwadii fihan pe lootọ, lati ọdọ agbẹjọro Olalekan Ojo, ni iwe ẹjọ naa ti wa, botilẹ jẹ pe titi di asiko yii, wọn ko fi iwe ranṣẹ si onibaara awọn, bu ori ayelujara ti wọn fi si lọ.
“Onibaara wa (Iyabo Ojo) ri bi ileeṣẹ amofin to n ṣoju Naira Marley, ṣe fi iwe ẹjọ ti wọn pe e si ori ayelujara, lai kọkọ fi ranṣẹ si ẹni ti wọn n ba ṣe ẹjọ, gẹgẹ bi ọna lati ba orukọ rere rẹ jẹ.
“Yatọ si eyi, igbesẹ naa jẹ amọọmọ ṣe, lati le fi sinu ewu eebu lori ayelujara, aibalẹ ọkan, to si tun le mu ki awọn ileeṣẹ to n ba polowo ọja o sa kuro lọdọ rẹ.”
Awọn nnkan ti Iyabo Ojo n beere lọwọ Naira Marley
Ileeṣẹ agbẹjọro to n ṣoju Iyabo Ojo sọ pe awada ni awọn nnkan ti Naira Marley n beere lọwọ rẹ jẹ.
Wọn ni, awọn ko si ni tẹti lati gbe ọrọ lọ sile ẹjọ, to ba fi kọ lati da awọn ibeere rẹ nu.
“Onibaara n beere fun biliọnu kan Naira fun pe awọn agbẹjọro Naira Marley fi iwe ipẹjọ rẹ si ori ayelujara, pẹlu erongba lati ba a lorukọ jẹ.
“Igbesẹ wọn ti mu ki onibaara wa padanu awọn ọna ti owo n gba wọle fun, to si tun sọ ọ di eniyan yẹpẹrẹ loju awọn eeyan ni Naijiria, nilẹ okeere, ati lọdọ awọn ileeṣẹ to jẹ aṣoju fun.
Wọn tun sọ ninu iwe naa pe, onibaara awọn tun le beere biliọnu kan miran, fun pe ori ayelujara ni wọn fi iwe ipẹjọ wọn si, lai kọkọ fi ranṣẹ si i.