You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
America dá Deborah Samuel akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n pa ní Sokoto lọ́lá
Orile-ede America ti fi ami ẹyẹ da Deborah Samuel, akẹ́kọ̀ọ́ ile ẹ̀kọ́ giga àwọn kan pa nipinlẹ Sokoto nitori pe 'o sọ̀rọ̀ odi si Anabi'.
America fi fun oloogbe naa ni ami ẹyẹ ni ayajọ ọjọ́ ti wọn n mọ riri àwọn to kú nitori ija ẹsin.
Àjọ America to n rí si ominira ninu ẹsin lagbaye sọ pe àwọn da Deborah Samuel lọla nitori o fi oju wina ifiyajẹni, wọn lu u, wọn tun sọ ọ ni okuta pa, ki wọn to dana sun.
" A da aye rẹ lọla, pẹlu bi a ṣe n tesiwaju lati fi opin si iru iwa jagidijagan bẹẹ."
Bawo ni wọn ṣe pa Deborah?
Oṣù karun-un, ọdun 2022 ni wọn pa Deborah ni Shehu Sagari College of Education n'ilu Sokoto, nitori 'ọrọ odi' ti wọn lo sọ si anabi lori ayelujara WhatsApp.
Akẹẹgbẹ rẹ kan ni iroyin sọ pe o kọ ọrọ kan nipa ẹsin si ori WhatsApp ti wọn ti ma n sọ̀rọ̀ nipa eto ẹ̀kọ́ kilaasi wọn.
Ọ̀rọ̀ naa ni Deborah fi esi si, ti wọn lo jẹ ọrọ odi.
Eyi to mu ki awọn akẹkọọ kan fi ipá wọ ọ jade ni ibi to n gbé, ti wọn si fi igi ati okuta pa a ki wọn to dana sun oku rẹ.
Fidio bí iṣẹlẹ naa ṣe waye gba ori ayelujara to si fa àríyànjiyàn pupọ.
Iṣẹlẹ naa fa rogbodiyan nipinlẹ naa, eyi to mu ki gomina ibẹ fi ofin de lilọ-bibọ fun wakati mẹrinlelogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Sokoto sọ pe àwọn mu afurasí meji to jẹ akẹẹkọ ilé ẹ̀kọ́ naa.
Lẹyin naa ni awọn alaṣẹ ile ẹ̀kọ́ naa pàṣẹ fun gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lati ma a lọ sile àwọn obi wọn.
Baba oloogbe sọ pe ọdún yii lo yẹ ko kẹkọọ jad.