Àwọn agbófinró nawọ́ gán Adeyemi, Ọ̀gá àgbà ayédèrú àjọ PFIPC lẹ́yìn tó kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́

Ọmọba Adeyemi Adeniyi wọ agbada funfun ati fila

Oríṣun àwòrán, Prince Adeyemi Adeniyi/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn agbofin ti fọwọ ofin Adeyemi Adeniyi, ẹni to n jẹjọ lori ẹsun pe o ṣe idasilẹ ayederu ileeṣẹ ijọba Presidential Foreign Intervention Promotion Council, PFIPC.

Ṣaaju nile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti paṣẹ wi pe ki wọn fọwọ ofin mu Ọmọba Adeniyi, lẹyin to kọ lati yọju sile ẹjọ lonii ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinla oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Adajọ Muhammed Umar paṣẹ naa lẹyin ti agbẹjọro ileeṣẹ ọlọpaa to gbe Adeyemi lọ si ile ẹjọ, Wisdom Madaki, da aba naa fun ile ẹjọ.

Ẹsun onikoko mẹjọ to da lori iwe yiyi, jibiti ati pipe ara rẹ ni nnkan ti ko jẹ ni wọn fi kan an.

Bo tilẹ jẹ wi pe Ọgbẹni Genesis Francis to jẹ agbẹjọro Adeyemi kede wi pe yoo yọju sile ẹjọ, ko pada yọju sibẹ.

Lẹyin naa ni igbimọ olupẹjọ sọ pe o ti to igba meloo kan bayii ti Adeyemi ko ti yọju sile ẹjọ nigba kugba ti igbẹjọ naa ba ti fẹ waye.

Agbẹjọro awọn ọlọpaa sọ fun ile ẹjọ wi pe o ti di igba marun un ti Adeyemi ti kọ lati yọju sile fun igbẹjọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Bayii ni agbẹjọro ọlọpaa rọ ile ẹjọ pe ko paṣẹ wi pe ki wọn fọwọ ofin gbe e; eyi to sọ pe o wa ni ibamu pẹlu abala 394 iwe ofin Naijiria.

Agbẹjọro Adeyemi tako aba naa, o si sọ pe onibaara oun kọ lati yọju sile ẹjọ tori awọn to n dunkoko mọ ọn lati ṣekupa a.

Ọgbẹni Francis ran ile ẹjọ leti wi pe Adeyemi yọju sile ẹjọ lọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un ti igbẹjọ naa waye.

Lẹyin ti o gbọ awijare awọn agbẹjọro mejeeji tan ni adajọ paṣẹ pe kawọn agbofinro lọ fọwọ ofin mu un.

Adajọ tun fidi rẹ mulẹ pe ẹẹkan ṣoṣo ni Adeyemi ti yọju sile ẹjọ lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ.

Adajọ Umar wa paṣẹ faṣọ agbofinro lati mu Adeyemi wa sile ẹjọ lọgbọnjọ oṣu Kẹsan an.

Amọ, lonii gan na ni ọwọ awọn agbofinro tẹ Adeyemi.

Koko awọn ohun ti ijọba fẹ ṣe iwadii rẹ nipa Adeyemi Adeniyi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade naa sọ pe Tinubu paṣẹ ki wọn ṣe iwadii iwe igbanisiṣẹ ti adari ajọ ofege naa, Adeniyi Adeyemi Mathew, n lo.

Iwadii naa yoo tun tu pẹrẹpẹrẹ bi ọgbẹni Adeniyi Adeyemi Mathew ṣe ri iwe igbanisiṣẹ lati ọọfisi Aarẹ titi to fi di ẹni to n ṣoju ijọba Naijiria niwaju awọn aṣoju ijọba ilẹ okere mii.

Ijọba yoo tun ṣewadii bo ṣe n gba fisa lorukọ rẹ, bo ṣe ṣi oniruru apo iṣuna lawọn ile ifowopamọ atawọn nnkan mii.

Onanuga tun tẹsiwaju pe Aarẹ fẹ mọ ohun to fun afurasi naa ni igboya atawọn nnkan mii to rọ mọ bo ṣe ri iwe igbanisiṣẹ ijọba apapọ gba lorukọ ijọba.

Atẹjade naa sọ pe "Iwadii naa yoo tu aṣiri bo ṣe ri ati bo ṣe n lo ayederu iwe lati ṣoju ijọba; bo ṣe ṣi awọn apo iṣuna ni oniruru ile ifowopamọ, bi owo ṣe n wọ inu awọn apọ iṣuna naa ati ibi ti owo ọhun ti wa, awọn banki to n lo atawọn to jẹ ki iṣẹ rẹ ṣeeṣe."

Aarẹ tun paṣẹ ki ICPC ṣewadii awọn kudiẹ-kudiẹ to wa nileeṣe ijọba ti afurasi naa gba wọle ati ọna ti yoo fi di awọn kudiẹ-kudiẹ naa ki irufẹ iṣẹlẹ bẹe ma baa waye mọ lọjọ iwaju.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Aarẹ paṣẹ fun gbogbo ileeṣẹ ijọba ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ICPC ninu iwadii naa ki wọn si fun ajọ naa ni ohun to ba bere fun iwadii rẹ.

Ileeṣẹ Aarẹ ni ọrọ naa jẹ eyii to buru jai to si lagbara lati dojuti Aarẹ ati ijọba Naijiria lagbaye.

Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe Onanuga sọ fun akọroyin oun pe iwadii ti wọn ṣe ti fi han pe ayederu ni ibuwọlu olori oṣiṣẹ Aarẹ, Femi Gbajabiamila to wa lori iwe igbnisiṣẹ afurasi to n tukọ ayederu ileeṣẹ ọhun.