'A gba ìjọba arawa, a fi ń nira wa lára' - Àwọn aráàlú sọ èrò wọn lórí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ìṣèjọba àwaarawa
Oni lo pe ọdun mẹtadinlọgbọn ti orilẹ ede Naijiria ti bọ saye ijọba awaarawa eyi ti a tun mọ si ijọba alagbada.
Lati ọdun 1960, ti ilẹ Naijiria ti gba ominira, ilana iṣejọba alagbada ko fi bẹẹ pẹ to bi awọn ologun ti dari ko to di ọdun 1999 ti wọn gbe ijọba le alagbada lọwọ.
Amọ nitori bi ilu ṣe ri, paapaa ipenija aabo ati ọwọngogo to n ba Naijiria, awọn eeyan paapaa awọn ọdọ lo maa n pe fun ki awọn Ologun gba ijọba boya nnkan yoo rọrun ju bayii lọ.
Fun awọn mii ẹwẹ paapaa awọn ti wọn ti logba lasiko iṣejọba mejeeji yii, ẹni ti Sango to ju rẹ ja kii bawọn bu ọba Koso ni ọrọ naa ri lọdọ ti wọn.
Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si awọn araalu lati gbọ ti ẹnu wọn ni bi a ṣe n ṣe ayajọ ominira mii lonii.

Iṣejọba alagbada maa n fun ni ni anfaani lati sọrọ, lati le ṣe nnkan to wu wa, lati le fi ẹhonu han ṣugbọn ti a ba n sọrọ nipa ijọba Ologun, ijọba apaṣẹ wa a niyẹn, nnkan ti won ba ti sọ ni abẹ ge
Fun Dokita Akinojo Atayese, ẹni to fi ilu Ado Ekiti, olu ipinlẹ Ekiti ṣe ibujokoo, to si ti tọ iṣejọba mejeeji wo sọ pe bi o tilẹ jẹ pe inu oun dun pe iṣejoba mejeeji ṣoju oun, o ni ijọba to lagbara ni ti Ologun.
O woye pe eeyan kii le sọ ohun to ba fẹ tabi huwa to ba wu u lasiko Ologun nitori ijọba bo o ba o pa, bo o ba ko bu u lẹsẹ ni ijọba Ologun, ti wọn kii gbọ sai.
Ero rẹ yii naa jẹ ohun ti Ademola Aderanti gbe lẹyin bi o ṣe ni ijọba awaarawa lo da julọ nitori ijọba Ologun jẹ apaṣẹ wa a to jẹ pe gbogbo ohun ti wọn ba ti sọ ni abẹ ge yala o tẹ araalu lọrun tabi bẹẹ kọ.
Aderanti ni ijọba awaarawa maa n fun araalu ni anfaani lati le sọrọ, paapaa ti awọn igbesẹ ijọba ko ba tẹ araalu lọrun.
"O maa n fun ni ni anfaani lati sọrọ, lati le ṣe nnkan to wu wa, lati le fi ẹhonu han.
Ṣugbọn ti a ba n sọrọ nipa ijọba Ologun, ijọba apaṣẹ wa a niyẹn, nnkan ti wọn ba ti sọ ni abẹ ge."
Ni igba ijọba Ologun, gbogbo nnkan ko le koko bayii, elo la n ra epo nigba yẹn, elo la n repo bayii.
Amọ fun Joshua Akinrinmade ati Ololade Adeyinka, ko fẹ ẹ si iyatọ kankan laarin ijọba mejeeji nitori wọn gbagbọ pe nnkan ko le to bo ṣe wa lasiko yii lasiko ijọba Ologun.
Awọn mejeeji ka ọwọngogo ati ipenija aabo, eyi ti wọn ni ko wọpọ bẹẹ lasiko Ologun bi idi ti wọn fi faramọ iṣejọba Ologun.
"Ijọba Ologun pẹlu imọ temi o fẹẹ dara ju ijọba arawa ta way ii lọ.
"Ni igba ijọba Ologun, gbogbo nnkan ko le koko bayii, elo la n ra epo nigba yẹn, elo la n repo bayii.
"Ẹ jẹ ka wo irẹsi, ọpọlọpọ mẹkunnu ni ko fẹ ẹ ri ounjẹ jẹ mọ, nitori pe a gba ijọba arawa, a tun wa fi n ni ara wa lara."






