Olùkọ́ ìmọ̀ ‘History’ ni yóò di Ààrẹ Uruguay tuntun

 Yamandu Orsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olukọ imọ itan tẹlẹ lorilẹede Uruguay, Yamandú Orsi, ti jawe olubori niu eto idibo Aarẹ orillẹede naa.

Orsi na Álvaro Delgado to jẹ ọmọ ẹgbẹ osẹlu to wa lori oye pẹlu nnka bii ida mẹta pere.

Delgado ti kede pe oun ti juwọ silẹ fun Orsi, o si ti kii ku oriire fun aṣeyọri rẹ ninu eto idibo naa.

Ẹgbẹ Broad Front lo tukọ orilẹede naa bọ fun ọdun marundinlogun lati ọdun 2005 si ọdun 2020, ki Aarẹ ti yoo gbe agbara silẹ, Luis Lacalle Pou to fidi Aarẹ to wa nipo janlẹ.

Ọpọ eeyan lo ri Orsi gẹgẹg bii ọmọlẹyin Aarẹ ilẹ naa nigba kan ri, José Mujica.

José Mujica ṣe daadaa nigba saa rẹ, o si mu inu ilu dun to bẹẹ ti awọn eeyan kan fi n juwe rẹ bii Aarẹ to toṣi julọ lagbaye.

Ọmọ atapata dide ni Orsi ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, koda ko si ina ijọba ni abule to ti wa.

Asiko to n ṣiṣẹ olukọ lo darapọ mọ oṣelu titi to fi di adari ẹka ileeṣẹ ijọba, Canelones.

Oun naa ṣe daadaa lasiko rẹ gẹgẹ bii olori Canelones to bẹẹ ti ileeṣẹ Google fi ni oun yoo kọ gbọgan nla kan sibẹ.

Nigba to n ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ, o ni oun yoo jẹ Aarẹ fun gbogbo araalu, oun yoo si ṣe ojusẹ oun lai ṣe ojuṣaaju.

Aarẹ to n fi ipo silẹ, Luis Lacalle Pou ti sọ pe oun yoo gbe agbara silẹ fun Orsi, oun yoo si ṣatilẹyin fun ijọba rẹ.

3.4 miliọnu eeyan lo n gbe ni Uruguay.