Wo àwọn agbábọ́ọ̀lù tó gba àmì ẹ̀yẹ tó tayọ níbi ife ẹ̀yẹ àgbáyé àti ẹ̀kọ́ méje tó wà nínú ìdíje náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Spain ti gba ife ẹyẹ agbaye 2026 FIFA World Cup lẹyin to gbo ewuro sẹnu orilẹede Argentina pẹlu ami ayo kan si odo.
Aṣeyọri yii ni igba keji ti Spain yoo gba ife ẹyẹ naa ninu itan.
Ikọ Lionel Messi lati Argentina lo gbe ipo keji ninu idije naa lẹyin ti wọn pade Spain ninu aṣekagba to waye ni papa iṣere New Jersy.
Orilẹede England lo ṣe ipo kẹta ninu idije ọhun lẹyin ti wọn na France ni ami ayo 6-4, oniruru ami ẹyẹ ni wọn si gbe fun awọn agbabọọlu to lamilaaka ninu idije naa.
Iwọnyi ni awọn agbagbọọlu to gba oniruru ami ẹyẹ ninu idije naa
Ọmọ orilẹede Spain, Rodrigo Hernández Cascante ti ọpọ mọ si Rodri lo gba ami ẹyẹ 'Golden Ball' gẹgẹ bii agbabọọlu to ta lẹnu julọ.
Kylian Mbappé lati France lo gba ami ẹyẹ 'Golden Boot' lẹyin to jẹ goolu mẹwaa nini ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to ti kopa. Oun tun ni ọkunrin to sọ goolu sinu awọn julọ ninu itan ife ẹyẹ agbaye ọhun.
Aṣọle ikọ Spain, Unai Simón, gba ami ẹyẹ 'Gloden Glove' latari pe ko jẹ ju goolu kan ṣosọ lọ ninu idije naa lati ibẹrẹ titi de ipari.
Pau Cubarsí lati Spain naa tun gbami ẹyẹ agbabọọlu ti ọjọ ori rẹ kere julọ to tun ṣe daadaa ninu idije ọhun.
Orilẹede Netherlands lo gba ami ẹyẹ orilẹede to ṣe ọmọluabi julọ lori papa lasiko idije naa.
Awọn ẹkọ meje to ṣe pataki lati kọ ninu idije 2026 FIFA World Cup
- Awọn alagbara le ṣubu: Ọpọ lo gbagbọ pe Lionel Messi yoo fakọyọ ninu aṣekagba idije naa amọ niṣe lo lulẹ niwaju Spain
- Imọ ẹrọ AI ninu ere bọọlu – Yatọ si ẹtọ VAR, bọọlu ti wọn lo lọdun yii ni wọn ṣe pẹlu imọ ẹrọ AI to wa ninu bọọlu naa funra rẹ to si wulo ife ẹyẹ naa, irufẹ eyii ti ko ṣẹlẹ ri ninu itan
- O ṣeeṣe ki ọpọ orilẹede gbalejo idije ifẹ ẹyẹ agbaye naa gẹgẹ bo ṣe waye lọdun yii ni Amẹrika, Mexico ati Canada lẹẹkan ṣoṣo. Kọ rọrun amọ o ṣeeṣe
- Ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn ba fọwọsọwpọ le ṣaṣeyọri ju eyii to lagbara lọ
- O ṣeeṣe ki orilẹede mejidinlaadọta kopa ninu idije naa lai si wahala kankan. Lọdun yii ni iye awọn to n kopa tẹlẹ pọ si; dibo orilẹede mejilelọgbọn to n kopa ninu rẹ rẹlẹ orilẹede mejidinlaadọta lo kopa ninu rẹ lọdun 2026
- Awọn orilẹede kekeke naa le ta putu ninu bọọlu agbaye, lara wọn ni Cape Verde ti wọn ṣe daadaa bo tilẹ jẹ pe igba akọkọ wọn ninu idije naa ree
- Gbogbo igba lawọn ololufẹ bọọlu n pọ si: Ọpọ eeyan, paapaa lawọn orilẹede bii Amẹrika ti wọn ti kudun bọọlu alapẹrẹ lo ṣẹṣẹ mọ iyi bọọlu afẹsẹgba. Bi papa iṣere ṣe kun fọfọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye naa lo ya ọpọ awọn ọmọ orilẹede naa lẹnu




























