"Bàbá mi ti fẹ́ mú ọjọ́ ìgbeyàwó mi, kí wọn tó dú u lọ́rùn sínú oko, à ṣe ẹni ẹlẹ́ni ní yóò gba ìṣe rẹ̀ ṣe"

Àkọlé fídíò, Bàbá mi ti fẹ́ mú ọjọ́ ìgbeyàwó mi, kí wọn tó dú u lọ́rùn sínú oko, à ṣe ẹni ẹlẹ́ni ní yóò gba ìṣe rẹ̀ ṣe"
"Bàbá mi ti fẹ́ mú ọjọ́ ìgbeyàwó mi, kí wọn tó dú u lọ́rùn sínú oko, à ṣe ẹni ẹlẹ́ni ní yóò gba ìṣe rẹ̀ ṣe"
Published

Ọpọ ẹda lo maa n gbadura pe ka ma tẹni ti ika, ohun ti a jẹ la n wa, ka ma pade ohun ti yoo jẹ wa.

Amọ eyi ko ri bẹẹ fun ọkunrin agbẹ kan, Garba Azeez, ti ọpọ eeyan tun mọ si Kebe, ẹni ti awọn agbebọn kan pa sinu oko rẹ, tawọn ẹbi rẹ si ba oku naa sinu oko ọhun.

Ọjọ kọkanla osu Kẹfa ọdun 2026 ni isẹlẹ naa waye nilu Ilorin ni ipinlẹ Kwara.

Isẹlẹ naa si lo ta ikọ iroyin BBC News Yoruba nidi kan, lati lọ ba ẹbi oloogbe naa sọrọ lati mọ iru ẹni to jẹ ati bi isẹlẹ naa se waye.

Garba Azeez wọagbada toke tilẹ alawọ ofeefe, o de fila asọ oke Sanyan

Ọkọ mi ko eso koko lọ si oko fun gbingbin, mo reti wọn titi di aago meji, aburo wọn lọ wo wọn ninu oko, o ri ọkada wọn ati apoti koko nikan - Aya Oloogbe

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, aya oloogbe, Fatima Abdulazeez salaye pe lọjọ ti isẹlẹ naa waye, ọkọ oun kọkọ jade nile lọ si Mọsalasi lati kirun.

"Lẹyin ti wọn ti Mọsalasi de, ọkọ mi ni oun fẹ lọ da ẹkọ mu, o si mu diẹ lara ẹkọ naa, pe oun yoo mu iyoku ti oun ba da.

Wọn ni awọn n jade lọ lati ko eso koko lọ si oko fun gbingbin, ti oun yoo si tun ya ki ẹnikan ni Oke Onigbin.

Wọn ni awọn yoo si tete pada tori awọn da aago meji fun ipade pẹlu awọn janmọ.

Mo reti wọn titi di aago mejila, mo n wo pe wọn kii pẹ to bẹyẹn ninu oko, nigba to di aago meji, mo sọ fun aburo wọn kan pe daddy ko ma tii de.

Eyi lo mu ki aburo wọn naa gbe ọkada lọ wo wọn ninu oko, o si ri ọkada wọn ati apoti ti wọn fi ko koko lọ sinu oko ati koko, wọn ko tii sisẹ rara."

Aya oloogbe, Fatima Abdulazeez da hijab alawọ buluu bori

"Awọn ọlọdẹ ri i, ti wọn ju oku ọkọ mi si, ti wọn si so ọwọ wọn mejeeji sẹyin"

Aya oloogbe, Fatima tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba pe awọn pe awọn ọlọdẹ adugbo, ti wọn si lọ sin oko lati wa ọkọ oun.

"Amọ igba tawọn ọlọdẹ naa de inu oko, wọn ba wọn nibi ti wọn ju oku wọn si, ti wọn si so ọwọ wọn mejeeji sẹyin.

Koko ti mo ni wọn fẹ lọ lọ sinu oko wọn, ni wọn gbe si ẹgbẹ ọkada wọn, eyi si fihan pe bi wọn se de inu oko, ni isẹlẹ naa waye.

Ọmọ oloogbe, Rofiat Abdulazeez da hijab alawọ dudu bori

A se baba mi ko ni duro se baba fun mi lọjọ igbeyawo mi, ẹni ẹlẹni ni yoo gba ise wọn se lọjọ ẹyẹ mi - Ọmọ Oloogbe

Ninu ọrọ tiẹ, ọmọ oloogbe, Rofiat Abdulazeez ni gbogbo ero awọn ni pe awọn ajinigbe ti gbe baba oun ni.

O ni iyawo oloogbe naa sọ fun awọn pe wọn ti ri ọkada baba oun ninu oko, ti wọn ko si ri baba oun gangan.

"Ni kete la pe Aafa lati ba wa joko se adura, pe awọn ajinigbe ti gbe baba mi tori wọn ko ri wọn ninu oko, ọkada wọn nikan ni wọ̀n ba nibẹ.

Mo pe iya mi, o ni oun sẹsẹ de ilu Isanlu Isin ni, ti oun ko si ri baba mi pe."

Rofiat, ọmọ ologbe wa bu sẹkun pe awọn apaayan naa du baba oun lọrun ni, ti wọn si pa silẹ.

"Emi ati baba mi ti ni ajọsọ pe ti wọn ba ti fun mi ni ọjọ igbeyawo Nikah mi, ta ba ti mu ọjọ, a maa se inawo naa, oun lo wa di ẹni ti n ko ri mọ bayii.

A se baba mi ko ni duro se baba fun mi lọjọ igbeyawo mi, ẹni ẹlẹni ni yoo gba ise wọn se lọjọ ẹyẹ mi.

Gbogbo isẹ ti baba mi se, wọn ko jẹ ko duro jẹ ki wọn to pa a, ko si ẹni ti yoo se bii baba fun mi."

Tawakalitu Abdulazeez tii se opo oloogbe keji da hijab alawọ eeru bori

Ọkọ mi naa lo n saanu wa, awọn lo n gbe jijẹ mimu lori wa, mo fẹ ki ijọba wadi otitọ ọrọ to wa nidi iku rẹ - Aya oloogbe

Mama Rofiat, tii se Tawakalitu Abdulazeez naa ba BBC News Yoruba sọ̀rọ, to si rọ ijọba lati ba wọn da si isẹlẹ han.

"Mo fẹ ki ijọba fi oju asebi han, mo fẹ ki ijọba saanu mi, ki wọn mase jẹ ki iku ọkọ mi lọ lasan, ki wọn ba mi tu asiri asebi.

Mo fẹ ki wọn wadi idi ti isẹlẹ naa se waye tori ẹru eeyan meji ti di ti ẹnikan bayii, ko si oluranlọwọ kankan.

Ọkọ mi naa lo n saanu wa, awọn lo n gbe jijẹ mimu lori wa, mo fẹ ki ijọba wadi otitọ ọrọ to wa nidi iku rẹ."

Obinrin opo kan to tun jẹ aburo oloogbe da hijab alawọ dudu bori

"Opo ni mi pẹlu ọmọ mẹfa, ẹgbọn mi ti wọn pa yii lo n gbọ bukata lori wa"

Obinrin opo kan to tun jẹ aburo oloogbe yii, naa ba BBC News Yoruba sọrọ nipa isẹlẹ yii.

O ni ọmọ mẹfa ni oun bi fun ọkọ oun ko to ku amọ Azeez Garba ti wọn pa yii lo da awọn ọmọ naa pọ mọ awọn ọmọ rẹ, lati maa tọju wọn.

" Mo fẹ ki ijọba ran wa lọwọ lati se awari iku to pa oloogbe naa tori wọn ko sẹsẹ maa lọ sinu oko yii, ibẹ naa ni wọn ti n wa jijẹ, mimu fun wa.

Ibẹ naa ni wọn ti n sanwo ile iwe awọn ọmọ temi ti mo jẹ aburo lẹyin wọn ati awọn ọmọ tiwọn ti wọn bi, to fi mọ orisirisi nnkan ti wọn n se ninu ẹbi.

Mo fẹ ki ijọba ran wa lọwọ lati se idajọ ododo lori iku to pa ẹgbọn mi."

Iwadii n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa - Ọlọpaa Kwara

BBC News Yoruba kan si ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lati mọ ibi ti iwadi de duro nipa isẹlẹ yii.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ni iwadi ti n lọ lori isẹlẹ naa, ti wọn si setan lati fi imu awọn eeyan ti aje iwa ipaniyan naa ba si mọ lori, ko ata ofin.