Ohun tí a mọ̀ nípa bí Boko Haram àti ISWAP ṣe ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ AI fún ìgbésùnmọ̀mí

Ikọ Boko Haram ninu aginju. Wọn bo oju, gbe ibọn dani, kọyin si mọto wọn, bẹẹ ni wọn gbe asia kan ti wọn kọ keu si lara dani

Oríṣun àwòrán, AFP

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Abọ iwadii tuntun ti fi han pe ikọ apaniyan meji lorilẹede Naijiria, eyi ti i ṣe Boko Haram ati ISWAP, ti n lo imọ ẹrọ atọwọda ti a mọ si Artificial Intelligence (AI) lati fi ṣiṣẹ laabi ti wọn gbe dani.

To ba jẹ bawọn ikọ onikọlu yii ṣe lodi si iwe kika ati imọ ẹrọ gbogbo ni eeyan fẹ wo, eeyan yoo sọ pe ko yẹ ki wọn tiẹ fọwọ kan ohunkohun ti a fi ọgbọn iwe tabi imọ ẹrọ gbe kalẹ rara.

Amọ lọwọ yii, iwadii ti fi han pe awọn Boko Haram ati ISWAP ti n lo AI, imọ ẹrọ to fẹrẹ ma si ohun ti ko le ṣe bi eeyan ba bẹ ẹ lọwẹ.

Ki ni wọn n lo imọ ẹrọ naa fun?

Abọ iwadii naa sọ pe awọn arijagba yii n lo imọ ẹrọ lati koju ọgbọn ti alatako ba fẹ lo, lati fi wadii aṣiṣe wọn ninu ikọlu lẹyin to ba ṣẹlẹ tan, ki wọn si tun fi ni anikun imọ nipa fifi ẹrọ igbalode ṣe ikọlu si i.

Iṣẹ iwadii naa ti Antonia Juelich, onimọ nipa AI ṣe pẹlu University of Cambridge, ni UK, da lori awọn ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ ISWAP ati Boko Haram tẹlẹ.

Ẹka iroyin AFP royin pe iwadii naa fi han pe awọn ẹgbẹ agbesunmọmi yii n tẹsiwaju ninu lilo imọ ẹrọ yii lati ro iṣẹ wọn lagbara.

Ki ni itumọ eyi?

Onimọ nipa imọ ẹrọ kan, Umar Saleh Gwani, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe AI kọ ni yoo ba wọn pinnu ibi ti wọn fẹ kọlu, sibẹ o maa n ran wọn lọwọ pẹlu awọn ohun to yẹ ki wọn mọ nipa ibi ti wọn fẹ kọlu, o si maa n fun wọn lawọn òye naa kiakia ni.

"Lara awọn ilana ti wọn n lo lọwọ ni ṣiṣe eto bi wọn yoo ṣe kọlu awọn ologun, ati bi wọn yoo ṣe pin awon ikọ agbesunmọmi naa si awọn aaye ọtọọtọ ti wọn yoo kọlu.

"AI kọ lo n pinnu fun wọn bẹẹ yẹn, amọ o n ran wọn lọwọ pẹlu imọran to ya kankan"

Gwani lo ṣalaye bẹẹ.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, awọn kamẹra ti wọn ti so pọ mọ imọ ẹrọ AI naa wa lara ohun ti wọn n lo lati wo ohun to ṣẹlẹ lẹyin ikọlu.

Eyi maa n jẹ ki wọn mọ ibi ti wọn ti ṣe aṣiṣe, yoo si kọ wọn lati ma ṣe iru aṣiṣe bẹẹ mọ ninu ikọlu ti yoo ba tun waye.

"AI le ṣalaye ohun to ṣẹlẹ finni-finni ninu fidio lẹyin ikọlu, o le tọka aṣiṣe, ti yoo si tun fun wọn ni awọn ọna ti wọn le gba fi dangajia ninu iṣẹ wọn."

Bẹẹ ni Umar Saleh Gwani ṣalaye.

Ifura loogun agba

Bi abọ iwadii yii ṣe fidi awọn nnkan wọnyi mulẹ to, awọn akọṣẹmọṣẹ onimọ ẹrọ kan ko fi gbogbo ara gba a gbọ.

Wọn lo yẹ ki eeyan ṣọra lati gba pe awọn ẹgbẹ naa n lo AI, bi eeyan ko ba ti i ṣewadii tiẹ daadaa.

Amofin kan to tun jẹ Ọmọwe, Audu Bulama Bukarti, onimọ nipa ọrọ aaboo nilẹ Adulawọ, sọ pe ọna ti wọn fi gbe iwadii naa kalẹ ko kun to.

"Ọpọlọpọ ọrọ lo nilo ki wọn fi otitọ rẹ mulẹ nipa abọ iwadii yii. Ko rọrun lati wadii abọ naa, nitori ọrọ ẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ tẹlẹ ninu Boko Haram ati ISWAP ni."

Ọmọwe Bukarti lo ṣalaye bẹẹ.

O ni amọ o ṣee ṣe ki awọn iroyin kan to ti jade tẹlẹ, pe awọn ikọ naa ti n lo AI tipẹ jẹ ootọ.

Ọmọwe Bukarti sọ pe awọn iwadii kan fi han pe awọn ISIS lati Libya, France atawọn apa kan ilẹ Arab ti gbe imọ AI de agbegbe Lake Chad.

Gẹgẹ bo ṣe wi, iwadii abẹnu fi han pe lati 2023 ni awọn ẹka ISWAP ati Boko Haram kan ti gbe awọn ẹka kan kalẹ to n ri si bi wọn ṣe n lo AI fun ikọlu wọn.

Ewu wo lo wa ninu eyi?

Alaye Bukarti ni pe awọn agbesunmọmi yii le gba agbara ọtun pẹlu imọ ẹrọ AI.

O tun le jẹ ki ibaraẹnisọrọ wọn ya kankan bo ṣe wi, ti wọn yoo ri olobo ti wọn fẹ kia, ti wọn yoo si ṣeto ọna ikọlu ti wọn yoo gba kia.

Bi awọn alaṣẹ ko ba tete koju ọgbọn igbalode yii fawọn agbesunmọmi, Ọmọwe Bukarti kilọ pe o le mu nnkan le si I lawọn agbegbe to n koju ikọlu agbebọn.

"Ipa pataki kan wa ti AI le ko lati ran awọn agbesunmọmi lọwọ, nitori ẹ lo ṣe ṣe pataki pe kawọn alaṣẹ ijọba tete gbe igbesẹ to yẹ lati ma jẹ ki wọn lo imọ ẹrọ yii fi huwa ọdaran. "

Bo tilẹ jẹ pe o si nilo iṣẹ iwadii si I lati fidi ẹ mulẹ pe awọn agbesunmọmi n lo AI, onimọ nipa aabo yii sọ pe ọkan lara awọn iṣoro ti ijọba yoo koju lọjọ iwaju ni.

Bẹẹ ni bi gbogbo aye ṣe n jẹ anfaani Ai lẹka ilera, ẹkọ, ọrọ aje atawọn yoku, awọn abọ iwadii n fi han pe awọn ẹlẹgiri naa paapaa n wa ọna ti wọn yoo fi maa lo imọ ẹrọ yii fun ikọlu wọn.