Agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nínú ọgbà fásitì, èèyàn mẹ́ta jáde láyé

UNLV shooting

Oríṣun àwòrán, getty images

Published

Eeyan mẹta ti jade lẹyin ti ọkunrin kan dede ṣina bolẹ ninu ọgba ile ẹkọ University if Nevada, nilẹ Amẹrika.

Ọkunrin agbebọn naa, to ti fi akoko igba kan jẹ olukọ fasiti ri ti jade laye lẹyin ti oun atawọn ọlọpaa doju ibọn kọ ara wọn.

Ọlọpaa ni ẹnikan to farapa nibi iṣẹlẹ naa ti wa nile iwosan bayii, nibi to ti n gba itọju.

Ọlọpaa ni awọn yoo gbe ọgba ile ẹkọ naa tipa, eyii to jẹ nnkan bii maili meji si Las Vegas Strip ti ọpọ araalu ti n gbafẹ.

O ti le ni igba 630 ti araalu ti ṣina ibọn bọle nilẹ Amẹrika lọdun yii nikan ṣoṣo.

Ilu Las Vegas yii ni irufẹ iṣẹlẹ bayii to buru julọ ti waye ninu itan ilẹ Amẹrika, nibi ti agbebọn ti ṣekupa aadọta eeyan lọdun 2017.

Awọn agbofinbro ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin CBS pe agbebọn ọhun ti ṣiṣẹ olukọ ni Georgia ati North Carolina ri ṣaaju ikọlu ọhun.

Ileeṣẹ iroyin Associated Press jabọ pe afurasi naa ti kọwe ẹbẹ iṣe sile ẹkọ ọhun ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Ọlọpaa ni awọn ko ni kede orukọ afurasi lai kọkọ sọ fun awọn mọlẹbi rẹ nipa ohun to ṣẹlẹ ati ipo to wa bayii.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, ọga ọlọpaa agbegbe Las Vegas, Kevin McMahill sọ pe awọn ko tii le sọ eredi to fi ṣe ohun to ṣe.

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI ati ATF ti n ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati ṣewadii iṣẹlẹ naa.