Ìbọn 'Amotekun' pa akẹ́kọ̀ọ́ FUTA níbi ìgbeyàwó, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fárígá l'Akure

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ Naijiria NANS ni ipinilẹ Ondo kan lu igboro Akurẹ tii ṣe olu ipinlẹ Ondo lọjọ Aiku lati ṣe iwọde tako iku akẹkọọ kan ti wọn ni oṣiṣẹ ikọ agbofinro Amọtẹkun kan ni ipinlẹ naa yinbọn pa lọjọ Satide.
Awọn akẹkọọ naa di awọn opopona kan nilu Akurẹ, paapaa orita to so opopona Ọda, Igbatoro ati ọfisi gomina ipinlẹ naa pọ pa lasiko ifẹhonuhan ọhun.
‘Ibi ayẹyẹ igbeyawo ni Tọpẹ lọ ti ibọn ẹṣọ Amọtẹkun fi ba a’

Alaga ẹgbẹ akẹkọọ Naijiria, NANS ẹka ti ipinlẹ Ondo, Akinọla Elijah Temitọpẹ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe Tọpẹ Elijah ni orukọ akẹkọọ ti iṣẹlẹ laabi naa ṣẹ si, ipele aṣekagba ẹkọ imọ nipa ọrọ aje (Economics) lo si wa ni ile ẹkọ fasiti imọẹrọ FUTA nilu Akurẹ ki ibọn awọn oṣiṣẹ amọtẹkun naa to ba a.
Akinọla ṣalaye siwaju sii pe ibi ayẹyẹ igbeyawo kan ni akẹkọọ to di oloogbe naa lọ lọjọ Satide nibẹ si ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun kan ti n yinbọn soke lati ṣe ajọyọ ọkọ iyawo tuntun naa ti wọn ni o jẹ ọkan lara wọn.
Ibọn ti wọn n yin soke yii, gẹgẹbi alaga ẹgbẹ akẹkọọ Naijiria, NANS ẹka ti ipinlẹ Ondo naa ṣe sọ, lo ṣeeṣi ba Tope nikun to si ran-an lọ si ọrun.
“Kete ti wọn ri pe ibọn ba akẹkọọ naa ni gbogbo wọn fi ẹsẹ fẹ. Awọn ọlọpaa to wa nibẹ lo ran awọn eniyan lọwọ lati gbe oloogbe naa lọ si ile iwosan.
“Ohun ti a n beere fun ni ki wọn fi oju ẹṣọ to yin ibọn naa han, ki wọn si faa le awọn ọlọpaa lọwọ fun ijiya ti o tọ.”

Akinola fi kun un pe wakati mejididinlaadọta lawọn n fun awọn alaṣẹ ajọ ikọ alaabo Amọtẹkun ni ipinlẹ naa lati fi ṣe eyi, bi bẹẹkọ awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ iwọde to le da omi alaafia ipinlẹ naa ru
A n rawọ ẹbẹ si ijọba ki wọn ba wa gbe igbesẹ to tọ lori ọrọ yii - ẹbi akẹkọọ to di oloogbe

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, aburo oloogbe naa, Adeola Alabi rawọ ẹbẹ si ijọba lati gbe igbesẹ to tọ lori ẹni to ṣekupa ẹgbọn ohun.
Adeola ni eyi ni yoo dun mọ mọlẹbi awọn ninu ti ijiya to nipọn ba le jẹ ọdaran naa.
Ki ni Amọtẹkun sọ?

Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati gbọ latẹnu ajọ amọtẹkun nipinlẹ Ondo lo ja si pabo.
Abẹwo aṣojukọroyin BBC Yoruba si ileeṣẹ ajọ naa ko so eso bẹẹni ọga ajọ naa ko gbe gbogbo ipe ti a pe lori ago rẹ, ko si fesi si atẹjiṣẹ ti a fi ranṣẹ si i pẹlu.
























