PenCom kéde bo ṣé lè mú nínú owó ìfẹ̀hìntì rẹ̀ fí sàn owó láti fí rà ilé

Published

Ajọ to n risi ọrọ owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ ni Naijiria (PENCOM) kede laipẹ yi pe awọn ti gbe eto kalẹ ti oṣiṣẹ le fi mu ninu owo ifẹhinti rẹ fi san owo asansilẹ ile to ba fẹ ra.

Gẹgẹ baa ṣe gbọ, ifayegba yii wa ni ibamu pẹlu ofin to de atunto ilana owo ifẹhinti labẹ ofin to de eto owo ifẹyinti Naijiria(Section 89 (2) of the Pension Reform Act 2014

Iroyin yii jẹ ohun idunnu fun awọn oṣiṣẹ yala lẹka ijọba tabi aladani to n fi owo ifẹhinti pamọ to si tun n gbero lati da ile ara tiẹ ni.

Amọ ṣa PenCom gbe awọn ilana kan kalẹ ti eeyan gbọdọ tẹle ko to le jẹ anfaani yii.

Atupalẹ awọn ilana yii ati ohun ti oṣiṣẹ to n ko owo ifẹhinti pamọ sọdọ PenCom le ṣe ni akori apilẹkọ yii.

Awọn nkan to gbọdọ ṣe lati fi jẹ anfaani yii

Pataki julọ, ẹni to ba fẹ jẹ anfaani yi nikan lo le kọwe beere fun anfaani yi.

Wọn ko le ba oṣiṣẹ to n da owo ifẹhinti ṣe eto yii lorukọ rẹ.

Irufẹ ẹni to ba tẹle eto yi yoo kan si ileeṣẹ to n ṣeto owo ifẹhinti rẹ fun alaye ẹkunrẹrẹ.

Ileeṣẹ to n gba owo ifẹhinti rẹ taa n pe ni PFA yii yoo tẹ akọsilẹ dede iye owo to wa ni akoto ikowo ifẹhinti rẹ pamọ si.

Too ba ti gba eleyi tan, ri pe o pada si ọdọ ileeṣẹ to n ṣeto ẹyawokọle,gba lẹta ti wọn fifẹ ta ile naa fun ẹ,ri pe o ṣe ayẹwo daada lati faaye gba wọn lati mọ pe ida 25% nikan ni o le yọ ninu owo ifẹhinti lati fikun owo ile.

Ida 75% to ku , ibomiran lo ti ma wa iyẹn.

Too ba ti ri iwe ti ileeṣẹ to fẹ ta ile buwọlu, eleyi ni o ma mu lọ si ileeṣẹ to n ko owo ifẹhinti rẹ pamọ ti o si le tẹsiwaju lati gba ida 25% to nilo.

Ida 25% nikan lo le gba, ko lee ju bẹẹ lọ

Ninu alaye ti PenCom ṣe, owo to pọju ti eeyan le gba to ba fẹ ya owo fi kun owo ti yoo fi ra ile ko le ju ida marundinlọgbọn yii lọ.

Owo ko baa pọgaan ninu akoto rẹ, ko le gba ju iye yi lọ ati pe ti owo naa ko ba to lati le fun ẹni yi lanfaani lati san ida 25% ninu owo apapọ to ba fẹ fi ra ile yi,

ileeṣẹ RSA le wo ọna mii lati fi ri owo yi ti eleyi ba wa si ni.

O le gba owo ida 25% yi ju ẹẹkan lọ ṣugbọn...

Alaye to wa lori eleyi yii ni pe ti eeyan ba ti kọkọ gba ida mẹẹdọgbọn kan lasiko ti iṣẹ bọ lọwọ rẹ, o tun le pada wa gba ida mẹẹdọgbọn mii ninu iye owo to n fi si akoto ifowo ifẹhinti rẹ si.

Ki o to le gba owo yi, o gbọdọ buwọlu iwe nibi ti yoo ti ṣalaye pe oun ti kọkọ gba ida mẹẹdọgbọn kan ṣaaju ṣugbọn bayi ti oun ti ri iṣẹ pada, oun fẹ gba iye owo yii lẹẹkan si lati le fi ra ile.

Yoo jẹ ajọmọ laarin ẹni to n da owo ati RSA rẹ pe owo ti wọn ba fun yii yoo kuro ninu gbogbo owo ti yoo gba ti o ba pada fẹhinti lẹnu iṣẹ.

Ti iye owo rẹ ko ba ka 25% ti wọn ni ko san lowo ile nkọ?

Owo to ba wa ninu akoto ẹni to fẹ jẹ anfaani yi ko ṣe dandan ko to dede iye owo ti awọn to fẹ ta ile n beere.

Fun apẹrẹ, ti o ba fẹ ra ile ti wọn si pe iye rẹ ni miliọnu mẹwaa Naira.

Ti o ba san ida 25% owo yi yoo maa ku si N2.5m.

To ba wa ṣe wi pe iye to wa ninu akoto owo rẹ ko ju N1.5 miliọnu lọ, o lanfaani lati wa miliọnu kan to ku nibo miran ko wa paapọ pẹlu eleyi ti o wa ninu akoto rẹ lati fi jẹ ko to N2.5m to nilo.

Ko si anfaani lati gba owo yii ti o ba ku ọdun diẹ ti wa fi fẹhinti lẹnu iṣẹ

Tọkọtaya le jijọ pa owo to ba wa ninu akoto ifowo ifẹhinti wọn pamọ lati le jẹ anfaani yi ti wọn ba fẹ ra ile.

Amọ bi o ba ku nkan bi ọdun mẹta tabi meji ti eeyan yoo fi fẹhinti lẹnu iṣẹ, ko ni lanfaanilati gba owo ida 25% taa n wi yii.

Lakotan, ẹni to ba fẹ jẹ anfaani yii nilati ṣe ayẹwo iroyin rẹ to kọ sọdọ RSA rẹ ki gbogbo nkan baa le lọ letoleto.