You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ síi nípa Olaolu Martins ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ ilé oúnjẹ Bukka Hut tó ṣáláìsí
Ile ounjẹ igbalode to gbale gba oko ni ipinlẹ Eko Bukka Hut ti kede iku ọkan lara awọn oludasilẹ rẹ, Olaolu Martins.
Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Iṣẹgun, Arakunrin Martins jade laye ṣugbọn wọn ko sọ ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Ẹni ti wọn jọ da ileeṣẹ ounjẹ igbalode naa silẹ to si jẹ oludari ileeṣẹ naa lọwọ bayi Rasheed Jaiyeola lo buwọlu atẹjade yi lorukọ ileeṣẹ wọn.
Ibeere ti o gba ẹnu ọpọ ọmọ Naijiria ati awọn to jẹ alabara ileeṣẹ ile ounjẹ naa bayi wa ni pe iru eeyan wo ni Laolu Martins to jade laye yi.
Laolu Martins jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta nigba to jade laye.
Lati ibẹrẹ pẹpẹ igbesi aye rẹ lo ti jẹ akikanju eeyan to ja fafa lẹnu iṣẹ.
Gẹgẹ bi ohun taa ri ka nipa rẹ, ileeṣẹ ayẹwe owo wo taa mọ si Price Water.
Loju opo rẹ to wa ni Linkedin la ti ri iroyin yi nipa rẹ.
Fasiti ilu Eko UNILAG lo ti kawe gboye to si tun ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ Stanbic IBTC laarin ọdun 2000-2005.
O kuro nibẹ lọ si Shell Nigeria ki o to wa lọ si Nigeria International Securities Limited to jẹ oludasilẹ nibẹ lati ọdun 2008 titi di igba to jade laye.
Awọn mọlẹbi rẹ naa ti fi atẹjade sita ni ikede iku ọmọ wọn.
Ninu rẹ, wọn ni ki awọn eeyan gbaruku ti mọlẹbi paapa iyawo, awọn ọmọ, obi ati awọn ọmọ iya rẹ lasiko yi.
Wọn ni ikede mii nipa eto isinku rẹ yoo maa waye laipẹ.
Loju opo ayelujara lawọn to jẹ ọrẹ ati alabaṣe rẹ ti n daro oniṣowo pataki to jade laye yi.