Obi Cubana fi ilé ńlá ta gbajúmọ̀ pásítọ̀, Jerry Eze, lọ́rẹ bíi ẹ̀bùn ọjọ́ọ̀bí ọdún kẹrìnlélógójì

Obi Cubana lapa osi, o wọ agbada funfun, de fila pupa, o n tẹ foonu rẹ o si n rẹrin-in. Pasitọ Jerry Eze lo wa lapa osi, o n sọrọ si ẹrọ gbohun-gbohun, o nawọ rẹ sapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Obi Cubana/ Facebook/ Pastor Jerry Eze/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iran olowo lo n ṣọrẹ olowo, awon oloṣi naa a si maa ṣe ọrẹ ara wọn nibi ori da wọn si.

Ni ti gbajugbaja olowo ọmọ ẹya Igbo, Obinna Iyiegbu tawọn eeyan mọ si Obi Cubana, ile nla kan lo ti fi tọrẹ bayii fun Pasitọ Jerry Eze toun naa jẹ gbajumọ ojiṣe Oluwa lawujọ.

Ọjọọbi Pasitọ Eze lo pe lanaa ọjọ Abamẹta, ọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026, ti Obi Cubana si kede pe oun bun un ni ọkan lara awọn ile nla toun n kọ lọwọ, ti yoo si pari loṣu Kejila ọdun yii.

Alaye Obi Cubana

Loju opo ayelujara ni Obi Cubana ti kede, pe ọkan lara awọn eeyan ti ọrọ wọn jẹ iyanu ni Pasitọ Jerry Eze to n dari ijọ Streams of Joy International, to si tun jẹ alakooso eto New Season Prophetic Prayers and Declarations (NSPPD).

Obi Cubana ki pasitọ naa fun awọn adura rẹ to n ṣe fawọn eeyan, ati ifarajin rẹ fun ọmọ araye.

"Lonii, mo fun ọ ni ile yii, eyi ti yoo pari loṣu Kejila, gẹgẹ bii imọriri gbogbo ohun ti o n ṣe."

Bẹẹ ni Obi Cubana kede.

O fi kun un pe ẹbun ile naa wa fun ṣiṣe atilẹyin iṣẹ ti pasitọ Eze n ṣe fun ọmọniyan.

O ni lati oṣu Kin-in-ni ọdun yii ni oun ti pinnu lọkan oun lati fun pasitọ naa nile kan lara awọn eyi toun n kọ lọwọ.

Cubana sọ pe oun ti ro o lọkan lati fi ṣe ẹbun fun Eze nigba ti yoo ba ṣe ọjọọbi rẹ loṣu Kẹjọ.

Amọ bi ile naa ṣe ku diẹ ko pari to, oun kede rẹ bayii pe o ti di ti Pasitọ Jerry Eze, oun yoo si pari rẹ fun un nigba ti yoo ba fi di oṣu Kejila ọdun 2026.

Ta a ni Pasitọ Eze Jerry?

Pasitọ Jerry Eze, o wọ aṣọ alawọ dudu, o kawọ rẹ mejeeji mọra bo ṣe n rẹrin-in.

Oríṣun àwòrán, Pastor Jerry Eze/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pasitọ Jerry Eze ni Olori awọn pasitọ ninu ijọ Streams of Joy International.

Ijọ yii wa fun nini ipa laye awọn eeyan kaakiri agbaye.

Pasitọ yii kan naa lo tun n dari eto New Season Prophetic Prayers & Declarations (NSPPD), eto kan ti wọn ti maa n gba adura lori ayelujara.

Nibẹ ni wọn ti maa n sọ aṣọtẹlẹ sinu aye awọn eeyan, awon to si ti ri iyanu nibẹ maa n jẹrii si agbara Oluwa.

O ti ju ọdun mọkanla lọ ti Pasitọ Jerry Eze ti da ijọ rẹ yii silẹ, o si ti gbèrú gidi.

Pastor Eze lo maa n sọ aṣayan ọrọ oyinbo kan to kari bayii, iyẹn 'What God Cannot Do Does Not Exist'. To tumọ si pe ko sohun ti Ọlọrun ko le ṣe.

Ẹka ijọ rẹ bayii ti le ni mẹrindinlọgbọn (26), wọn wa ni Naijiria, Canada, America ati UK.

Gbajumọ Pasitọ ni Jerry Eze, o si ti farahan ni awọn ikanni agbaye bii BBC, CNN atawọn mi-in.

Loju opo YouTube, ikanni rẹ ni awọn eeyan wo o ju ni Naijiria, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

Oun naa ni awon eeyan maa n woju to ba n ṣeto ẹsẹkẹsẹ (live) lori ayelujara bi akọsilẹ ṣe sọ.

Ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44) lo pe loke eepe lọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ 2026.