Olorì Oluwatosin bímọ obìnrin fún Ooni Ogunwusi lẹ́yìn oṣú mẹ́ta tí Olorì Maryam bí ìbejì

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Ogunwusi/ Facebook
Idunnu tun ti ṣubu lu aayọ laafin Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, pẹlu bi ọkan lara awọn olori rẹ; Oluwatosin, ṣe ṣẹṣẹ bimọ obinrin lanti-lanti.
Alekun oore ọmọ yii lo n waye lẹyin oṣu mẹta ti Yeyeluwa, Olori Maryam Ajibola Anako, bi ibeji ọkunrin fun Ooni si ilẹ alawọ funfun.
Ọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ikede ayọ naa waye pẹlu atẹjade kan ti Sodiq Lawal, agba olukede ni aafin Ooni fi sita lorukọ Adari ikede Ooni, Otunba Moses Olafare.
Ìya atọmọ wa ni alaafia ara ni ikede naa sọ.
Nigba to n fi ẹmi imoore han si Ọlọrun lori ìbimọ naa, Ooni Ogunwusi ṣalaye pe iya ati ọmọ wa ni alaafia ara.
"Ti Oluwa alagbara ni gbogbo ogo, fun oore ọfẹ rẹ ti ki i yẹ ati ẹbun pataki aye tuntun.
" Mo ki gbogbo ile Oduduwa pata fun dide Ọmọọbabinrin lati ọdọ Olori Oluwatosin."
Bẹẹ ni Ooni Adeyeye kede to si sure fun ọmọ tuntun naa.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Tẹ o ba gbagbe,lẹyin ti Naomi Silekunola to bi Tadenikawo, ọmọkunrin akọkọ fun Ooni Ogunwusi kuro laaafin ni Kabiyesi fẹ awọn olori mẹfa.
Laarin oṣu mẹta ni Ọba Adeyeye si fi fẹ wọn.
Awọn olori naa ni: Mariam Anako, Elizabeth Akinmudai; Tobiloba Philips, Ashley Adegoke, Ronke Ademiluyi ati Temitope Adesegun.




























