You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
''Ìjọba Tinubu ní láti máa san N100,000 gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ''
Lẹyin ijọba apapọ kede afikun owo iranwọ fawọn oṣiṣẹ latari bi gbogbo nkan ṣe gbowo lori bayii, akọṣẹmọṣẹ oluṣiro owo kan, Owolabi Salis ti rọ ijọba apapọ lati buwọlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira, N100,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
Ọgbẹni Salis to fi ilu New York ṣe ibugbe l'Amẹrika sọ pe awọn ọmọ Naijiria n la nkan ti ko fararọ kọja lasiko yii.
O ni ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ijọba ni ati rọwọ mu lọ si ẹnu ti nira fun bayii.
Salis ṣalaye pe ''nigba ti ijọba apapọ kede N30,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lọdun 2019, N325 ni awọn eeyan maa n ṣẹ owo dọla kan si nigba naa.
Amọ, lonii, owo dọla kan ti di ẹgbẹrun un kan naira ni Naijiria bayii.
Eyi gan an lo jẹ ki o nira fawọn ọmọ Naijiria lati gbe igbe-aye irọrun.
Bakan naa ni ounjẹ tun ti gbowo lori, yatọ si eto aabo to mẹhẹ to jẹ ki ebi maa pa ọpọ idile ni Naijiria.
Eleyii to tun dabi rẹ ni bi awọn fasiti ijọba atawọn ileẹkọ giga ṣe fi owo kun owo ile iwe eyi to si ti jẹ ko nira fawọn ọmọ talaka lati lọ si ile ẹkọ bayii.
N100,000 ko ju ọgọrun kan owo dọla lọ, ati wi pe ọpọ awọn oloṣelu lo n gba ẹgbẹrun lọna ogun owo dọla loṣooṣu.
Lẹyin ti a ba ti yọ owo ounjẹ, owo ile ati owo ọkọ tan ninu ọgọrun dọla, owo ti tan.
Owo gọbọi lawọn oloṣelu n gba lasiko yii eleyii ti ko jẹ ki nkan to wọn gogo ni wọn lara rara.
Aarẹ Bola Tinubu ni lati wa nkan ṣe si ọrọ to wa nlẹ yii nitori ebi n pa awọn araalu.''