Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ‘100 level’ dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekúpa ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀

SAFINA MOHAMMED ADIZATU

Oríṣun àwòrán, SAFINA MOHAMMED ADIZATU/TWITTER

Published

Ile ẹjọ kan ni Ghana ti fẹsun kan ọdọbinrin kan atawọn ọrẹ rẹ pe wọn ṣekupa ọkunrin kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Ghana amọ to n fi orilẹ-ede Canada ṣebugbe.

Wọn ni ọdọbinrin naa gbẹmi oloogbe ọhun to jẹ ọrẹkunri rẹ lasiko to wa sile fun ọjọ diẹ.

Ipele ẹkọ kinni ni afurasi naa, Safina Mohammed Adizatu, wa ni fasiti ijọba Ghana, iyẹn University of Ghana.

Gẹgẹ bii nnkan ti awọn ọlọpaa sọ, oun ati ọkunrin miran, Michael Fiifi Ampofo Arku, ni wọn jọ pa oloogbe ọhun.

Wọn ni ṣe ni oloogbe naa ṣabẹwo si Safina, to n gbe lagbegbe Ashalley Botwe School Junction, lati sun mọju ki afurasi naa atawọn ẹmẹwa rẹ mii, to gun lọbẹ pa.

Iroyin ni wọn gun lọbẹ ni ọrun, ẹrẹkẹ ati ẹyin ki wọn to tun fun lọrun pa.

Lẹyin ti wọn pa tan, wọn fi oku rẹ silẹ ninu ile fun wakati mẹrinlelogun nitori wọn ko mọ bi wọn yoo ṣe sin, amọ lẹyin wakati mẹrinlelogun naa ni wọn gbe oku ọhun sita lẹgbẹ ọkọ ayọkẹlẹ to gbe lọ sibẹ.

Lẹyin naa ni Safina ke si ọlọpaa kan to jẹ ọrẹ rẹ, to si sọ fun onitọun pe alejo oun ni oloogbe naa, amọ lojiji lo fo ṣanlẹ to si ku.

Safina Diamond

Oríṣun àwòrán, GHANA POLICE

Nigba ti awọn ọlọpaa de ibẹ lawọn ọlọpaa ṣakiyesi pe ejo lọwọ ninu lori ọrọ iku oloogbe naa ki wọn to bẹrẹ iwadii nibi ti akara ti tu sepo.

Oku ni ibatan mi wa ṣe nile ki wọn to pa danu – Mọlẹbi oloogbe

Ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe oku ẹgbọn rẹ to jade laye lo lọ ṣe ni Ghana ko to pade iku ojiji naa.

Ibatan rẹ ọhun, Obama Cee ni “O ti to ọdun mẹta bayii ti ifẹ ibatan mi ati obinrin yii ti fori sọgi, koda oloogbe na ti fẹ iyawo miran, o si ti bi ọmọ.”

Gẹgẹ bii ohun ti ibatan oloogbe naa sọ, o maa n fi owo atawọn ẹbun mii ranṣẹ si afurasi ọhun ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, yatọ si Safina, awọn ọlọpaa ti n wa awọn mii ti wọn fura si lori iku ọkunrin ọhun.