Àwọn olùdíje sípò ààrẹ tọwọ́bọ ìwé àdéhùn lórí ìbò ọjọ́ sátidé, ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, PETER OBI/TWITTER
Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń gbáradì láti dìbò yan ààrẹ tuntun ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kejì ọdún 2023, àwọn olùdíje tó ń dupò náà ti tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pé kò ní sí wàhálà kankan níbi ètò ìbò ọ̀hún.
Lára àwọn olùdíje tó péjú pésẹ̀ síbi ètò náà tó wáyé ìlú Abuja ni Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Atiku Abubakar ti PDP, Omoyele Sowore ti AAC, Rabiu Kwankwaso ti NNPP àtàwọn mìíràn.
Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party náà báwọn péjú pésẹ̀ síbi ètò náà.
Ẹ̀ẹ̀mejì ni títọwọ́ bọ ìwé àdéhùn náà wáyé fún ti ètò ìdìbò ọdún yìí lòdì sí ti ọdún 2015 tó jẹ́ ti ẹ̀ẹ̀kan.
Ní oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2022 ni wọ́n kọ́kọ́ buwọ́lu ìkan láti ṣàdéhùn pé kò ní sí rògbòdìyàn lásìkò ètò ìpolongo ìbò.
Lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí láti rí kí àláfíà wà lásìkò ìbò ni olórí orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀, Abdulsalam Abubakar, Bíṣọ́ọ̀bù Mathew Kukah àti dókítà John Momoh.
Àwọn mìíràn tó tún péjú síbẹ̀ ni ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, Mahmood Yakubu tó ṣèlèrí pé ètò ìdìbò náà yóò lọ bí àwọn ti ṣe làá kalẹ̀.
Bákan náà ni ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní inú òun kò dùn sí bí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú kò ṣe mú àdéhùn tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n tọwọ́bọ ìwé àdéhùn akọ́kọ́ ṣẹ.
Baba wá pàrọwà sí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú láti ba àwọn alátìlẹyìn wọn níwọ̀ọ́ kí ètò ìdìbò gbogbogboò le lọ nírọ̀rùn.
Ó tún rọ àwọn olóṣèlú láti wo àwòkọ́ṣe ààrẹ àná Goodluck Jonathan tó gba èsì ìdìbò ọdún 2015 láti lè mú kí àláfíà jọba ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ààrẹ Muhammadu Buhari náà báwọn péjú pésẹ̀ síbi ètò náà tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóò rí dájú pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.
Ààrẹ Buhari ní àwọn máa gba àwọn ọmọ Nàìjíríà láàyè láti yan ẹni tó bá wù wọ́n gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àti àwọn tí yóò máa jẹ́ olórí fún wọn láìsí wàhálà kankan rárá.
Ó ní àwọn ti ṣàfihàn èyí ní àwọn ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo, Ekiti, Osun àti Anambra níbi tí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà ti ní àǹfàní láti yan ẹni tó wù wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí wọn.
INEC bẹ̀rẹ̀ pínpín àwọn ohun èlò ìdìbò káàkiri àwọn ìpínlẹ̀
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pín àwọn ohun èlò ìdìbò káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ orílẹ̀ èdè yìí.
Èyí ló ń wáyé ní ìgbáradì fún ètò ìdìbò sípò ààrẹ àti àwọn aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí yóò wáy;e lọ́ja Àbámẹ́ta.
Àwọn ohun èlò ọ̀hún tó wà ní ìpamọ́ il;e ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, CBN tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pín sí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Pínpín àwọn ohun èlò náà ló wáyé níwájú àwọn aṣójú ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn olùwòye ètò ìdìbò àti àwọn akọ̀ròyìn.
Àwọn ọ̀gá àgbà àjọ INEC ní ìpínlẹ̀ Odsun àti Eko ní àwọn ti gbáradì láti ṣètò ìbò báyìí.
























