Ẹ tètè parí ìwádìí lórí Emefiele àti Bawa - Falana rọ DSS

Published

Femi Falana, Agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan ti ke si ajọ DSS pe ki wọn jara mọ iwadii ti wọn n ṣe lori ẹsun tí wọn fi kan AbdulRasheed Bawa, alaga ajọ EFCC tẹlẹ ati Godwin Emefiele, Gomina banki apapọ lorilẹede Naijiria tẹlẹ.

Emefiele ni ọwọ ajọ DSS tẹ lọjọ kẹwaa oṣu kẹfa lori esun ṣíṣe owo ilu mọkumọku.

Bawa, to jẹ alaga ajọ to n gbogi ti iwa ajẹbanu ni aarẹ Tinubu ni ko lọ rọkun nile lori ẹsun aṣilo agbara ipo rẹ.

Falana, lasiko to n sọrọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe ṣalaye pe ofin orilẹede Naijiria ko fi aye gba kí eeyan wa latimọle kọja wakati mẹrinlelogun ni agbegbe ti ile ẹjọ sunmọ.

"DSS ni lati gba aṣẹ lati le ti eeyan mọ atimọle ju iye wakati yii lọ ati pe tí ile ẹjọ ba fun wọn laṣẹ gan, o ni iye akoko ti eeyan fi le wa lọdọ wọn."

O wa rọ ìjọba apapọ lati mojuto igbẹjọ ọhun lati le yago fun awọn kudiẹkudiẹ to le da ẹjọ naa ru.

"Iwadii ni lati waye ni kiakia paapaa lori ẹsun to lagbara bayii, ni o lero pe o yẹ ki idaduro kankan wa lori awọn ẹsun yìí."

"Lori ọrọ Emefiele, Ajọ DSS fẹsun kan lọdun to kọja lori ṣiṣe owo ilu mọkumọku, ẹ jọọ ẹ gbe igbesẹ lori ẹsun naa ni kiakia."

Lori ọrọ Bawa, Falana ni o ṣeeṣee ki iwadii DSS ma peye lori ẹsun ti wọn fi kan-an ṣugbọn ijọba gbọdọ se kiakia pẹlu iwadii wọn