Igbó ni wọ́n n gbìn dípò Kòkó kaakiri okò nipinlẹ Edo báyì'- NDLEA

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ajọ to n gbogun ti egboogi oloro nilẹ Naijiria, NDLEA ti sọ pe ọpọ inu ok oni awọn oniṣẹ ibi fi n gbin igbo ti awọn eeyan n mu bayii dipo Kokoo to wulo fun araalu.
Ọga agba ajọ NDLEA nipinlẹ naa, Mitchell Ofoyeju lo fidi eyi mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aje, ọsẹ yii.
Ofoyeju sọ pe igbo ti awọn eeyan n gbin, lo ti n rọpo awọn ohun jijẹ to yẹ ki wọn maa fi oko ati igbo gbin bayii, leyi to si le ṣe akoba pupo fun alaafia ilu.
Nigba to n sọrọ, Ofoyeju sọ pe ilẹ to le ni diẹ ni ẹkita (2.27 hectares) ni awọn ti ṣafari, ti awọn kan fi gbin igbo si, to si lawọn ti ba gbogbo rẹ jẹ patapata.
Ofoyeju fidi rẹ mulẹ pe afurasi mẹta ni ọwọ awọn ti tẹ ninu iṣẹ iwadii ti awọn ṣe laaarin ọsẹ meji, ati pe iṣẹ iwadii naa ṣi n tẹsiwaju.
Nibẹ lo ti rọ gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ NDLEA lati le maa ta wọn lolobo, bi wọn ba kofiri awọn to n fi igbo ọba gbin egboogi oloro bii igbo.
O ni awọn alaga ijọba ibilẹ w ani ipo ti wọn ti le dẹkun itankalẹ egboogi oloro kaakiri ilu, paapaa bi awọn eeyan ṣe n gbin in.
"A ko le maa tẹsiwaju lọna yii mọ, nitori pe ohun to bẹrẹ gẹgẹ bi ọgba kekere, lo ti wa n di ohun ọgbin nla," Ofoyeju sọ bẹẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe, "ọsẹ meji la fi ba gbogbo oko naa jẹ. Awọn alaga ijọba ibilẹ ni wọn sunmọ araalu, a si nilo ibaṣepọ wọn."
Bakan naa lo sọ pe oko marun-un ọtọọtọ ni awọn ti ri ibi ti wọn fi gbin igbo ti iwọ rẹ lẹ ni ẹgbẹrun marun-un kilogiraamu (5,674.17kg).
Níbo ni wọ́n ti rí àwọn igbó tí wọ́n gbìn yìí?
Ọga agba naa sọ pe agbegbe Monday Camp to wa ninu igbo Usen, ijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Ovia ni wọn ti ṣawari oko meji ti wọn fi gbin igbo yii.
O ni awọn ṣawari oko meji miran ni awọn ṣawari ninu igbo Igwe-Oke, ijọba ibilẹ Ila-Oorun Owan; nigba ti awọn ṣawari oko karun-un ninu igbo Ogboha, ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Owan.
Àwọn tọ́wọ́ tẹ̀
Alaga NDLEA nipinlẹ Edo ṣalaye pe asiko ti awọn lọ ṣabẹwo si inu igbo ọba Ogboha lọwọ tẹ Sunday Segun, ẹni ọdun mọkandinlogoji.
O sọ pe ayika inu igbo ọhun lawọn ti ri Segun, ti igbagbọ si wa pe oun lo wa ni iṣakoso gbingbin igbo ọhun.
Ofoyeju tẹsiwaju pe ninu iṣẹ iwadii miran ti awọn ṣe lọ si garaaji Bob-Izua to wa loju ọna New Road, Okada, lọwọ ti tẹ Hammsa Mohammed pẹlu egboogi oloro to le ni iwọn kilogiraamu meje (7.1kg).
O ni awọn gba ọbẹ mẹta ati oniruuru oogun abẹnugọngọ lọwọ rẹ lasiko tọwọ tẹ ẹ.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe, yatọ si gbigbogun ti gbingbin egboogi oloro igbo, o lawọn tun gba egboogi oloro alagbara ninu iṣẹ iwadii ti wọn ṣe niluu Auchi.
Inu ọkọ ayọkẹlẹ kan lo sọ pe awọn ti ṣawari igo 590 ti wọn ko egboogi oloro codeine si, pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta egboogi tramadol ti jẹ iwọn ọgọrun miligiraamu.
Bakan naa lo ni awọn tun gba oogun tiramadọ ọgọrun to jẹ ọkọọkan jẹ iwọn 225mg, ati egboogi Diazepam ti ko din ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn.
Bẹẹ lo sọ pe ọwọ tẹ Jamie Zubaru lori iwadii kan ti awọn n ṣe lọwọ, ati pe afurasi naa ti n ran ileeṣẹ wọn lọwọ ninu iwadii awọn.






























