Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tẹ afurasí tó po pàrágà tó gbẹ̀mí èèyàn 29

Agbo jẹdi ninu ike.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin kan ti wọn fura si pe oun lo po agbo jẹdi kan ti ogogoro wa ninu rẹ, eyii to ṣokunfa iku eeyan ti wọn to ọgbọn ni ijọba ibilẹ Odigbo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Abayomi Jimoh lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin niluu Akure.

Jimọh sọ pe afurasi ọhun ti n ran awọn lọwọ lati wa kulẹkulẹ ohun to fa iku awọn eeyan naa.

O fi kun pe ogogoro ti wọn fura si pe o ṣokun awọn iku naa ti wa lakata awọn bayii ni itẹsiwaju iwadii ti wọn n ṣe.

Lara iwadii naa ni lati mọ eroja pato to wa ninu ogogoro naa ati ibaṣepọ rẹ pẹlu iku awọn ti ọrọ naa kan.

O sọ siwaju si pe ijọba ti n ṣe ayẹwo oku awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ti esi ayẹwo naa yo si ṣi aṣọ loju egungun gbogbo ohun to ṣẹlẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn oṣiṣẹ ẹka Criminal Investigation Department(CID), tun ti fi ṣikun ofin mu afurasi mẹrinla mii lori ẹsun pe wọn n ta oniruru agunmu ati paraga lagbegbe naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa so pe kọmisọna ọlọpaa, Felix Ohagwu, ti paṣẹ ki wọn fofin de gbogbo awọn to n ta paraga tabi agbo jẹdi ti ko gba ontẹ ijọba lagbegbe ọhun.

Ọjọ Ẹti to kọja ni ijọba ipinlẹ Ondo fidi rẹ mulẹ pe ọgọrọ eeyan jade laye ti awọn bii aadọta mi si dero ile iwosan lẹyin ti wọn mu nnkan ti wọn fura si pe o jẹ agbo jẹdi niluu Odigbo.

Kọmiṣọna ọlọpaa, Banji Awolowo-Ajaka, fidi rẹ mulẹ pe eeyan ti iye wọn to ọgọta ni ọrọ naa kan.

Ninu awọn eeyan naa ni eeyan mọkandinlogun ti jade laye, nigba awọn mẹtadinlọgbọ mii ṣi wa nile iwosan fun itọju lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Kọmiṣọna ọhun fikun pe pupọ awọn ti iṣẹlẹ naa kan ni wọn jẹ ọkunrin ti ọjọ ori wọn jẹ lati ọdun mẹrinla si ọdun marundinlaadọta.

Awọn agbegbe ti isẹlẹ na ti le koko julọ ni Orita Odigbo, Araromi-Obu, Newtown, Odole, Okele, ati Oniparaga.

Ṣé òótọ́ ni pé àgbo jẹ̀dí tí wọ́n fi ògógóró pò ló gbẹ̀mí ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn l'Ondo?

Ijọba ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iku ọpọ eeyan to tun gbe nnkan bii aadọta mii dele iwosan ni ijọba ibilẹ Odigbo.

Oniruru ilu ni iku naa ti waye ninu eyii ti Odigbo, Newtown ati Orita wa lara rẹ, to fi mọ Araromi-Obu.

Oniruru iroyin lo ti n lọ ni igboro pe agbo jedi tabi agunmu ti awọn eeyan naa mu lo ṣokunfa rẹ, amọ ki loṣokunfa isẹlẹ naa?

Ki lo ṣokunfa iku ọgọrọ eeyan naa?

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin ijọba ipinlẹ Ondo, The Hope sọrọ lẹyin to ṣabẹwo si awọn ile iwosan ni Arawomi-Obu ni ijoba ibilẹ Odigbo, kọmiṣọna fun eto ilera ipinlẹ naa, dokita Banji Ajaka sọ pe ijọba ko tii mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Amọ o sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ kokoro aifojuri kan to n gba ẹnu wọle lo ṣokunfa arẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iroyin ti ikọ oluwadii naa gba fi han pe o ṣeeṣe ki awọn eeyan ọhun ti mu agunnmu ti wọn fi ogogoro po pọ ki wọn to dubulẹ aisan.

O ni awọn oṣiṣẹ eto ilera ti gba awọn ohun ti wọn gbagbọ pe wọn mu, to fi mọ igbọnsẹ ati itọ wọn, wọn si ti ko lọ sinu laabu fun ayẹwo.

Kọmiṣọna naa ṣalaye pe wọn tun gba ẹjẹ awọn to ṣi wa nile iwosan lati ṣayẹwo rẹ boya awọn nnkan mii to lewu wa ninu rẹ, eyii ti yoo le ṣalaye ohun to pa awọn to ti doloogbe.

Igbagbọ tun wa pe wọn maa ṣe ayẹwo oku awọn to ti jade laye lati mọ siwaju si nipa iṣẹlẹ naa.

Iye awọn awon lo ku ni pato?

Nigba ti awọn akọroyin bere lọwọ rẹ iye eeyan to ku ni pato, Ajaka ni "Mi o tii le sọ lọwọ yii."

Lẹyin naa lo tun kilọ fun awọn araalu ki wọn dẹkun ati maa gbe iroyin nipa iye eeyan to ku ni pato kiri lai fidi rẹ mulẹ.

O ni lẹyin ti ijọba ba ti pari iwadii rẹ tan ni yoo kede iye awọn ti ọrọ naa kan ni pato.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn araalu ki wọn sọra fun mimu ohun ti wọn ko mọ ipinlẹ rẹ tabi eyii ti ko gba ontẹ jọba.

A ti bẹrẹ iwadii - Ọlọpaa

Ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ naa ti fidi iroyin ọhun mulẹ bo tilẹ jẹ pe wọn lo kede iye eeyan pato to ku ninu iṣẹlẹ ọhun.

Agbẹnbusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ni ifọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ondo atawọn ajọ mii ti ọrọ naa kan ti n ṣiṣẹ takuntakun lati wadii ọrọ naa.

Ọlọpaa sọ pe iwadii ṣi n lọwọ, nitori naa ki awọn araalu ma di ẹbi iku naa le ohunkohun lori titi ti iwadii yoo fi pari ti wọn yoo si mọ ohun to ṣokunfa rẹ.

Jimoh pari atẹjade naa pe ọlọpaa ni ajọṣepọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ondo yoo tẹsiwaju lati maa bun araalu gbọ nipa ibi ti iṣẹ de duro lori iwadii wọn.