Kí nídìí tí INEC kò fi kéde orúkọ àwọn olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Accord àti NNPP?

Dikwa, Tinubu, Hashim-Olawepo ati Makinde

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Oludije sipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu Accord, Gbenga Olawepo-Hashim ti bu enu ate lu ajọ to n mojuto eto idibo, INEC fun bi wọn ko ṣe fi orukọ rẹ sara orukọ awọn oludije sipo aarẹ ti wọn gbe sita lopin ọsẹ.

Olawepo-Hashim ninu atẹjade kan to fi soju opo Facebook rẹ sọ pe INEC ko laṣẹ labẹ ofin lati yọ orukọ oun kuro lara awọn oludije sipo aarẹ bi o ṣe jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu oun lo panupọ yan oun gẹgẹ bi oludije.

O ni oun ni oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Accord ti ko si si ẹni to maa yọ oun nipo naa.

O woye pe ofin Naijiria ko fi aaye gba INEC lati yan ẹni ti yoo jẹ oludije sipo oṣelu fun ẹgbẹ oṣelu kankan.

O ni ile ẹjọ nikan lo ni aṣẹ lati gbe igbesẹ nibi ti ifanfa ba ti n waye ninu ẹgbẹ lori ipo kan tabi omiran, to si ni bi INEC ko ṣe gbe orukọ oun jade ko tumọ si pe oun ko ni kopa ninu eto idibo naa mọ.

O fi kun pe irufẹ iṣẹlẹ bayii nibi eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Osun ninu oṣu Kẹjọ nibi ti ile ẹjọ ti sọ fun INEC lati da orukọ awọn ti wọn ko kọkọ gbe orukọ wọn jade lati da wọn pada, ti wọn si kopa nibi eto idibo naa.

Olawepo-Hashim ni ọrọ naa ti wa niwaju ile ẹjọ giga ti ilu Abuja, nibi to ti n beere pe ki ile ejọ paṣẹ ki ẹgbẹ oṣelu Accord ri oun gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ wọn nibi eto idibo ọdun 2027.

O ni ile ẹjọ ti gbọ ẹjọ naa, to kan ku pe wọn n duro de idajọ.

Kí ni INEC sọ?

Amọ ọga agba kan to n ṣiṣẹ pẹlu INEC gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin TheGuardian ṣe sọ, o ni INEC ko le yọ orukọ oludije ti ẹgbẹ oṣelu ba ti yan gẹgẹ bi oludije wọn.

O ni ti kii ba ṣe pe ẹgbẹ oṣelu kan ba kọwe ranṣẹ si INEC pe ki wọn yọ orukọ oludije wọn tabi paarọ rẹ tabi ki ile ẹjọ paṣẹ bẹẹ, o ni INEC ko kan le gbe igbesẹ bẹẹ.

Yatọ Gbenga Olawepo-Hashim, INEC ko tun kede oludije sipo aare lẹgbẹ oselu New Nigeria People's Party, NNPP, Suleiman Dikwa.

Ṣaaju ki INEC to gbe orukọ awọn oludije sipo aarẹ Naijiria patapata lo ti kọkọ gbe orukọ kan eyi ti orukọ oludije lẹgbẹ oṣelu Accord ati NNPP wa ninu wọn.

INEC kéde pé ADC ẹgbẹ́ òṣèlú Atiku ati NDC ti Obi kò rí olùdíje si gbogbo ipò Aṣoju-ṣofin ati Sẹnetọ ninu idibo 2027

Awọn oludije sipo aarẹ ti INEC kede

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ajọ Eleto Idibo INEC ti kede pe oludije mọkandinlọgọrun un, 99 ni ẹgbẹ oṣelu NDC fi sita fun ipo Senetọ 109 mọkan din laadọfa to ṣi silẹ.

Nigba ti wọn si fi oludije 327 silẹ fun ipo 360 to wa fun awọn Aṣoju-ṣofin NAijiria ni Abuja.

Nibo ni ADC ẹgbẹ oṣelu Atiku Abubakar ko ti ni?

Awọn agbẹgbẹ ti wọn ko ti ni Oludije ni Bauchi South, Bauchi Central, Bauchi North, Benue Northeast, Ekiti South, Jigawa Northeast, Kaduna South, Katsina Central, Yobe East and Yobe North.

Nibo ni NDC ẹgbẹ Peter Obi ko ti ni Oludije?

Ẹgbẹ oṣelu NDC ti Peter Obi n ba dije dupo aarẹ Naijiria naa ko ni oludije fun ipo Sẹnetọ ni ipo mẹwaa.

Bakan naa ni wọn ko ni oludije ni ipo Aṣoju-ṣofin ni ipo mẹtalẹlọgbọn 33.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kini INEC tun sọ?

Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ti kede awọn oludije ti yoo kopa ninu eto idibo sipo aarẹ ti yoo waye lọdun 2027.

Yatọ si awọn oludije sipo aarẹ ti ajọ INEC fi sita, wọn tun kede orukọ awọn igbakeji ti wọn yoo jọ dije du ipo naa ninu oṣu Kinni, ọdun 2027.

Ninu orukọ naa ti INEC gbe jade, eyi ti akọwe rẹ, Rose Oriaran-Anthony, buwọ lu lọjọ Abamẹta to kọja niluu Abuja, lo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn oludije naa ni ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun fi ranṣẹ si wọn.

Gẹgẹ bi alakalẹ ajọ INEC, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Kiini ọdun 2027 ni eto idibo sipo aarẹ atawọn ile aṣofin apapọ maa waye nigba tie to idibo sipo awọn gomina ati ile asofin ipinlẹ maa waye lọjọ Kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2027.

Gbigbe orukọ awọn oludije sita lo w ani ibamu pẹlu ofin to n ri si eto idibo Naijiria tọdun 2026 eyi to la gbogbo bi eto idibo gbọdọ ṣe lọ kalẹ.

Gẹgẹ bi alakalẹ ofin to de eto idibo Naijiria, ẹgbẹ oṣelu ti ko ba fa orukọ oludije kalẹ ko ni kopa nibi eto idibo.

Ni bayii, o ti han pe gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu to wa ni Naijiria lo fa oludije ati igbakeji wọn kalẹ fun eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.

Ẹwẹ, ninu gbogbo awọn oludije mejidinlogun naa, Atiku Abubakar ni o dagba julọ ẹni ti ọjọ ori rẹ jẹ ọdun mọkandinlọgọrin (79), ti Aarẹ Bola Tinubu si tẹle lọjọ ori lẹni ọdun mẹrinlelaaadọrin (74).

Oludije lẹgbẹ oṣelu PRP, Donald Duke lo ni igbakeji to dagba julọ, Rabiu Kabiru ẹni ti ọjọ ori rẹ jẹ ọgọrin ọdun (80).

Ẹgbẹ oṣelu Democratic Leadership Alliance, DLA ti wọn ṣẹṣẹ forukọ silẹ pẹlu INEC lo ni oludije, Adebisi Moses Olusoji ati igbakeji, Abubakar Nafisat Usaku ti ọjọ ori wọn kere julọ ti wọn si jẹ ẹni ọdun marundinlogoji.

Wo akojọ orukọ awọn oludije lẹgbẹ oṣelu kọọkan ati igbakeji wọn

  • Oludije: Sowore Omoyele
  • Igbakeji: Magashi Haruna Garba

Omoyele Sowore ni oludije ti ẹgbẹ oṣelu AAC fa kalẹ nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ naa.

Akọroyin ni Sowore, to si tun maa n ja fun ẹtọ awọn eeyan. Oun si lo ni ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters.

Ọpọlọpọ igba ni ijọba Naijiria ti fofin gbe Sowore ti wọn si fi si ahamọ.

Oṣu mẹta ni Sowore lo ni ahamọ lẹyin ti wọn fi pampẹ ofin gbe e ni ọjọ Keji, oṣu Kẹjọ ọdun 2019 fun ẹsun pe o n ditẹ mọ ijọba ki wọn to fi silẹ ninu oṣu Kejila ọdun 2019 kan naa.

Ọmọ ẹgbẹ 34,522 ni ẹgbẹ oṣelu AAC ni kaakiri Naijiria.

  • African Democratic Congress (ADC)
  • Oludije: Abubakar Atiku
  • Igbakeji: Amaechi Chibuike Rotimi

Atiku Abubakar lo n dije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC.

Odu ni Atiku nidii eto oṣelu Naijiria, kii ṣ aimọ foloko rara. Ọpọ igba lo ti gbiyanju lati dupo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu oriṣiriṣi.

Ọdun mẹjọ lo fi ṣe igbakeji aarẹ Naijiria lasiko iṣejọba aarẹ Olusegun Obasanjo.

O dije dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP to si ṣe ipo keji.

  • APC
  • Oludije: Tinubu Bola Ahmed
  • Igbakeji: Shettima Kashim

Bola Tinubu ni aarẹ to n ṣejọba Najiria lọwọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lẹyin ti INEC kede pe oun lo gbegba oroke nibi eto idibo ọdun 2023.

Bakan naa lo tun ri tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu rẹ gba lati tun dije lọdun 2027.

Asiwaju Bola Tinubu ṣe gomina ipinlẹ Eko fun saa meji laaarin ọdun 2003 si 2007.

Igba keji ree ti Tinubu yoo maa dije dupo aarẹ Naijiria.

  • APM
  • Oludije: Makinde Oluseyi Abiodun
  • Igbakeji: Musa Lawal Daura

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni oludije sipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement, APM fun eto idibo gbogbogbo 2027 lẹyin ti wọn kede rẹ nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu naa.

Saa meji ni Seyi Makinde lo nipo gomina ipinlẹ Oyo, to si jẹ onimọ ẹrọ ṣaaju ko to wọnu oṣelu.

Makinde ni afojusun oun ti oun fi fẹ dupo aarẹ ni lati mu atunto ba eto ọrọ aabo ipinlẹ Naijiria ti ipinlẹ kankan ko ni di akurẹtẹ ti wọn ba koju iṣoro.

  • Nigeria Democratic Congress (NDC)
  • Oludije: Obi Peter Gregory
  • Igbakeji: Musa Mohammed Rabiu Kwankwaso

Ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) fidi Peter Obi mulẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ wọn.

Gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Anambra ni Peter Obi to si ni ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn n fẹ lori ayelujara.

Abẹ asia ẹgbe oṣelu Labour Party lo ti dije dupo aarẹ lọdun 2023 to si gbe ipo kẹta amọ to fi ẹgbẹ naa silẹ lọdun 2025.

Lẹyin naa lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADC ko to tun ta kọsọ sinu NDC.

  • Peoples Democratic Party (PDP)
  • Oludije: Onor Sandy Ojang
  • Igbakeji: Umaru Babangida

Mọ̀ nípa àwọn olùdíje méjìndínlógún tó ń dupò ààrẹ Nàìjíríà

Fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), awọn ifanfa kan to waye ninu ẹgbẹ naa mu ki wọn pin sọna meji.

Amọ ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un ni igun ti Minisita fọrọ ilu Abuja, Nyesom Wike n dari panupọ lati kede sẹnetọ tẹlẹ ri, Sandy Onor bi oludije wọn.

Igun keji ni ti wọn kede pe aarẹ tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan ni oludije wọn.

Lẹyin o rẹyin, Sandy Onor ni INEC kede bii oludije PDP.

  • PRP
  • Oludije: Duke Donald
  • Igbakeji: Rabiu Kabiru
  • Gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Cross River ni Donald Duke, to n dije lẹgbẹ oṣelu People's Redemption Party (PRP).

Nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ naa to waye ninu oṣu Karun-un ni Donald Duke la ẹnikeji rẹ, Kinsley Yakubu mọlẹ.

  • Social Democratic Party (SDP)
  • Oludije: Adebayo Adewole Ebenezer
  • Igbakeji: Bugaje Usman Muhammed
  • Eekan oloṣelu ati agbẹjọro to n dije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) ni Adewole Adebayo.

Oun nikan ni oludije ti ẹgbẹ naa fa kalẹ nibi eto idibo abẹnu egbẹ naa to waye ninu oṣu karun-un.

Awọn wo tun ni?

  • Action Alliance (AA)

Oludije: Rufai Adekunle Omo-Aje

Igbakeji: Shehu Hussaini

  • Action Democratic Party (ADP)

Oludije: Abbas-Bin Aliyu

Igbakejie:Ike Chinazam

  • Action Peoples Party (APP)

Oludije: Yusuf Kabiru

Igbakeji: Ofordile Peace Egobia

  • BP

Oludije: Adenuga Sunday

Igbakeji: Mustapha Usman Turaki

  • DLA

Oludije: Adebisi Moses Olusoji

Igbakeji: Abubakar Nafisat Usaku

  • Labour Party (LP)

Oludije: Okereke Sunday Chibuzo

Igbakeji: Konto Hajja Bintu

  • NDP

Oludije: Okwori Ada Elizabeth Fredrick

Igbakeji: Chukwuemeka Uchenna Anthony

  • NRM

Oludije: Okereke Nkem Esther

Igbakeji: Sulaiman Nasir Muhammed

  • Young Progressives Party (YPP)

Oludije: Agada Peter Ada

Igbakeji: Key Patience Ndidi

  • Zenith Labour Party

Oludije: Nwanyanwu Daniel Daberechukwu

Igbakeji: Hassan Khalid