You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Henry Kissinger gbajúgbajà aṣojú ìjọba orílẹ̀èdè America papòdà lẹ́ni ọdún 100
Minisita fọr ilẹ okere nigba kan ri forileede America Henry Kissinger ti dagbere faye lẹni ọgọrun ọdun ni ile rẹ to wa ni Connecticut.
Atẹjade lati ọwọ Kissinger Associates ko sọ ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Nigba aye rẹ Kissinger jẹ ogbontarigi aṣoju orileede America to tun jẹ olubadamọran aarẹ lori ọrọ aabo lasiko ijọba aarẹ Nixon ati aarẹ Ford
O gbiyanju nipa amulo ilana détente ti America lo lati fi mu ki ibaṣepọ laarin America pẹlu Soviet Union ati China gunrege nigba naa.
Awọn kan fẹsun kan wi pe o dọgbọ ṣegbe fun iditẹgbajọba to mu ẹmi lọ eleyi to waye ni orileede Chile.
Kissinger yi kanna ni wọn fun lami ẹyẹ igbelarugẹ alaafia Nobel Peace Prize.
Awọn mii a si maa foju ọdaran to ṣaburu nigba ogun wo aṣoju ijọba ilumọọka yi.
Ọmọ akẹkọọ ti wọn bi ni Germany to pada di aṣoju America
Tohun ti pe o kuro ni ijọba lọdun 1970 Kissinger ṣi jẹ eekan tawọn olori a maa kan si fun amọran lori ọrọ ilẹokere.
Ọmọ bibi orileede Germany ni Kissinger jẹ ti wn si bi lọdun 1923.
O jẹ akọbi ọmọ olukọ ti ogun si le kuro lati Germany wa si America lọdun 1938.
Titi to fi ku, ede ẹnu rẹ ṣi n tọka si ibi to ti ṣẹwa.
O gbawe ọmọ onilẹ America lọdun 1943 to si fi ọdun mẹta ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ologun lẹyin to tun ba ẹka ọtẹlẹmuyẹ naa ṣiṣe pọ.
Lẹyin to kawe gboye kini, keji ati ikẹta ni fasiti, o ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ fasiti lori ọrọ ilẹ okere ni Harvard.
Lọdun 1969, aarẹ igba naa Richard Nixon yan sipo olubadamọran lori ọrọ aabo.
Ipo yi lo fun ni obitibiti agbara eleyi to fi n ṣe idari ati akoso ọrọ ilẹ okere America.
Gbo nkan tawọn olori lagbaye n ṣọ nipa rẹ
Aarẹ America tẹlẹ George W Bush ṣapejuwe Henry Kissinger lewaju awọn to n ṣe idaro Kissinger.
O ni ''America ti padanu ọkan ninu awọn ohun to lamilaaka nipa ọrọ ilẹ okere to ni''
Awọn ọmọ aarẹ tẹlẹ Richard Nixon,Tricia Nixon ati Julie Nixon Eisenhower sọ pe ''itan aye Kissinger jẹ manigbagbe- to si fi han pe o julowo ọmọ America nii ṣe''
Atẹjade ti wọn fi sita tẹsiwaju pe ''Titi la o maa ṣe iranti Kissinger fawọn aṣeyọri rẹ latimuitẹsiwajuba alaafia''
Wọn fi kun ''ṣugbọn iwa rẹ la o ni gbagbe nipa rẹ''
Lorileede China ti wọn ti mọ daada tori ipa to ko ninu mimu ibaṣepo to gunrege waye laarin America ati China,ikede iku rẹ gbode kan loju opo wọn Weibo.
Ikede iku rẹ ti ileeṣẹ iroyin China News gbe sita juwe rẹ gẹgẹ bi ''ọrẹ atijọ awọn eeyan orileede China''
China Central Television juwe rẹ gẹgẹ bi ''ogbontarigi aṣoju'' orileede to ko ipa ribiribi ninu ibaṣepọ laarin China ati America.
Ka ma gbagbe pe bawọn kan ṣe n kan sara si Kissinger lawọnmi fun ọpọ ọdun ko ye maa bẹnu atẹ lu Kissinger.
Awọn wọnyi sọ pe o pataki ifigagbaga America ati Soviet Union ju ẹtọ awọn eeyan lọ.
Wn tun lo ṣatilẹyin fun ijọba amunisin jakejado agbaye to fi mọ ti aarẹ Augusto Pinochet lorileede Chile nigba naa lọhun.
Gbogbo awọn ẹsun yi si ni Kissinger tio tako nigba aye rẹ,