You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mi ò ní #15m láti fi ra fọ́ọ̀mù tí máa fi díje - Babatunde Gbadamosi
Olùdíje sípò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú, Action Democratic Party, ADP, lọ́dún 2019 ti sọrọsoke.
Oun naa ló tún jẹ́ olùdíje sípò àtúndì ìbò Sẹ́nétọ̀ ẹkùn ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Eko lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP lọ́dún 2020, Babatunde Gbadamosi ti fohùn léde lórí èròńgbà láti tún díje lọ́dún 2023.
Gbadamosi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ayélujára Facebook rẹ̀ ní láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni àwọn ènìyàn ti ń sọ fún òun láti díje dupò gómìnà.
Ó ní púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ló ń pe òun láti díje dupò gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party.
Ó ní ìpè yìí jẹ́ òun tó wú òun lórí tó sì mú òun náà lọ́kàn ní tòótọ́.
Gbadamosi wá kọ ọ́ wí pé bí èròńgbà náà ṣe dá tó àti pé ìpínlẹ̀ Eko nílò bọ̀ lọ́wọ́ àjàgà àwọn tó sọ ọ́ di akoto owó wọn, ó ní ìgbésẹ̀ náà nílò owó gidi.
Ó ní lásìkò yìí, lẹ́yìn tí òun ti díje ni ẹ̀meèjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ léra wọn lọ́dún 2019 àti 2020, òun kò ní owó kankan láti ná díje kankan mọ́
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó jọ wí pé ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko tí wọ́n bá gbé ènìyàn tó dáńtọ́ kalẹ̀ àmọ́ òun kò ní owó láti ná mọ́
Ó fi kun un pé òṣèlú tí òun ti ṣe sẹ́yìn tí kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ wí pé àwọn ènìyàn kò ì tíì ṣetán láti bọ́ nínú àjàgà, ọ̀nà kan tí òun fi le gbà ni pé tí wọ́n bá fi ẹ̀mí ìfarajìn hàn.
Gbadamosi tẹ̀síwájú wí pé tí àwọn ènìyàn bá fẹ́ kí òun díje kí wọ́n dá owó pọ̀ láti lọ ra fọ́ọ̀mù ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party tí wọ́n ń tà ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún fún òun.
"Nígbà náà ni mà á gbà wí pé àwọn ènìyàn tí ṣetán láti jẹ́ kí a gba àwọn"
"Gbogbo owó tí wọ́n máa san fún fọ́ọ̀mù kò ju ogún mílíọ̀nù náírà lọ
Ati pé ó di ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹjọ kí gbèdéke tí INEC fún àwọn ẹgbẹ́ láti forúkọ olùdíje sípò gómìnà wọn sọ́wọ́ yóò wá sópin".
Ó ní láìsí èyí òun kò ní "shish" tí òun lè dà sórí òṣèlú mọ́.