Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí fídíò tó ṣàfihàn báwọn ọlọ́pàá kan ti ṣe ìkọlù sí ọ̀dọ́kùnrin tó ń ta góòlù l'Eko

Ibi ti ikolu naa ti waye l'Eko

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Okunrin ti olopaa se ikolu si
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ijinlẹ lori fọnran kan to ṣafihan bi awọn ọlọpaa kan ṣe ṣe ikọlu si ọkunrin kan to n ta goolu nipinlẹ naa.

Atẹjade ti ọlọpaa fi sita loju opo 'X' wọn lo fidi eyi mulẹ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ti mọ ibi ti awọn ọlọpaa tọrọ naa kan ti n ṣiṣẹ.

Agbegbe ti wọn n pe ni Festac nipinlẹ Eko ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Ẹti to kọja, ṣugbọn ti fọnran naa jade sori ayelujara lọjọ Abamẹta, ko to di awuyewuye nla.

Ọlọpaa sọ pe ẹkun E (Area E) ni awọn ọlọpaa naa ti n ṣiṣẹ, ti a si gbọ pe asiko ti ọkunrin oni goolu naa fẹẹ lọ gbe ọja goolu fun onibara rẹ ni wọn da a duro lati ṣe ikọlu si i.

Funra ọkunrin ọhun la gbọ pe o gbe fọnran naa sita lọjọ Abamẹta, to si ni b'awọn ọlọpaa ọhun ṣe da oun duro, ni wọn ti bẹrẹ sii ṣe ayẹwo, to si jẹ pe wọn ko ri ohunkohun to jẹ ẹru ofin lara oun.

Ọkunrin ọhun sọ pe awọn ọlọpaa fi ẹsun kan oun pe ẹrọ toun fi n ṣe odiwọn goolu fawọn onibara oun ni wọn sọ pe oun n lo lati fi wọn egboogi oloro, to si loun sọ fun wọn pe ko ri bẹẹ.

O wa sọ pe awọn ọlọpaa naa sọ foun lati wọ inu ọkọ wọn, ati pe oun yoo de teṣan lati ṣe iwadii rẹ siwaju, to si loun ko gba fun wọn.

O ni oun ko gba lati wọ inu ọkọ wọn, nitori toun ko ṣẹ ẹṣẹ kankan, ati pe oun fura si awọn ọlọpaa naa nitori pe wọn ko mura gẹgẹ bi ojulowo ọlọpaa, bẹẹ si ni ọkọ ti wọn gbe jade ko ni nọmba idanimọ.

Bakan naa lo sọ pe nibi ti wọn ti n fipa mu oun wọnu ọkọ wọn, ni wọn ti fi idi ibọn gba wọn lori, ti wọn si lu oun nilukulu.

Fọnran naa wa ṣafihan bi awọn ọlọpaa ọhun ṣe n ṣe ikọlu si ọkunrin ọhun lẹgbẹ bọọsi ti wọn n pe ni Korope, ko to di pe wọn ge oju rẹ, toun naa si ṣafihan ibi ti wọn ti fi nnkan ge oun loju.

Siwaju sii ni fọnran miran tun ṣafihan ibi ti ọkunrin ọhun ti fẹsun kan ọkan lara awọn ọlọpaa naa ti sọ fun akégbẹ rẹ lati yinbọn, ko to di pe wọn na papa bora.

A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí - Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀

Nigba ti wọn n sọrọ lori fọnran ọhun, ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti da ọlọpaa ọhun mọ, ati pe awọn ti ranṣẹ pe wọn lati wa sọ idi ti wọn fi gbe igbesẹ naa, lati bẹrẹ iwadii.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ri fọnran yẹn, ati pe a ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa," ọlọpaa sọ bẹẹ.

"Awọn ọlọpaa tọrọ naa kan la ti da mọ gẹgẹ bii pe ẹkun agbegbe E ni wọn ti n ṣiṣẹ. Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, Tijani Fatai, ti paṣẹ pe ki ọga ọlọpaa ẹkun naa ko gbogbo wọn wa si olu ileeṣẹ wa lati bẹrẹ iwadii, ati igbesẹ to yẹ.

"A rọ ọkunrin tọrọ naa kan lati kan si ẹka to n ri si ifẹsunkan nileeṣẹ ọlọpaa pẹlu eyikeyi ninu awọn ẹrọ ibanisọrọ yii 09111111150, 09111111151 lati le ran iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post