Tinubu sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Oriire lákàtà ajínigbé, kókó ohun tó sọ rèé

Bola Tinubu wọ agbada olomi buluu ati fila, Arabinrin Rachael Alamau wọ aṣo olomi buluu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fun igba akọkọ lẹyin ti awọn olukọ atawọn akẹkọọ ti ajinigbe ko wọgbo lọ l'Ogbomoso loṣu Karun-un gba itusilẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti ṣalaye pe ijọba oun kọ lati sanwo itusilẹ fawọn ajinigbe naa fun awọn idi kan.

Ọjọbọ ọsẹ yii ni Tinubu ṣalaye naa fawọn ọba alaye lati ipinlẹ Oyo, to ṣabẹwo si i niluu Abuja lati ki i fun aṣeyọri naa.

Nibẹ ni Aarẹ ti sọ pe kaka kijọba oun dunaa-duraa pẹlu awọn ajinigbe, awọn ẹbi wọn lawọn fi ofin mu ṣinkun.

Koko ọrọ Aarẹ Tinubu lori itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ Oriire

Ninu alaye Aarẹ Tinubu lo ti ni awọn ajinigbe naa beere owo ati itusilẹ awọn ikọ wọn to wa ni ọgba ẹwọn ki wọn too le tu awọn olukọ ati akẹkọọ to wa nigbekun wọn silẹ.

O ni ṣugbọn ijọba oun kọ jalẹ lati ṣe ohun ti wọn fẹ.

Aarẹ Tinubu sọ pe kaka bẹẹ, ọgbọn inu ati òye awọn ologun lo mu aṣeyọri naa wa tawọn to wa nigbekun fi gba iyọnda lẹyin ọjọ mẹrindinlọgọta.

"A sọ fun wọn pe a ko gba. A o ni I ba awọn ọdaran dunaa-dura. Wọn pa eeyan, awa naa si ti ṣetan lati ba awọn ẹbi wọn fa a delẹ, ati awọn eeyan agbegbe wọn, ibi kan lawọn naa dagba si, a si ko wọn.

"Ero temi ni pe a ṣe aṣeyọri pẹlu atilẹyin ati adura yin.

"Mo gba pe a gbọdọ gbe oriyin fawọn ologun lọkunrin ati lobinrin fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe."

Tinubu ṣalaye pe awọn ologun ṣe aṣeyọri nitori wọn mọ apade-alude igbo naa.

Ẹkọ ti ijọba kọ lara iṣẹlẹ ijinigbe Ogbomoso

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ fi kun un pe iṣẹlẹ yii tun kọ ijọba apapọ lẹkọọ, o ṣi oju ijọba si ohun to yẹ, eyi to mu koun sọ ikọ ologun mẹjọ di mejila wayi.

Aarẹ sọ pe boun ṣe sọ ikọ ologun di mejila lati mẹjọ, jẹ idahun si iṣoro aabo, ti yoo jẹ ki ologun wa ni arọwọto lawọn agbegbe, ti yoo si ro wọn lagbara si I lati koju awọn agbesunmọmi.

Bakan naa ni Tinubu kede ipinnu rẹ lati tun awọn ọdẹ aṣogbo kọ, oun yoo si tun fun wọn ni nnkan ija ogun si i.

O ni ọlọpaa ipinlẹ yoo ṣee ṣe lai si pe wọn yoo ṣi agbara lo.

" Ọlọpaa ipinlẹ yoo wa, yoo si ni gàgá ti wọn o fi ni i ṣi agbara lo.

"A maa da aabo bo o lọwọ iwa aitọ, ẹyin ọba alaye naa yoo si ni ipa tẹ ẹ maa ko nibẹ."

Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu wi.

O di ẹbi ijinigbe to n lagbara si i le aabo to mẹhẹ ni Naijria ati awọn agbegbe Sahel ti orilẹede yii mule ti.

"Awọn mi-in ninu awọn ajinigbe yii ki i ṣe ọmọ Naijiria, ṣe ẹ ri iṣoro aabo ti wọn n koju ni Mali, Burkina Faso ati Niger Republic n da kun iṣoro wa.

"Nitori ẹ la ṣe gbọdọ ro awọn ọdẹ aṣogbo wa lagbara si I, ka si ṣe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ,'' Aarẹ Tinubu lo ṣalaye bẹẹ.