Ikú dóró! Gbajúmọ̀ olórin Juju St. Janet jáde láyé

Oríṣun àwòrán, St Janet/Instagram
Iroyin ibanujẹ lo tun suyọ lagboole olorin nilẹ Naijiria, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ọkan lara awọn gbajugbaja olorin nni, Iyun Janet Ajilore tọpọ awọn eeyan mọ si St Janet ti jade laye.
Saint Janet, gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n pe e, lo ki aye pe o digboṣe lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo da a dubulẹ lati bi oṣu diẹ sẹyin.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni ilu-mọ-ọn-ka olorin naa fi aye silẹ, gẹgẹ bi awọn to sunmọ ọn ṣe gbe e sita.
Ọpọ awọn akẹgbẹ olorin naa lo ti gbe iroyin iku rẹ sori ikanni ayelujara wọn, nibi ti ọpọ ti n barajẹ pupọ lori ipapoda rẹ lai ro tẹlẹ.
"Pẹlu ibanujẹ, a n kede ipapoda St. Janet (Iyun Janet Ajilore), ẹni to fi aye yii silẹ lẹyin aisan rampẹ," ọkan lara awọn atẹjade ori ayelujara sọ bẹẹ.
Atẹjade ọhun fi kun un pe, "Orin rẹ, ẹbun rẹ, ohun ara ọtọ rẹ fọwọ kan aye ọpọ eeyan, to si fi ipa manigbagbe silẹ lagboole amuludun. Ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rẹrẹ. Titi ayeraye la o maa ranti rẹ."
Lara awọn to fi iroyin iku St Janet sita, pẹlu ọrọ ibanikẹdun ni Ayoola Akinola Michael tọpọ mọ si Alayo Melody Singer.
"A n gbe ile aye lonii, a maa ku to ba di ọla! St Janet, ki Ọlọrun tẹ ẹmi rẹ si afẹfẹ rere," Alayọ Singer banujẹ.
Bakan naa ni gbajugbaja oniroyin nni, Otunba Femi Davies naa fidi iroyin ọhun mulẹ loju opo ayelujara rẹ laarọ ọjọ Aiku, to si lo dun oun d'ọkan.
Davies lo jẹ ko di mimọ pe olorin naa ku lẹyin aisan rampẹ to ti n ba a finra.
"St Janet (Iyun Janet Ajilore), gbajugbaja olorin Juju ilẹ Naijiria, ẹni ti awọn eeyan mọ gẹgẹ bii pe o fi ara jin, to si tẹpa mọ iṣẹ rẹ, pẹlu ọkan akikanju ati itara, to fi mọ awọn orin amaraya ti ku.
"Ọjọ Abamẹta to kọja yii lo dakẹ lẹyin aisan rampẹ," Femi Davies ṣalaye.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni awọn mọlẹbi oloogbe naa ko tii sọ ohunkohun lori iku rẹ.
Ki lo ṣokunfa iku Saint Janet?
Bo tilẹ jẹ pe BBC News Yoruba ko tii le fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn lara ohun ti a gbọ ni pe aisan to nii ṣe pẹlu itọ ṣuga lo ṣokunfa iku rẹ.
Taani Saint Janet
Odu ni Janeth Omotoyosi Janet Ajilore Iyun, ẹni ti wọn tun n pe ni Mama Yabis, kii ṣaimọ foloko lagboole olorin Juju nilẹ Naijiria, ti ọpọ awọn to gbafẹ si gbadun ori rẹ nigba to wa laye.
Ko fẹẹ si agbo ariya tabi ibi ti awọn eeyan ti ma lọ n jaye, ti wọn kii tii gbọ orin rẹ lagbaye. Bo ṣe n ṣere orin nilẹ Naijiria, lo tun ti lọ soke okun lati lọ kọrin fawọn ololufẹ rẹ.
Inu ẹgbẹ akọrin ti ijọ Kerubu ati Serafu ni St Janat, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun naa ti bẹrẹ iṣẹ orin rẹ, nibẹ lo si ti bẹrẹ sii nifẹ si iṣẹ orin kikọ.
Nigba to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun, St Janet bẹrẹ sii tẹle gbajumọ olorin nni, Segun Lawaye jade orin kikọ, to si n ṣe elegbe lẹyin rẹ.
Igba to ya loun naa pinnu lati ṣe awo orin tiẹ sita, bo tilẹ jẹ pe ko tii gbajumọ nigba naa.
Diẹdiẹ ni Mama Yabis tun bẹrẹ sii mu idagbasoke ba orin rẹ, leyi to jẹ ko bẹrẹ sii di gbajugbaja laarin awọn olorin.
Ohun pataki tubọ jẹ ki Mama Yabis di ilu mọ-ọn-ka ni ti bo ṣe bẹrẹ sii yi awọn orin ti wọn n kọ lawọn ile ijọsin si ikọkukọ, eyi gan-an lo jẹ ki awọn to gbafẹ fẹran orin ọhun.
Nigba naa lo bẹrẹ sii pe ara rẹ ni oludasilẹ ile ijọsin Saint Bottles, eyi ti oloyinbo n pe ni "General Overseer of Saint Bottles Cathedral (Sinners' Chapel),".
Apejẹ yii lo ṣafihan iru awọn orin to n kọ fun awọn olulufẹ rẹ kaakiri agbaye
Pẹlu bo ṣe n kọ irufẹ orin yii to, awọn eeyan tun ṣi n gba tiẹ siwaju si i, to jẹ ki wọn maa pe e si oniruuru ode ariya nilẹ Naijiria ati loke okun.
Awo orin rẹ to pe ni 'Faaji Plus' gan-an lo tubọ gbe e ja sita gbangba, to di pe ko si ibi naa ti wọn kii tii kọ ọ.
Ọpọ igba ni ẹgbẹ olorin bii PMAN ti fi ofin de Saint Janet nitori irufẹ orin to n kọ, leyi ti wọn sọ pe ko ṣagbelarugẹ fun iwa ọmọluabi.
Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekoo tun gbe igbesẹ lori awo orin rẹ to pe ni 'Faaji Plus', ti wọn si fagile e lawọn ode to ba nii ṣe pẹlu ijọba ipinlẹ naa.




























