Má forúkọ mi ṣe ìpolongo ìbò mọ́, Makinde dá a padà fún Oriyomi

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina Seyi Makinde ìpínlẹ̀ Oyo ti kìlọ fún oludije sipo gomina f'ẹgbẹ òṣèlú Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, wí pé ko ye fi orúkọ oun ṣe ìpolongo ibo mọ.

Ṣaaju ni Oriyomi sọ pe oun loun mu Makinde wọ agbo oselu.

Amọ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo to sọrọ níbí eto kan niluu Ibadan sọ pe ki Oriyomi atawon mii ti wọn n l'orukọ oun fún oselu jawọ nbẹ tori oun ko dupo gomina ipinlẹ Oyo mọ.

Makinde wa rọ àwọn eeyan to n dupo òṣèlú wí pé ki wọn gbaju mọ nnkan ti wọn ba fẹ ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Oyo, dipo bi wọn ṣe n bu oun kaakiri.

''Mo ri awọn eeyan kan ti wọn n sọ kaakiri pe awọn fẹ jẹ gomina ipinlẹ Oyo.

Mo tun ri ọkan to ni oun loun mu mi wọ inu oṣelu, amọ, emi o dije fun ipo gomina mọ o.

Awọn eeyan ipinlẹ Oyo ti fun mi lanfaani lati sin wọn, mo fẹ ki awọn naa lọ sọ fun araalu nnkan ti wọn ba fẹ ṣe yatọ; ẹ ye bu Makinde mọ.

Ẹ le maa bu Bimbo atawọn ọmọlẹyin rẹ, koda ẹ le maa bu ara yin; ṣugbọn emi o dupo gomina mọ.

Ki lo de ti Makinde ko ṣe awọn nnkan kan? Ṣe nnkan ti ẹ fẹ maa fi ṣe ipolongo ibo niyẹn?

Mo fẹ ki ẹ mọ wi pe emi ti ṣe temi o,'' Makinde lo ṣalaye bẹẹ.

Oriyomi Hamzat ṣàlàyé bí tírélà ṣe gba ààrín òun àti Gómìnà Seyi Makinde kọjá lẹ́yìn tó ní òun ṣe ṣàtìlẹ́yìn fún un dé ipò gómìnà

Gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio ilu Ibadan to tun n dije du ipo gomina ipinlẹ Oyi labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Oriyomi Hamzat ti sọ pe oun wa lara awọn to ṣatilẹyin fun Seyi Makinde lati de ipo gomina ipinlẹ Oyo.

Hamzat sọ pe atilẹyin oun fun Makinde ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu owo tabi ere ti oun yoo jẹ lati ọwọ rẹ amọ o jẹ nitori igbagbọ oun pe yoo ṣiṣẹ sin araalu.

Ọrọ yii lo jade lasiko ti Oriyomi n ba awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu Accord sọrọ lopin ọsẹ to kọja nibi ipade kan ti wọn fi sọ ori ọna Circular.

Korikosun ni sọrọsọrọ naa ati Makinde tẹlẹ amọ alangba ti wọ inu ogiri ibaṣẹpọ wọn lẹyin ti awọn mejeji ya si ọna ọtọtọ ninu oṣelu, paapaa ni imurasilẹ fun eto idibo ti yoo waye lọdun 2027.

Hamzat, to gbajumọ fun eto "Kokoro Alate" lori redio rẹ, Agidigbo FM ni oun ṣatilẹyi fun Makinde pẹlu igbagbọ pe yoo sin araalu.

Amọ o kabamọ pe ọpọ araalu ni ko gboriyin fun akitiyan oun lati gbe gomina ọhun dori ipo.

Mo wa lara awọn to gbe Makinde dori ipo

O ni "Seyi Makinde ti tun Oyo ṣe... Ta lo gbe Seyi Makinde wọle? E mi ni. Mo wa lara awọn to gbe Seyi Makinde wa, mo si ṣatilẹyin fun gẹgẹ bii gomina.

"Gbogbo awọn nnkan meremere to ṣe, kilode ti ẹ kọ gboriyin fun mi? Kilode to fi jẹ pe eyii ti ko daa to ṣe ni wọn fi n bu mi?

"Gbogbo awọn ẹgbẹ alatako yẹn, ti wọn ba fẹ sọrọ, wọn maa sọ pe o ṣe nnkan meremere, kilọde ti ẹ ko gboriyin fun emi naa?

Oriyomi tẹsiwaju pe "Awọn eeyan ti pe mi ni alaimoore, Alaimoore bii ti bawo? Ṣe kii ṣe Oriyomi kan naa to wa ba yin lati ṣe ipolongo ibo fun? Igbagbọ ti ẹ ni ninu mi han ninu esi ibo naa.

"Mi o tẹle ijọba nitori ki wọn gbe iṣẹ fun mi. Mo ni adehun pẹlu ijọba pe mo maa ṣatiẹyin fun wọn ti wọn ba maa ṣetọju araalu. Ko si ohun to jọ idunadura rara.

"Mo kan n fẹ ki awọn eeyan gboriyin fun mi pe ẹni ti mo ni ki wọn dibo fun n ṣe daadaa ni."

Ki lo tu aarin Makinde ati Hamzat ka?

Ede aiyede arin Hamzat ati Makinde yii lo n waye ṣaaju eto idibo ọdun 2027.

Oriyomi fẹ du ipo gomina ipinlẹ Oyo ninu eto idibo naa nigba ti Makinde fẹ du ipo Aarẹ amọ Makinde ko ṣatilẹyin fun Oriyomi.

Kọmiṣọna fun eto iṣuna labẹ ijọba oloogbe Abiola Ajimobi, iyẹn Bimbo Adekanmbi, ni Makinde n ṣatilẹyin fun ko di gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM.