Ṣé lóòtọ́ọ́ ni àwọn ẹ̀gbọ́n Ademola Adeleke ti já àkóso ìjọba Osun gbà mọ́ ọ lọ́wọ́? Àlàyé rèé
Saaju eto idibo gomina nipinlẹ Osun, ni ẹnu ti n kun gomina ipinlẹ naa pe oun kọ lo n dari eto isakoso nipinlẹ naa, amọ se lo n se abẹsinkawọ fun awọn ẹgbọn rẹ.
Awọn eeyan kan wa n naka aleebu si gomina Adeleke pe se lo fa akoso ipinlẹ Osun le ẹgbọn rẹ ọkunrin, Deji Adeleke, tii se baba olowo nipinlẹ Osun lọwọ, ẹni to tun jẹ baba gbajumọ akọrin takansufe nni, David Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si Davido.
Bakan naa ni wọn ni ẹgbọn gomina lobinrin, Dupe Adeleke Sanni, ti ọpọ eeyan n pe ni Yeye lo jẹ igi lẹyin ọgba fun gomina Adeleke to si n pasẹ awọn igbesẹ ti yoo gbe lori eto akoso ipinlẹ Osun fun.
Idi ree ti BBC News Yoruba se fi ọrọ wa gomina Adeleke lẹnu wo lati mọ ero rẹ nipa ẹsun ti awọn eeyan n fi kan yii.
Bakan naa ni a fẹ mọ ipa ti ẹbi rẹ n ko ninu eto akoso ipinlẹ Osun.

Oríṣun àwòrán, @AAdeleke_01
"Tori mo jẹ gomina, n ko le sọ pe awọn ọmọ iya mi kii se ẹgbọn mi mọ"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, gomina Ademola Adeleke ni ọmọ iya oun ni Deji ati Dupe Adeleke ti awọn eeyan mẹnuba pe wọn ti ja akoso ijọba ipinlẹ Osun gba mọ oun lọwọ.
"N ko le sọ pe mo di gomina, ki n wa sọ pe wọn kii se ọmọ iya mi mọ.
A wa papọ lootọ amọ emi ni Ọlọrun fun ni asẹ biro pupa lati fi ọwọ si nnkan.
Nigba miran, ti wọn ba fun mi ni imọran, mo maa n ronu jinlẹ le lori tabi ki n gbadura si.
Nigba miran, mo le gba imọran naa, ki n fi ọwọ si tabi ki n kẹyin si imọran naa amọ eeyan kan ko le da nnkan se.
Tinubu gan ni awọn eeyan to n ba gba imọran, nitori naa, awawi lasan ni pe awọn lo n dari ijọba nipinlẹ Osun."

Oríṣun àwòrán, @AAdeleke_01
"Ẹgbọn mi ni ki n kọkọ mojuto eto aabo na, ki n fi oju ọna Ikirun si Osogbo silẹ, mo sọ fun pe mo fẹ sare tete se oju ọna naa, emi sa ni gomina"
Bakan naa ni gomina Adeleke salaye pe aimọye igba ni awọn eeyan maa n ke si awọn ọmọ iya oun, ti wọn jẹ ẹgbọn oun yii pe ki wọn ba oun sọrọ.
"Nigba ti mo kọkọ de ipo gomina, ọna to lọ si Ikirun lati Osogbo, nibi ti ijọba Aregbesola se de, mo mọ pe awọn eeyan n ku nibẹ, ọna naa si ni mo kọkọ fẹ se.
Amọ ẹgbọn mi ni ki n kọkọ mojuto eto aabo na, ki n fi oju ọna naa silẹ, mo si sọ fun pe mo fẹ sare tete se oju ọna naa.
Emi ni gomina, mo si lọ se ọna naa, ni ọjọ ti a fẹ si ọna naa, mo ni ko wo o lori tẹlifisan pe mo ti se ọna naa, nigba to wo o, o ni eleyi si wa dara o.
Bo se yẹ ko ri niyẹn."




