Baálé ilé lu ìyàwó rẹ̀ pa nítorí oúnjẹ, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa ni ọwọ ṣinkun ofi ti tẹ ọkunrin kan, Musbawu Amodu, ẹni ọgbọn ọdun fun ẹsun pe o lu iyawo rẹ, ẹni ogun ọdun pa.

Ọlọpaa ni ilu Angwan Yahaya, Agyaragu ni ijọba ibilẹ Obi, ipinlẹ Nasarawa ni iṣẹlẹ naa ti waye lasiko ti ija du tọkọtaya naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Nasarawa, Ramhan Nansel ṣalaye pe nnkan bii aago mejila abọ ọsan ọjọ Aiku, ọjọ Kejila, oṣu Keje ni awọn eeyan kan lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Agyaragu pe afurasi naa ti lu iyawo rẹ ti ẹmi si ti bọ lọrun iyawo naa.

Nansel ni kete ti wọn mu ẹjọ naa de agọ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa lọ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ti wọn si gbe oku iyawo naa lọ sile iwosan Federal University Teaching Hospital, Lafia fun ayẹwo kikun.

O fikun pe awọn ọlọpaa fi ṣikun ofin mu afurasi naa to si jẹwọ lasiko ti wọn n fi ọrọ wa lẹnu wo pe inu lo bi oun pe iyawo kọ lati dana ounjẹ, eyi lo fa a ti oun fi fi ibinu lu u.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Amodu ti kabamọ iwa to wu, to si ni oun ko mọ pe iṣẹlẹ naa maa ja si iku fun iyawo oun.

Ọmọ meji ni oloogbe naa fi kalẹ, ọkunrin kan ati obinrin kan, ti igbeyawo oun ati ọkọ rẹ si ti pe ọdun mẹfa.

Kọmiṣanna ọlọpaa Nasarawa, Shetima Mohammed ti paṣẹ pe ki ẹka to n ri si iwa ọdaran ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Lafia bẹrẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si ri pe iwadii wọn ya kiakia.

Kọmiṣanna naa wa fi da awọn araalu loju pe idajọ ododo maa waye lori iṣẹlẹ naa ati pe kete ti iwadii ba ti pari ni wọn maa gbe afurasi naa lọ si ile ẹjọ fun idajọ ododo.

Bakan naa lo bu enu atẹ lu ifiyajẹni to maa n waye ninu igbeyawo, bo ṣe woye pe iṣẹlẹ to waye jẹ ohun ti ko yẹ ko waye rara, to si rọ awọn lọkọlaya lati maa yanju ede aiyede to ba n waye laaarin wọn ni tubi n nudi.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa sọ aridaju fawọn olugbe Agyaragu lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ, pe gbogbo agbegbe naa lo wa ni pẹlẹ kutu bayii, tawọn ẹṣọ aabo yoo si tẹsiwaju lati maa mojuto agbegbe naa fun igba kan na.