Mọ nípa àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ líìgì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wáyé ní Ọjọ́rùú

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist
  • Published

Chelsea kọ̀ láti bórí Brentford, Man Utd bínú bù ìgbàjú lú Tottenham

Ni Ọjọru, ninu ifẹsẹwọnsẹ ligi ilẹ gẹẹsi, awọn ẹgbẹ agbaboolu fakọyọ, ti wọn si mi awọn orisirisi, ti ifẹsẹwọnsẹ yoo si tun waye lalẹ oni.

N se ikọ agbabọọlu Manchester United labẹ olukọni Erik Ten Hag gbo ewuro si oju ikọ Tothenham pẹlu ami ayo meji si odo. Fred ati Fernandes lọ ṣe atọna bi wọn ṣe bori ikọ Tothenham sugbọn oro si ma ibo miiran yoo fun lẹyin ti atamatase Cristiano Ronaldo fi ara pa ti wọn si lilo lati gbe jade kuro ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ikọ Tothenham gbinyanju agbara wọn sugbọn ikọ Manchester United ni awọn ni fun anfani lati ri imu mi ori papaa Old Trafford

Ninu ifẹsẹwọnsẹ miiran, ikọ Liverpool bori West Ham United pẹlu ami ayo kan si odo. Darwin Nunez lo mi awọn naa.

Kete ti wọn wọ ninu saa keji ni ikọ West Ham ri pẹnariti lẹyin ti Joe Gomez kọlu Jarred Bowen sugbọn ọrọ bẹyin yọọ fun  Bowen nigba ti amule Liverpool ṣe idaduro fun lati mi awọn.

Igba akọkọ re ti Darwin Nunez yọọ mi awọn ni papaa Anfield, eyi to jẹ ti Livrepool.

Ikọ Newcastle United naa fakọyọ lana nigba ti wọn bori ikọ Everton pẹlu ami ayo kan si odo

Akọnimọgba ikọ naa Eddie Howe gbosuba fun awọn agbabọọlu naa paapa julọ Miguel Almiron to mi awọn fun ikọ Newscastle .

Nibayi ikọ Newcastle ko ti padanu ifẹsẹwọnsẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti wọn ti kopa ninu ligi ile gẹẹsi.

Nise ni ikọ Brentford taku si ọrun ikọ Chelsea, ti ko si ẹnikẹni to ni anfani lati mi awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ana.

Ikọ Chelsea ti gba ifẹsẹ wọnsẹ meju bayi ti wọn ko si ti padanu rara ninu ligi ile gẹẹsi lati igba ti wọn ti kede olukọni tuntun Graham Potter

Ọpọ igba ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ni amule ikọ Chelsea Kepa Arrizabalaga ṣe idaduro fun ikọ Brentford nigba ti Ivan Toney ati Bryan Mbeumo gbinyanju lati mi awọn.

Bakan an ni David Raya di apata nla to n ṣe idaduro lana nigba ti Cesar Azpilicueta ati Kai Havertz gba bọọlu si ojule