WAEC ṣàlàyé ìdí tó fi gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò tó lé ní 200,000

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, WAEC

Published

Ajọ to n ri si idanwo aṣẹkagba ile ẹkọ girama ni iwọ oorun Afrika, WAEC, ti gbẹsẹ le esi idanwo akẹkọọ ti iye wọn jẹ 262,803.

WAEC ni pupọ ninu awọn esi idanwo ti wọn gbẹsẹle naa ko ṣẹyin awọn magomago idanwo ti awọn akẹkọọ naa ṣe.

Esi idanwo 262,803 ọhun ni wọn gbẹsẹle ninu awọn 1,613,733 to kọ idanwo naa lọdun 2023.

WAEC

Oríṣun àwòrán, WAEC

“A fẹ fi da awọn to n gbe iwe wọle sinu gbọngan idanwo pe wọn ko ni lọ lai jiya”

WAEC ni ọpọ awọn akẹkọọ naa lo ṣe makaruru lasiko idanwo, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

O ni iyanlẹnu lo jẹ pe pupọ akẹkọọ lo maa n gbe iwe wọ ninu gbọgan idanwo pẹlu igboya.

Aṣoju WAEC nileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Parick Areghan sọ pe ajọ naa ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn akẹkọọ ọhun ba a lorukọ jẹ.

O ni “A fẹ fi da awọn to n gbe iwe wọle sinu gbọngan idanwo pe wọn ko ni lọ lai jiya, bẹẹ si ni a ko ni faye gba iru rẹ lati maa tẹsiwaju mọ.”

“Awọn akẹkọọ ti igbesẹ wa ko ba tẹ lọrun le gba ile ẹjọ lọ to ba wu wọn.”

WAEC sọ siwaju si pe oun ti fi ṣikun ofin mu awọn to ṣagbekalẹ gbagede ti awọn eeyan ti n ṣe makaruru idanwo, ‘mircle centres’ lawọn ipinlẹ bii Abia, Borno, Imo, Ogun ati Oyo.

Bakan naa ni o ni oun tun tu aṣiri awọn olukọ atawọ oṣiṣẹ WAEC to n ṣatilẹyin fun awọn akẹkọọ naa.

Bi o ṣe le wo esi idanwo WAEC ọdun 2023

Oniruru ọna ni eeyan le gba lati wo esi idanwo WAEC ọdun 2023.

Ọna akọkọ ni nipa titẹ atẹjiṣẹ “WAEC*ExamNo*PIN*ExamYear” lori foonu rẹ si nọmba 32327.

Ọna keji ni lilọ sori ikanni www.waecdirect.org.