You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìtàn ìgbé ayé Kudirat Odukanmi, Iyabo Oko tó jáde láyé
Gbajugbaja oṣere tiata, Kudirat Odukanmi ti ọpọ mọ si Iyabo Oko ni o ti jade laye lowurọ oni.
Ọmọ oṣere naa, Aishat Adebisi lo fi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC News Yoruba pe iya oun ti dagbere fun aye.
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1960 ni wọn bi Iyabo Oko, niluu Iwo nipinlẹ Osun, gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa lori ayelujara Wikepedia.
Ni 1973 si lo bẹrẹ iṣẹ ere ori itage nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹtala, labẹ ẹgbẹ oṣere Eda Onile Ola.
Oloogbe Kudirat Odukanmi bẹrẹ si ni di ilumọọka oṣere lẹyin to kopa ninu fiimu Oko, ti Adebayo Salami ‘Oga Bello’ kọ.
Ọdun 2015 ni Iyabo Oko ti wa ninu aisan
Iyabo Oko, ẹni ọgọta ọdun ni kudiẹkdiẹ ti de ba ilera ara lati ọdun 2015, ko to wa jade laye loni
Aisan yii ni ko fun Iyabo Oko laye lati le kopa ninu ere sinima gẹgẹ bi ti tẹlẹ.
Ni ọdun 2015 ni iroyin sọ pe Iyabo Oko ni aarun Ischemic stroke, eyi to mu ko da fiimu ṣiṣe duro.
Ninu oṣu Kinni, ọdun 2022, ni iroyin iku oṣere naa kọkọ jade, ṣugbọn awọn ọmọ rẹ tun pada kede lẹyin wakati diẹ pe iya awọn ko ku mọ.
Awọn ọmọ rẹ sọ fun BBC nigba naa pe lẹyin wakati mẹta ti iya awọn ti gbẹmi mi, lo tun pada si aye.
Ninu oṣu Kẹta ọdun 2022, ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja oṣere tiata naa wa sọ fun BBC Yoruba pe agba oṣere naa ti n gbadun, bo tilẹ jẹ pe o ku ni ibọn n ro.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni awọn gẹgẹ bii mọlẹbi mọọmọ kọ lati sọrọ nipa oṣere naa lori ayelujara ni nitori awọn eeyan kan to le maa ro pe nṣe ni awọn fẹ tọrọ owo lọwọ awọn ololufẹ rẹ.
O ni "Awọn mọlẹbi ti ni ki a maṣe sọ ohunkohun nipa ilera iya wa lọwọ yii nitori awọn eeyan to le maa ro pe a fẹ tọrọ owo lọwọ wọn ni."
"Bi mọ ṣe n ba yin sọrọ yii gan, ọwọ mi ni ẹrọ ilewọ wọn wa, nitori a ko fẹ ki wọn ba ẹnikẹni sọrọ lakoko yii amọ ara wọn ti n balẹ diẹ-diẹ."
"Kii ṣe gbogbo nnkan to ba n ṣẹlẹ ni a oo maa sọ lori ayelujara, a ko si ṣetan lati maa gbe wọn jade ni gbogbo igba, ẹni to ba fẹ lati ṣe iranlọwọ fun yoo ṣe e lai bẹbẹ."
Diẹ lara awọn fiimu ti Iyabo Oko kopa ninu rẹ ni Oko, Ayitale, Idun nu Okan, Mayowa ati Okobo meji.